Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): P

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Atumo-Ede (Yoruba-English): P

Oju-iwe Kiini[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

pa, verb. (primary idea, “to make to feel, suffers, etc.”, extensively used in composition), to kill, to murder, to put out of existence, to ruin, to stay, to betray to quench fire, to extinguish, to bruise, to rub, to scrub, to cut yam or calabash into halves, to break any hard nut, to peel the bark of a tree, to win a game, to hatch, (eggs), to tell fables, to be intoxicated (as with liquor).

páá, adv. at once, in an instance. Ó lọ síbẹ̀ páá. (He went there at once.)

pá adj. bald, hairless (as in the head). Bàbá náà pá lórí. (The man is bald.)

pá v.t. to avoid giving occasion for quarrel, to avoid strife. Ó pá èṣù (páàṣù/péèṣù) mọ́ nílẹ̀ (He avoided strife.)

padà, v.i. to return, to come back. Yóò padà dé ilẹ́ láìpẹ́. (He will return home soon.

padà v.t. to alter, to change to convert to. Yóò pa èrò rẹ̀ dà. (He will alter his plan.

pàdánù, v.t. to lose, to suffer loss. Yóò pàdánù ojú rẹ̀ láìpẹ́. (she will lose her sight soon.)

padà san, v.t. to repay, to refund, to retaliate. Wọn yóò padà san owó ìwé náà. (The will refund the cost of the book.)

padà sẹ́yìn, v.i. to turn back, to relapse. Ó padà sẹ́yìn sí àwọn ìwà burúkú rẹ̀ àtijọ́ (He relapsed into his old bad habits.)

padà sí v.t. to resort to, to come back to, to turn upon, to return to. Ó ti padà sí ilé. (He has returned home.

pàdé, v.t. to meet with, to come together. Jẹ́ kí á pàdé ní ilé rẹ lálẹ́ (Let us meet at your house tonight.)

padé, v.t. to shut, to close up. Ó pa ilẹ̀kùn dé. (He closed the door.)

pàdégun (pàdè ogun), n. to meet in battle, to encounter) Wọ́n pàdégun (They met in battle).

pàdéminígbọ̀nwọ́, n. (lit. meet me at the elbow) watery sauce. pàdéminígbọnwọ́ ni agbára àwọn òtòsì ká. (poor people can afford only watery source.)

pàdẹ, v.t. to expose near the gate of a town or village the garments or other clothes left by a hunter after his death.

padẹmọ́lọ́wọ́, v.t. to hand-cuff; fig to cheat, to swindle. Wọ́n padẹ mọ́ ọn lọ́wọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀. (His hands were handcuffed behind his back.)

pàdí, v.t. to be cracked at the bottom (said of pots, etc.) Ìkòkò náà pàdí. That pot is cracked.

pàdí, v.t. to be the cause of. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ó pàdí iná náà? (Do you know what caused the fire?).

pàdi, n. bunch of banana, etc. Ó ra pádi ọ̀gẹ̀dẹ̀ kan. (He bought a bunch of bananas.)

pááfá, páráfà, n. a butcher’s table, board, a long table, a litter. Òun ni ó ni pááfà yẹn. (He owns that butcher’s table.

páfe, pátápátá, adv. altogether, absolutely, entirely, completely. Ó tán páfe. (It is completely finished.)

páfin, v.i. to be careful not to infringe the law (generally used with a negative).

pàfọ̀, v.i. to wallow in the mire. Ẹlẹ́dẹ̀ náà ń pàfọ̀. (The pig is wallowing in the mire.)

pagi, v.t to lop off the branches and leaves of trees (as by the ‘Orò’) eaten the leaves of a tree. Orò pagi orò has eaten the leaves of the tree.

pagidarì, interj. an exclamation of surprise, fancy! Pagidarì! Kò tíì wọ ọkọ̀ òfurufú rí. Fancy! She has never been in a plane before.

pa gììrì, Ta gììrì, v.i. to arouse oneself suddenly, to shudder. Ó pa gììrì nígbà tí ó rí ẹ̀jẹ̀. He shuddered at the sight of blood.

pàgọ́, v.i to make or fix a tent. ó pagọ́. He pitched a tent.

págunpàgun, adj. clumsy, uneven, reagged. ọ̀nà náà ṣe págunpàgun. The road is uneven.

pàgbẹ́, ṣángẹ̀ẹ́ v.t. to clean a new forest for the purpose of cultivating it for planting yams, corn, etc., to clear the forest. Ó ti pàgbẹ́. He has cleared the forest.

pagbo, v.i to make or form a ring or circle, to arrange in a circle. Wọ́n pagbo They arranged themselves in a circle.

pahín payín, v.i to chip off two of the upper front teeth (for fashion), to file teeth. Ó pahín. He filed his teeth.

pahím keke, Payín keke, v.t. to gnash the teeth. Yóò máà pahín keke nígbà tí ó bá gbọ́ pé iṣẹ náà kò bó sí i mọ́. (He will be gnashing his teeth when he hears that he lost the contact.

pahùn dà (pa ohùn dà), v.t. to alter or disguise one’s voice, to change one’s tone. Ó pahùn dà the tone of his voice.

páipài, adv. adj. or adv. uneven(ly) (The road is uneven.

