Jump to content

Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): H

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Atumo-Ede (English-Yoruba): H)

Atumo-Ede (English-Yoruba): H

habit: n; (I am in the habit of getting up late.) ìwà; bárakú Iwà mi nipé kí n máa pé jí dìde.

habitat: n; (The habitat of this fish is the deep sea.) ilé; ibùgbé Nínú alagbalugbu omi okun ni ilé eja yìí.

had: v (He had two bags of fruits yesterday, but now he only has one.) ní ó ni àpò èso meji lánàá sugbon eyo kan soso ló ní báyìí.

haggle: v; (The fruit seller wanted twenty naira for a basket of fruits, but I haggle with him and at last we agreed on fifteen naira.) ná; dún-ùn-ná-dún-rà Eni tí ó n èso náà fé gba ogún náírà fin àpèrè èso kan, sùgbon mo na an lowo rè nígbèyìn a jo fenu gúnlè lórí náírà méèédógún.

hail: n; (There was a hail storm yesterday which damage the corn.) yìnyìn yìnyìn bó lulè lánáà, èyí ti o ba agbado náà jé.

hail: v; (It was hailing yesterday.) rò hìí –kí òjò ro hìí ojó rò hìí lánàá

hair: n; (His hair is black.)irun irin oríi rè dùdú.

hairdresser: n; (My mother is a hairdresser.) onídìrí onídìríní ìyáà mi.

half: n; (We have half each.) ìlàjì; ààbò; adébù; ìdáméjì Àbààbò ni a ní níkòòkan.

hall: n; (The school hall can hold 200 people.) (The people who govern the town work in the Town Hall.) yàrá nlá Gbòngan ilé-ìwé náà lè gba igba ènìyàn. Gbòngàn Inú gbòngàn ilú náà ni àwon tí n sàkóso ìlú náà ti n sise

halt: (The can halted in front of the house.) dúró okò ayókélé náà dùró níwájú ilé náà.

halt: n; (The game came to a halt.) ìdúró ; Eré dárayá náà wa sí ìdúró.

halve: v; (My brother and I halved the orange.) pín sí ni Emi ati ègbón ní pin osàn kan náà sí méjì.

ham: n; (Would you like a piece of ham?) itan eran elédè tí a fi iyò sí N jé o ni ìfé sí itan eran eléfè tí a fi iyò sí?

hammer: n; (He gave me a new hammer.) òòlù ó fún mi ni òòlù tuntun kan

hammer: v; (She hammered the nail through the wall.) fi òòlù lù ó fi oolu lu èsò náà mó ara ìgàná.

hand: n; owó A di owo ara wa inú.

hand: v; (Hand me that plate.) fowó fún-kí a fún èèyàn ní nnkan pèlú owó fowo fún mi ni abó náà.

handbag: n; (I bought a new handbag.) àpò ìfàlówó mo ra àpò ìfàlówó tuntun ken.

handball: n; (She prefers handball to football.) bòòlù aláfowógba. Ó gbádùn bóòlù aláfowógba ju aláfesègbá lo.

hand-basin: n; (I washed my hand in a hand-basin) abo ìfowo mo fowó mí nínú abó ìfowó.

hand-cart: n; (The man was pushing his hand cart.) omolanke okùnrin náà n ti omolanke rè.

handful: n; (I put three handfuls of rice in the pot.) èkúnwó mo bu ìresì èkúnwó méta sínú ìkòkò náà.

habdicap: n; (He wanted to run in the race but his sore leg is a handicap.) adínàgboòkú; ìdíwó ó fé kópa nínú eré ìje náà sùgbón ese rè tí ó légbò ló se ìdíwó fún un.

handwriting: n; (Your handwriting is very good.) ìsowókòwé Ìsowokòwé re dára gìdigidi.

handy: adj; (The house is handy for the market.) rorùn; nítòsí ; mo níwon Ile náà mo níwòn fún ojà náà.

harvest: n; (We are all helped with the harvest.) (It was a good maize harvest.) ìgbà ìkórè Gobgbo wa ni ìgbà ìkórè náà sànfààní fún. Ìkórè-oye nnkan tí a kórè Ìkórè àgbàdo náà dáro.

harvest: v; (It is the season for harvesting the sugar.) kórè ó jé àsìkò tí a n kórè súgà.

has: v; (She has two Children.) ní ó ní àwon omo méjì.

haste: n; (In my haste I forgot to take along my hat.) ìyára; ìkánjú Nínú ìkánjú mo gbàgbé láti mú fìlà mi dání.

hasty: adj; (He ate a hasty lunch.) kánjú; yára ó je oúnje ìkánjú lósàn-án

hat: n; (She had a plastic hat.) fìlà ó n fìlà oníke kan.

hatch: n; (She passed the food through the hatch form the kitchen.) àlàfo tàbí ìbi tí ó sán lára ìgbànná ó gba oúnje náà gba inú àlafo ìgànnà láti ilé ìdána.

hatch: v; (The Chickens hatched this morning.) pa eyin; pa láti mú eyin. Awon omo adìye náà pa láàrò yìí.

hate: (I hate snakes.) kórìíra mo korìí awon ejò.

hatred: n; (She looked at me with an expression of hatred.) ìríra ó wò mi pèlú ìríra.

haul: v; (They hauled the boat onto the shore.) fà; wó wón wó okò omi náà sójú ibú.