Pajápajá, n. numbness, cramp pajápajá mú un. (He has cramp.

pajẹ, v.t. to kill animal for food, to miss, to omit. ó pa á jẹ. (He killed it and ale it

pakà, v.t. to thresh corn. Ó pakà (He threshed corn.)

pakájà, v.i. to pass a country cloth from under one arm to the other shoulder, to throw the end of one’s cloth over one’s shoulder.

pákáńleke, n. worry, compulsion, force. pákáńleke tí ó ń ṣe hàn lójú rẹ̀. (The worry showed on his face.

pa kànnàkánná, v.t. (of eyes) to be dazed with, blows, lighting, etc. Ojú rẹ̀ pa kànnàkánná. (He felt dazed.)

pakàpakà, Apakà, n. corn thresher, thresher of corn. pakàpakà ni (He is a corn thresher.)


pàkàpàkà, adv. greedily. Ó ń jẹun pàkàpàkà. (He is eating greedily.)

pakasọ, adj. not even, beyond limit, vast. Igbó náà pakasọ (it was a vast area of forest.)

pàkátà, n. a flat open calabash. Ó lé obirẹ̀ sórí pàkátà. (He arranged her kolanuts on a flat open calabash.)

pa kẹ̀ẹ́kẹ̀ẹ́, v.i. to bustle about, to bustle around. Ó ń pa kẹ̀ẹ́kẹ̀ẹ́ kiri ilé ìdáná. She bustled around the kitchen.

pakẹ́rẹ́, n. a kind of rope.

pákí, Gbáàgúdá, ẹ̀gẹ́, n cassava.

palate, n. a coarse mat.

pákó,n. board, plank.

pàko, n. bamboo.

pákò, orín, n. chewing-stick.

pako, sáko, v.t. to clean field for cultivation.

pakọ, v.t. overpower.

Pá kọ̀kọ̀, pa kọ̀rọ̀, v.i. to go by nooks and corner, to go stealthily. Ó ń pá kọ̀kọ̀. (He was going stealthily).

pákọ̀kọ̀ n. a secret play at night like the Orò.

Pa kọ́lọ́, pa kọ́lọ́kọ́lọ́, v.i. to sneak, to skulk. Kí ni o ń ṣe tí o ń pá kọ́lọ́kọ́lọ́ ní ìta níbẹ̀ yẹn? (What are you doing sneaking around out there?).

pakú, v.t. to extinguish, to quench. Àwọn panápaná gbìyànjú láti pa iná tí ń ń jó mínú ilé náà kú. Foremen tried to quench the flame raging through the building.)

pakùnrété, òrofó, n. a kind of dove.

pàkùrọ́, pa èkùrọ́ v.t. to crush or crack palm-kernals. wọ́n pàkùrọ́ lánàá (They crushed palm-kernels yesterday.)

pa kuuru, pa kuuru mọ́, v.t. to rush fibrously against. ó pa kuuru mọ́ mi. (He rushed furiously against me.)

pàkúta, adj. laving sands or stones. Oúnjẹ yìí ń pàkúta. (The food has sands in it.)

pákútá, n. a small stew-pan.

Pàkúté, Tàkúté, n. trap for mouse or rat. Ó kẹ́ pàkúté méjì fún àwọn ekú náà ó sì pa wọ́n. (He set two traps for the rats and he killed them.)

pààlà, v.t. to mark boundary of land or territory, to demarcate boundary between land or territory. A pààlà oko wa. (We demarcated the boundary between our farms.)

pàlà, adv. with much effort, with difficult, to writh in pain. Ó ń rá pàlà. (He is writhing in pain.)

palaba, adj. fist, broad, flat. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ náà rí palaba. (The boy has a glat cheek.)

palaba, adj. large.

paláàbatà, palágbọn, v.t. to strike writh. Àdìmú-òrìṣà staff. Wọ́n ń paláàbatà. (They were striking people with the àdìmú-òrìṣà staff called ) ‘ọ̀pá àbatà’

paláàdánù, v.t. to make to lose, to involve in loss. Ó pa á láàdánù. (It involved him in loss.)

pá láàyà, v.t. to strike with terror, to terrify. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pá mi láàyà. (His words terrify me.)

pàlàkà, n. the division of the fingers or the groins, the point at which the branch is attached to the trunk of the tree, axil, the place where branch emerges from a tree.

palámọlù, v.i to strike the two feet one against the other in the act of jumping.

pálapàla, n. nonsense. Ó ní àwọ̀ pupa ni ó dúró fún àlàáfíà nílẹ̀ Yorùbá, Irú pálapàla wo nìyen!. (He said the red colour stands for peace in Yoruba land. (What nonsense!).

pàlàpálà, n. crevice of the rock, etc.

pa lápa tán, v.t. to kill outright. Wọ́n pa wọ́n lápa tán. (They were killed outright.)

pa lára, v.t. to hurt, to bruise, to damage. Ṣẹ́ ó pá ọ́ lára? (Did he hurt you?)

pa lára dà v.t. to transform, to change into another form. Ó ti pa á lára dà sí orísìí mìíràn. (He has changed it into another form.)

pa láró, v.t. to dye. Ó pa irun rẹ̀ láró sí dúdú nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ síí hewú. (She dyed her hair black when it began to book grey.)

pa láṣe v.t. to command, to order, to authorize. Ó pa á láṣẹ pé kí n rà á. (He ordered that I buy it.)

palé, v.i. to rub the floor of the house with horse-dung, green leaves. Àwọn obìnrin náà palé wọn. (The women rubbed the floor of their house with horse-dung.)

pale lé, bààlè lé, v.t. to set a mark upon as a thing not to be touched by another except the owner, protective charm. Ó pààlè lé oko rẹ̀. (He put a protective charm on his farm to disallow others from entering it.)

palẹ̀ mọ́, v.t. to put things together or in order, to clear, to take away. Wọ́n palẹ̀ òkú náà mọ́ fún sínsin. (They took away the corpse for burial.)

pa lẹ́rìn-ín v.t. to make to laugh. Ó pa mí lẹ́rìn-ín. (He made me laugh.)

páálí, n. card-board

páálí, pẹ́ẹ́lí, adj shriveled, shin. Ó rí pẹ́ẹ́lí (She was shin.)

pàlọ́, v.i. to propound riddles, or puzzles, for solution, to tell a riddle. Ó pàlọ́ fún wa. (He told us a riddle.)

pa lọ́lọ́, pa rọ́rọ́, v.i. to be quiet, still or motionless, to be awed, to be silent. Ó pa lọ́lọ́. (He remained silent.)

pa lọ́tí v.i. to be drunk, to swell up with pride. Ayọ̀ ń pa ọ́ lọ́tí. (You are drunk with success.)

pámi, v.i. to be disheartened, to lose heart.

pamọ́ v.t. to keep safe, to preserve for future use, to protect. Ó pa á mọ́. (He protected it.)

pa mọ́kùn, v.t. to keep in mind, to keep to oneself. Ó pa àṣíírí náà mọ̣́kùn (ara rẹ). (He kept the secret to him self.)

pa mọ́lẹ̀, v.t. to conceal, to hide, to suppress. A kò lè pa ìbínú rẹ̀ mọ́lẹ̀. (We could not suppress her anger.)

paamọ́lẹ̀ paramọ́lẹ̀, n. viper, adder

pa mọ́nú, v.t. to keep in mind, to keep to oneself. Ó pa àṣíírí náà mọ́nú (He kept the secret to him self.)

pa mọ́ra, v.t. to bear patiently, to endure, to bear with fortitude. Ó pa ìrora náà mọ́ra. (He bore the pain with fortitude.)

pará, v.t. to put out the light, to quench burning fire, to extinguish. Ó paná àtùpà náà. (He extinguished the lamp.)

pandan, adj. add, quaint, awkward.

pandero, pantero, n tambourine.

páńdọ̀rọ̀, n. a tree much used in medical precantions.

pánlún, pán-ún adv. at once, at a stroke. Ó kán an.

pan-hun pán, pọ́n-ún, pọ́n-hún, adv. at, once, at a stroke. Ö kán igi náà pọ́n-ún. (He broke the stick at once.)

pani pànìyàn, v.t. to kill to murder, to kill a person, to kill someone. Ó lè pani. (He can kill someone.)

panígbe, v.t. to cause to cry, to, make to cry. Ó pa á nígbe. (He made him cry.)

panígbè, v.t. to be severely, to worry, to trash. Ó pa á nígbè. (He trashed him.)

panilérìn-ín, adj amusing, exciting, laughter, ridiculous. Fìlà tí o dé panilẹ́rìn-ín. (You look ridiculous in the hat you put on.)

panipani, n. murder. Òṣèré náà kò ní ọgbọ́n panipani nínú. (The players lacked the killer instinct.)

panirun, v.i. to destroy. Wọn kò níí gbà á láyè láti panirun. (They won’t allow him to destroy us.)

pa níyè, ra níyè, v.t. to confuse, to confound. Ó pa mí níyè. (I go confused.)

paníyè dà, pa lérò dà, v.t. to persuade, to change the mind. Ó pa mí níyè dà. (It caused me to change my mind.)

pankẹ́rẹ́, n the willow.

pàǹpá, n. bargain, mutual agreement between traders, to enter into a compact. Wọ́n dì pàǹpá. (They went into a compact with one another.)

pańpẹ́, pawọ́pẹ́, n handcuffs. wọ́n fi pańpẹ́ mú ún lọ́wọ́. (He was in handcuffs.)

páńsá, n. dry calabash uncut.

panṣágà, n. adulterer, fornicator adulteress.

panságà, n. adultery, fornication, halotry, prostitution. Ó ń ṣe pánṣágà. (He is committing adultery.)

pànṣárá, n. a broad wicker tray on which articles are exposed for sale. Ó lé obì lé orí pàǹsárá. (She arranged the kolanuts in little piles on a broad wicker tray on which articles are exposed for sale.)

panṣùkú, n. a large basket or calabash with cover, used for carrying food, wearing apparels, etc, when traveling.

pantí, pàntírí, n. heaps of rubbish, debris, litter.

panu mọ́, v.i. to be silent, not to speak, to keep silent. Mo panu mi mọ́. (I kept silent.)

pápá, n. grass field, newly-burnt field for cultivation.

pàápàá, adv. especially, particularly. Mo gbádùn eré náà pàápàá, ti ìlàjì àkọ́kọ́. (I enjoyed the play, especially, the first half.)

pàápàá, reflex. Pron. Myself, yourself, himself, ourselves, yourselves, themselves. Òun pàápàá ni. (It was he himself.)

pàpà, adv. violently, eagerly.

papa, n. anxiety, worry, trouble.

pàápàá gidi, adv. even.

papagoori, n. a small bird superstitiously regarded by the worshippers of Ṣàngó, who pretend to understand its cry.

pápásaw, n. a herb much used in curing abscess or witlow.

pàpèjọ, v.t. to call a meeting or an assembly. Ó pàpèjọ (He called a meeting.)

papó, v.i. to collapse. Ó ti papó. It has collapse. Àpótí onípáálí náà ti papó. (The card-board box has collapsed.)

papòdà, v.i. to change place, to die. Ọkùnrin náà papòdà. (The man died.)

pa poro, v.i. to corrugate, to make a furrow. Ó pa poro. (He made a furrow.)

papọ̀, v.t. to join, to mingle together, to unite, to assemble. A papọ̀. (We assembled.)

pàpọ̀ ju, v.i. to be abundant, to be numerous. A pàpọ̀ jù. (We were very numerous.)

páraá. n. the upper part of the plate rests on the posts supporting a piazza.

pàrà, adv. with suddenness, at once, suddenly. Ó jágbè mọ́ mi pàrà. (He shouted at me suddenly.)

para, v.t. to rub the skin with ointment. Ó fi epo para. (He rubbed palm-oil on his body.)

pààrà, v.t. to frequent or hunt a place. Mo ń pààrà ilé rẹ̀. (I frequent his house.)

para dà, v.i. to disguise, to change or conceal by altering one’s appearance. Ó para dà. (He disguised himself.)

párafà, n. a bamboo sofa. Wọ́n jókòó lórí párafá. á. (They sat on a bamboo sofa.)

pàràkọ̀yí, n. guild of traders, any member of this, an Ọ̀yọ́ title.

para mọ́, v.i. to keep oneself close, to take heed. A para mọ́. (We took careful heed.)

pàrándún, v.i. to tell exaggerated tales. Ó pàrándún fún wọn. (He told them an exaggerated tale.)

parapárà, n. mat made of the soft matter in the bamboo poles. Ó tẹ́ ẹní parapárà. (He spread a mat made of the soft matter in the bamboo pole.)

para pọ̀, v.i. to unite, to join together, to become ally. Wọ́n para pọ̀. (They became allies.)

pa rán-unràn-un, v.i. to move about with perplexity, to be a vagrant. Ọ̀mùtí náà ń pa rán-unràn-un kiri. (The drunkard is moving about with perplexity.)

parẹ́, v.i. to erase, to rub out, to obliterate. Wọ́n ti pa á rẹ́ (They have erased it.)

parẹ́ lúúlúú, v.i. to efface entirely. Ó pa àkọlé náà rẹ́ lúúlúú. (He effaced the inscription entirely.)

parí, v.i. to come to an end, to finish. Wọ́n ti parí iṣẹ́ wọn. (They have finished their work.)

párí adj. bald with scalp wholly or partly hairless. Wọ́n párí. (They are bald.)


páárí ẹ̀rẹ̀kẹ́, n. jaw, jaw-bone. Páárí ẹ̀rẹ̀kẹ́ won i ó máa ń sún sókè sún sódò tí o bá ń sọ̀rọ̀?. (Which jaw moves up and down when you talk?)

pariwo, v.i. to make noise. Ó pariwo. (He made a noise)

pàró, n. native leather necklace. Ó fi pàró kọ́rùn. (He wore a native leather necklace round his neck.)

pààrọ̀, v.t. to exchange to barter. Mo fi kọ́kọ́rọ́ pààrọ̀ àpò. (I exchanged a key for the bag which I received.)

pa rọ́rọ́, v.i to be very calm, to be silent. Wọ́n pa rọ́rọ́. (They remained silent.)

pa rúbọ, v.t. to kill for sacrifice, to immolate. Ó pa ewúrẹ́ rúbọ. (He killed a goat as a sacrifice.)

parun, v.t. to destroy, to obliterate, to perish. Wọ́n parun. (They perished.)

pa sára, v.t. to paralyse. Ó á sára. (He paralysed him.)

pasẹ̀, v.t. to rock a child on the back to keep it quiet or make it sleep. Obìnrin náà pasẹ̀ fún ọmọ rẹ̀. (The woman rocked her child on the back to make it sleep.)

pàsi, n. a kind of coarse grass for thatching.

pàsán, patiye, n. whip, rod, scourge. Ó mú pàsán tí ó lẹ̀ dání. (He held a flexible whip in his hand.)

pàṣẹ, v.t. to command, to order. Ó pàṣẹ pé kí n jókòó. (He ordered that I sit down.)

pàṣípààrọ̀, n. exchange, barter. Mo fi kọ́kọ́rọ́ ṣe pàṣípààrẹ̀ àpò. (I exchanged a key for a bag which I receired.)

páṣù, v.t. to avoid strife, not to give the devil any chance of mischief.

paṣu, v.t. to cut yam ready for planting. Ó paṣu fún èèbù. (He cut a yam for palnting as seeds.)

pátá, n. short trousers used in working short underpants. Ó wọ pátá rẹ̀. (He puts on his short trousers.)

palà v.t. to kill for the purpose of selling. Wọ́n pa ewúrẹ́ tà. (They killed a goat and sold its meat.)

pàtàkì, adj. chief, principal, important. Ìwé pàtàkì ní (It is an important book.)

pátákó, n. plank, board. Ó kọ̀wé sójú pátákó ìkọ̀wé. (He wrote on the school board.)

pátápátá, adv. on the whole, altogether, absolutely, entirely, totally, thoroughly, completely. Ó tán pátápátá. (It is completely finished.)

pátapàta, mátamàta adj. speckled. Ó rí pátapàta. (It is speckled.)

pàtẹ; v.i. to spread or expose one’s wares for sale in the market. Ó pàtẹ ìlèḳẹ̀. (she spreads her beads for sale in the market

pàtẹ́wọ́, v.i. to clap one’s hand. Awọn ọmọ náà pàtẹ́wọ́. (The children clapped their hands.)

pátì, n. heels of the foot.

patì, v.t. to keep on one side, to neglect, to shelve, to ignore. Ó pa á tì. (He ignored him.)

pàtì, adv. forcibly, violently Ó fi eyín já ẹran pàtì. (He forcibly bit some meat.)

pàtìpàtì, adv. forcibly, violently, doggedly, Ó ń jà pàtìpàtì. (He is fighting doggedly.)

pátipàti adj. shabby, to be covered in weals Are wọ́n rí pátipàti (Their bodies were covered in weals.)

patiyẹ, n. whip, cane. Ó n ọmọ náà ní patiyẹ. (He hit the child with a cane.)

pàtó adv. exactly, definitely, gist of a metter. Sọ fún mi ní pàtó ohun tí ó sọ. (Tell me the gist of what he said.)

pàátó, pàtótó, v.i. to make noise.

pawọ́dà, v.t. to change the hand, to use money on trading with a view to make a profit. Mo ti ń fi owó tí o fún mi pawọ́dà. (I have started using the money you gave for trading.

pawọ́pẹ́, n. hand-cuff, trap. Ó kẹ́ pawọ́pẹ́ méjì fún àwọn eku náà. (He set two traps for the rats.)

pànyán-àn pọ̀nyán-àn, n. a Spaniard. Ọmọ ilẹ̀ pànyán-àn ni. (He is a spaniard.)

pàyẹ́ dà, pìyẹ́ dà, v.t. to moult (feathers). Ẹyẹ náà ti pàyẹ́ dà. (The bird has moulted.)

pé, correct (as numbers, etc., complete, perfect, to meet, to assemble. Ó pé (It is complet.)

pè, v.t. to call, to invite, to cry out, to pronounce. Ó pè mí (He called me.)

pé, cony: that, in order that. Ó sọ pé wọ́n wá. (He said that they came.)

pe àpèjọ, pàpèjọ, v.t. to call a public meeting, to convene a mass meeing. Ó pàpèjọ. (He called a public meeting.)

pa àṣẹ padà, v.t. to countermand or revoke an order. Ó ti pa àṣẹ náà padà. (He has revoked the order.)

Oju-iwe Keji[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

pébe, adv. thoroughly.

peefọ to cast off or change skin, to slough off skin. Èjò náà ti pèèfọ̀. (The snake has sloughed off its skin.).

Pẹ̀sẹ̀, Pẹ̀sẹ̀pẹ̀sẹ̀, adv. gently, easily, conveniently. Ó jókòó pẹ̀sẹ̀ (He sat down gently).

Pẹta, v.t. to sprout, to shoot out. Igi yìí ti pẹta (This tree has sprouted)

Pẹẹ́ta, adv. vigorously, warmly, fiercely. wọ́n fìjà pẹẹ́ta (They fought fiercely)

Pẹ̀tẹ́, adj. flat, even. Orí rẹ̀ tẹ́ pẹ̀té (His head is flat)

Pẹ̀tẹ́lẹ̀, n. level ground, plain. wọ́n ń ṣeré lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ (They were playing on a level ground)

Pẹ́tẹ́lẹ́, n. sympathetic, swelling on the groin


Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀, n. mud, mire, ooze. Ẹsẹ̀ wa rì sínú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ (Our feet sank into the mud)

Pẹtẹpẹ̀tẹ, adj. muddy, miry ilẹ̀ náà rí pẹ́tẹpẹ̀tẹ (The soil is myddt)

Pẹtẹrí, adv. remarkable, noticeable. Ó ṣe pẹtẹrí (He performed a remarkable feat)

Pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, v. storey building, platform. Ó kọ́ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì (He built a storey building)

Pẹ̀tù sí, v.t to appease, to throw oil on the troubled water, to settle. Mo ti Pẹ̀tù sí wàhálà náà (I have settled that trouble)

Pì adv. at once, immediately, noisily. Ó bẹ́ sódò pì (He jumped into the river noisily)

Pidán, v.i to perform sleight of hand, to do conjuring. Mo pidán (I did conjuring)

Pìjẹ, v.t. to cut grass for horse. Mo pìjẹ (I cut grass for the horse)

Pilẹ̀, Pilẹ̀ṣẹ̀, v.t. to commence to begin, to originate. Òun ló pilẹ̀ rẹ (He began it)

Pìmọ̀, Pìmọ̀ Pọ̀, v.i. to take counsel together. Wọ́n pìmọ̀ pọ̀. (They took counsel together)

Pín, v.t. to divide, to share, to distribute to allot. A pín in sí méjì (We divided it into two)

Pin, v.t. to terminate, to end. Ibí ni ọ̀nà yìí pin sí (This road ends here)

Pín fúnne, v.t. to administer to, to dispense, to distribute to, to share out amongst. Ó pín ilẹ̀ náà fúnmi (He shared out the land amongst us)

Pínní méjì, Pín sí méjì, v.t. to divide into two. Ó pín ẹran náà sí méjì (He divided the meat into two)

Pín nínú, v.t. to participate in, to partake of, to share out of. A pín nínú ẹran náà (We shared out of the meat)

Pín níyà, v.t. to part asunder, to separate. Ó pín wọn níyà (He separated them.

Pinnu, v.i to decide, to resolve, to determine. Ó pinnu láti lọ (He has decided go to)

Pinpin, adv. fast, tightly. Ó pa ojú dé pinpin (His eyes were tightly closed)

Pinpin, n. the details (of a matter). Ó tọ́ pinpin ọ̀rọ̀ náà. (He investigated the details of the matter)

Pínyà, v.i to part, to separate. A pínyà ní ṣọ́ọ̀bù náà (We parted at the shop)

Pípa, n. killing, slaughtering. Ó sọ̀rọ̀ nípa pípa tí àwọn ọ̀tá pa àwọn ọmọ aláìmọ̀kan. (He talked about the killing of the innocent children by the enemy

Pípá , adj. bald. Orí pípa kọ̀ ṣeé ru abọ́ gbígbóná. (A bold head cannot be used to carry a hot tin-bowl.

Pípadà, adj. mutable, alternate, changeable.


Pípamọ́, adj. secret, latent, dormant.

Pípani, adj. deadly, hurtful.

Pípanilẹ́rìn-in, adj exciting laughter

Pípapòdà, n. change of place

Píparí, n. that which is to be ended, conclusion,

Pípárí, n. baldness.

Píparun, n. that which may be destroyed

Pípasẹ̀ n. the act of lulling a child to sleep by dancing.

Pípàṣẹ, n. command

Pípé, adj. perfect, complete, full. Ó ṣe àlàyé pípé lórí ọ̀rọ̀ náà. (He provided full explanation on the matter.)

Pípè, n. call, invitation

Pípé pérépéré, adv. perfectly, completely.

Pípé, adj. long, durable, old, ancient. Ọjọ́ pípẹ́ ni ó gbà á kí ó tó parí rẹ̀ (He took him a long time to complete it)

Pípẹ́ títí, n. long duration. Iṣẹ́ ọlọ́jọ́ pípẹ́ títí ni (It was a contract of a long duration)

Pínpín, n. division, sharing

Pípinnu, n. resolution, determination

Pípọ̀ Púpọ̀, adj. many, much, plenty. Ó ní ìwé púpọ̀ (He has many books) pípọ̀, pípọ̀, jáde, n vomit

Pípọ́n n. ripeness, maturity

Pípọ́n, adj. ripe, mature. Ó jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ pípọ́n. (He ate a ripe plantain.

Pípọ́n lójú, n. affliction, torment.

Pípọ́nnu, n. adulation, flattery.

Pípọ̀ Pípọ̀ púpọ̀ púpọ̀, adv. abundantly, numerous, manifold, much, too much. Ó ń dààmí púpọ̀ púpọ̀. (He worries too much)

Pípọ̀pípọ̀, Púpọ̀púpọ̀, adv. abundantly, numerous, manifold much, too much. O ń dààmú púpọ̀ púpọ̀ (He worries too much)

Pirápirá, adv. entirely, completely. wọ́n sé ìlẹ̀kùn náà pirápirá. (The door is completely shut)

Pìrí pìrípìrí, adv. at once (modifying the verb ‘ṣí’ to open or remove a lid or cover), suddenly. Ó ṣí i pìrí (He opened it suddenly)

Pírípírí, adv. in short smart jumps.

Pirọrọ, v.i to pretend to be asleep. Mo pirọrọ I pretended to be asleep)

Pìtàn, v.t. to give a history of person or thing. Ó pìtàn ìlú náà fún wa. (He gave us the history of the town)

Pìtìmọ̀, Pìtìmọ̀mọ̀, adv. abundantly, innumerable. Wọ́n pọ̀ pìtìmọ̀ (They are innumerable)

Pítipìti, adv. abundantly, innumerable. Wọ́n pọ̀ pítipìti. (They are innumerable)

Pìtìpìtì adv. vigorously, strenuously (qualifying ‘Jà’, to struggle), doggedly. Ó ń jà pìtìpìtì. (He is fighting doggedly.)

Pitú, v.t. to perform a feat. Ó putí ńlá (He performed a great feat)

Pìwàdà, Pàwàdà, v.i. to change one’s behaviour and conduct, to repent. Ọlọ́run fẹ́ràn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó pìwàdà (God loves the sinner who repents)

Píye, v.i healthy, sound, normal

Piyèdà, payèdà, v.i.to change one’s mind. Mo piyèdà (I changed my mind)

Pìyẹ́, v.i. to plunder, to forage, to take plunder Àwọn ọmọ ogun náà pìyẹ́ (The soldiers took plunder)

Pò, adj. to knead, to mix, to tan leather. Ó pò wọ́n pọ̀ (He mixed them together)

Poo, adv. altogether, entirely, completely. Wọ́n ti ṣe é tán poo (They have completely finished.)

Po, adj. short, insufficient, inadequate

Pòbìrì kòtò, v.i. to form into a conclave, to form a circle. Wọ́n pòbìrìkòtò yí i ká (They formed a circle round him)

Pòfin rẹ́, v.t. to rescind a law. Wọ́n pòfin náà rẹ́ (They rescind the law)

Pòfo, v.i. to fail in an endeavour, to be unsuccessful. Ó pòfo (He was unsuccessful)

Pohùnréré, v.t. to cry alound, to lament, to bewail. Wọ́n pohùnréré. (They lamented)

Pojóbò, v.t. to make a slip-knot or noose. Wọ́n pojóbò okùn náà (They made a noose in the rope.

Pojú dà to turn away, to frown at. Ó pojú dà dí i (He frowned at him)

Pòkìkí , kòkìkí, v.t. to extol, to publish,

Pòkìkí, Kòkìkí, v.t. to extol, to publish, to spread the fame of. Wọ́n pòkìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin tí ó mọ̀wé (She was extolled as a brilliant girl)

Pòkudu, adj. gloomy, cloudy. Ojú ọjọ́ náà pòkudu. (It was a cloudy day)

Pòlà, n. the report of a gun as being audible. Ìbọn náà dún pòlà. (The report of the gun was audible)

Pòlápòlá, adj. nerveless (of teeth), sound made by a toothless person while eating. Ó ń jẹun pòlápòlá bí akáyín. (He is making the sound made by a toothless person while eating as if he is one)

Poolo, n. a place where an ordeal is to take place.

Polongo, v.t. to proclaim, to defame a person. Ọba náà polongo òfin kónílégbélé. (The king proclaimed a state of emergency)

Polówó, Polówó ọjà, v.t. to advertise one’s ware, to tout. Ó polówó ọjà rẹ̀ (He advertises his wares)


Pòlù, Pòpà, v.t. to mix together, to mingle. Ó pò wọ́n pọ̀ (He mixed them together)

Pòǹgbẹ, v.t. to quench the thirst, to slake the thirst. Mo pòǹgbẹ (I slaked my thirst)

Póńpó, n. short staff, baton

pòǹṣẹ́, Pònṣẹ́rẹ́, n. name of a tree, the shell of whose fruit is used in making snuff-box.

Poopoo, n. bamboo stick

Pópó, n. street, thoroughfare. Ó ń rìn lójúu pópó (He is walking on the street)

Pòpò, v.i to be busily engaged

Pòpòkú, Pòpòkí, n. coarse thick cloth, blanket. Obìnrin yìí ló wun pòpòkú yẹn (This coarse thick cloth was woven by that woman.

Póòpólà, n. name of a tree bearing rich scarlet flowers, the fruit of which is edible.

Pòpòndó, n. a kind of bean.

Póópòòpó, adv. tediously, at great length, cut into small pieces. Ó gé e póó pòò pó (He cut it into small pieces)

Poroporo, adv. talkatively.

Pòròpórò, n. dry stalk of corn, cornstalk

Pòròpòrò, Pẹ̀rẹ̀pèrè, adv. profusely, copiously. Wọ́n ń làágùn pòròpòrò. (They were perspiring profusely)

Pòrúúruù, v.i. to be confused, to feel bewildered. Ó pòrúúruù. (He felt bewildered)

Pósí, n. coffin. Wọ́n gbé òkú náà sínú pósí (The corpse was placed in a coffin)

Pòṣé, v.i to express impatience or dissatisfaction by making ‘pshaw’, to sigh unhappily. Ó pòṣé. (He Sighed unhappily)

Poṣù jẹ v.i. to skip a month, to be in the family way. Wọ́n poṣù méjì jẹ (They skipped two months)

Pòṣùṣù, v.i. to form into a group, to cluster round angrily. A pòṣùṣù lé e (We clustered angrily round him)

Pótopòto, adv. profusely, in abundance

Pòtútù, v.i. to feel cole, to be ill. Mo ń pòtútù (I feel cold)

Pòwe, to speak in proverbs or parable, to quote a proverb. Mo pòwe kan (I quoted a proverb)

Pòòyì, v.i tp turn rpimd, to whirl, to spin round. Wọ́n pòòyi (They spun round)

Pọ̀ adj. plentiful, many, cheap, common, great, mighty. Wọ́n pọ̀ (They are many)

Pọ̀, v.t. to throw up, to vomit. Ó Pọ̀ (He vomited)

Pọ̀, n. the sound of leather or hide when beaten, any dull sound. Ó dún pọ̀ (It gave forth a dull sound)

Pọ̀, adj. cheap, ìwé náà pọ̀ ní náírà márùn-ún The book is cheap at five naira.

Pọ̀, adv. cheaply

Pọ̀dà v.i to be of feeble mind, to, be a fod. Ó pọ̀dà (He is a fool)

Pọfọ̀, v.i to recite certain cords to bring about spell or incantation, to perform incantation on. Ó pọfọ̀ sí orí tí ó ń fọ mi láti jẹ́ kí ó rọ̀. (He performed incantation on my headache to cure it)


Pọ̀gẹ̀gẹ́, Tọ̀gẹ̀gẹ́, v.i to walk as a weak person. Ó ń Pọ̀gẹ̀gẹ́ (He is walking like a weak person)

Pọ̣̣̀gbún, v.i. to collapse, to become oval, to be of oval shape. Ó pọ̀gbún (It is of oval shape)

Pọ̀ jáde, v.t. to disgorge, to throw up. Òórùn náà fẹ́ jẹ́ kí ó pọ̀ jáde. (The smell made me want to throw up)

Pọjọ́ jẹ, v.t. to skip days. Ó pọjọ́ méjì jẹ nínú ọ̀sẹ̀. (He skipped two days in a week.)

Pọ̀ jù adj. more than, much more than. Bata mi pọ̀ ju tìrẹ. (My shoes are more than yours).

Pọ̀ jù lọ, adj. most, most of all. Òun ni ó ní owó tí ó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo wọn. (He had the most money of all of them).

Pọ̀kà Pọ̀kàkà, v.i to be in death-troes, to be struggling to die. Ó ń pọ̀kàkà ikú. (He went into death-throes)

Pọ̀ọ̀kọ́, n. a small calabash used as ladle

Pọn, v.t. to fetch water from a well or stream. Wọ́n pọn omi nínú kànga náà. (They fetch water from the well)

Pọ́n, v.t. to flatter, to sharpen knife, etc, to make much of. Ó pọ́n ọ̀bẹ náà (He sharpened the knife.)

Pọ̀n, v.t. to carry on the back (as a baby) Ó pọn ọmọ náà sẹ́yìn rẹ̣̀. (She carried the baby on her back)

Pọ́n àpọ́njù, Pọ́n àpọ́nra, adj orer-ripe, too ripe. Ká tòmáátì wọ̀nyẹn kí wọn tó pọ́n àpọ́njù. (Pick those tomatoes before they get too ripe)

Pọndan, adj. odd, solitary

Pọ́ndún, adj. ripened as corn, over-ripe and squashy. Ó pọ́ndún (It is orer-ripe and squashy)

Pọngà, adv. entirely, clean.

Pọngbẹ, v.t. to draw (well) dry. Ó pọn kànga náà gbẹ (He drew the well dry)

Pọ́n lójú, v.t. to afflict, to torment, to trouble, to give trouble. Àwọn ọmọ rẹ̀ ń pọ́n ọn lójú. (His children are giving him trouble)

Pọnmi, v.i to draw water. Ó pọnmi láti inú kànga. (He drew water from the well)

Pọnmọ, v.t. to put child on one’s back, to carry child on one’s back. Ó pọnmọ rẹ̀ sẹ́yìn rè. (She puts her child on her back).

Pọ̀nmọ́, Pọ̀nmọ́pọ̀nmọ́, adv. severely, briskly Ó ń rìn Pọ̀nmọ́pọ̀nmọ́. (He is walking briskly)

Pọ́nmú, v.t. to sharpen. Ó pọ́n àdá náà mú. (He sharpened the cutlass.

Pọnpọdọ́, n. a short underskirt)

Pọ́n ràkọ̀ràkọ̀, adj dark brown. Ó pọ́n ràkọ̀ràkọ̀. (It is dark brown)

Pọ́n rúsúrúsú, Pọ́n Ròkíròkí, adj. brown, brownish. Ó pọ́n rúsúrúsú. (It is brown).

Pọ́nsọ, v.i. to ripen as corn.

Pọntí v.t. to make or brew beer from Indian or guinea corn. Ó pọntí ọkà (He brewed beer from guinea corn)

Pọ́n yanyan adj. turned brown from sheer dirt. Ẹ̀wù rẹ̀ pọ́n yanyan. (His clothes turned brown from dirt)

Pọ̀rẹ̀rẹ̀, v.i. to indulge, to idolize, to visit with importunity, to flutter round. Labalábá náà ń pọ̀rẹ̀rẹ̀ yí àwọn àdòdó náà ká (The butterfly flutters from flower to flower).

Pọ́rọ́, easily, quietly. Ó bọ́ pọ́rọ́ (It slipped off quietly)

Pọ̀ sí i, v.i. to increase. Ó pọ̀ sí i (It increased)

Pọ̀sílán Pọ̀sóde, Bọ́sílébọ́sóde, v.i to fuss about. Síwọ́o bọ́sílé bọ́sóde kó o wá nǹkan tó wúlò ṣe. (Stop fussing around and find something useful to do.)

Pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, n. mud, mire Ẹsẹ̀ rẹ̀ rì sínú pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ (His leg got stuck in the mud)

Púkẹ́púkẹ́, adv. softly. Ó ń wú ilẹ̀ púkẹ́púkẹ́ (He digs the soil softly)

Pupa, n. redness

Pupa, adj. red, scarlet. Aṣọ yìí pupa (This cloth is red)

Pupa ẹyin, n. yolk of an egg

Púpọ̀, adj. many, much, numerous, plenty. Ó lówó púpọ̀ (He has plenty of money).

Púpọ̀púpọ̀, adv. abundantly, much, to be numerous. Wọ́n pọ̀ púpọ̀púpọ̀ (They were very numerous)

Purọ́ v.i. Ó purọ́ (He told a lie)

pútẹ́ Pútẹ́pútẹ́, adv. easily (qualifying verb ‘Já’, to cut) Okùn náà ja Pútẹ́ (The rope snapped easily)

Putu, Putuputu, adv. well (modifying verb ‘Hó,’ to lather) Ọṣẹ náà ń hó putu (The soap lathers well)