haunt: v; (People say that the old house is hunted by the ghost a men who died there.) pààrà; kààkìrí Àwon ènìyàn so pé òkú okùnrin kan tí o kú nínú ilé àtijó náà n pààrà ibè.

hawk: n; ( The hunter killed a hawk.) àwòdì; àsá ode náà pa àwòdì kan.

hawk: v; (The woman hawked throughout.) kiri ; polówó ojà obinrin náà polówó ojà ni gbogbo ìná yesterday.

have: v; (The have gone.) (I haven’t got any fruit.) ti wón ti lo. Ní N ko tíì ní eso kankan. hay:n; (The farmer makes hay when the weather is fine.) koríko gbígbe Àgbè maa n se koriko gbígbe nígbà ti ojú ojó bag be dáadaa.

hazard: n; (There are many hazards in a journey across Africa.) ewu Ewú púpò ló wà nínú ìrìn-ajo káàkiri ile Adúláwò.

hazardous: adj; (The journey across Africa is hazardous.) léwu Ìrìn-àjò káàkiri ìle Adúlawo léwu.

haze: n; (The mountain were in haze.) ìkuukùu. Ìkuùkùu bo àwon òkè náà.

hazy: adj; (Since it was very hazy, we Couldn’t see the mountains.) tí ó ní ìkuukùu, sèkuukùu Níwòn ìgbà ti oju ọjọ́ sèkuukùu a ko ri àwon òkè náà.

he: pron; (He passed his examination.) (He is my brother.) ó ó yege nínú ìdáwò rè. Ni Egbón mi ni.

head: n; (Hit it on the head.) orí ó lùú lórí.

head: v; (The bus is heading toward the center of the town.) (The bus headed the line of cars.) (The football player headed the ball to the other side of the field.) sún mó oko akérò náà n sún mo aarin gbùngùn ìlú. Kólórí: saájú ; wà ní iwáju Oko akéro náà ló saáju àwon oko lo wà lórí ìlà. Forí gbé; forí kan:- kí a fori gbé bóòlù Agbábóòlù náà fori gbé boólù náà sí apá kejì oríi papa.

headache: (He has got a headache.) orí fífó ó ní orí fífó.

heading: n; (The heading of that book is very good.) àkolé Akolé ìwé náà dára gídigidi.

headhght: n; (The headhghts of a car show the drwer the way in front, when he is drwing at night.) iná iwájú oko Iná iwájú, okò máa n fi òye iwájú okò han awakò nigbakúùgba tí ó bá n wakò lálé.

headline: n; (The headline of the story was “Girl jumps out of burning house to safery”.)

àkole mú iwé ìròyin Akolé ìtàn mú iwé iroyìn ni pe “omobìnrin bé jade fun ìgbàla nínú ilé elé tí n jò” 

headquartes: n; (The army headquartes is not inside the town.) ojúkò; olóri elé isé ojúkò/ dú ilé-isé awon omo ogun náà kò sí n àárín ìlú.

heal: v; (Doctors help to heal people who are ill.) (The sore place on my arm has healed.) sò sàn; mú lára dá; sàn. Àwon onísègùn tó máa n wo àwon tí ara won kò dá sàn. ojú egbò tó wà ní apá mi ti sàn.

health: n; (I wish you all good health and long life.) ìlera; dídá ara Mo gbàdúrà ìlera àti èmí gígùn fún gbogbo yìí.

healthy: adj; (You look very healthy.) ní ìlera; taagun ó ní ilera dáadáa

heap: n; (The workmen left a heap of stones in our yand.) akòjopò nnkan gegele. Àwon òsìse náa fi àkójopò àwon òkùta wéwèèwè gegele sílè nínú ogbàà wa.

heap: v; (He heaped his plate wigh food.) kó jo gegele ó ko oúnje gegele sínú abóo rè.

hear: v; (I heand the rain on the rood.) (Have you heand about what happened yesterday.) gbó dídún nnkan mo gbó dídún òjò lórí òrùlé. Rí iroyin ìsèlè kan gbó N je o ti gbó nípa ohun tó selè lánàá?

heart: n; (All living things have heart.) (In the heart of the forest, wild animals lives.) okàn Gbogbo èdá alaàyè lo ní okàn Aárìn gbùngbùn Àwon eranko búburú náà gbe ní àarun gbùngbùn ìgbó náà.

heartbeat: n; ìsokúlú okàn Ìsokúlú òkàn re ti dúró.(His heartbeat has stopped.)

heartless: adj; (The heartless man beated this little boy very hard.) aláìláàánú okùnrin aláìláàánú náa na omodékùnrin rè ní ìnàkumà.

heat: n; ( Fire gives heat.) (The winners of the heats run in the chief race.) ooru ; Ìgbóna Iná máa fa ooru. Eré ìje to saájú eré ìje àsekágbá. Àwon tí o bá gbégba oróke nínú eré ìje to to saaju àsekágba oróke n sare nínú asekàgbá eré ìje. heat: v; (The sun heated the tin roof until it was very hot.) mú gbóná; ta; sí, Oòrun ta sí òrùlé onépáànù ná gbóna ti to fig bona gidigidi. heater: n; (He heated the water wigh a heater.) ero amú-nnkan-gbóná; ohun tó lè fa ooru ó lo ohun èlò ìmúnkangbóná láti mú omi náà gbóná. heathen: n; (The are all heathens.) kèfèrí; abòrisà Kèfèrì ni gbogbo won. how: adv; (How big is that bag.) lónà won- a máa n lo ìwon wìínrè wònyí í gégé bí atóka ìbéère Bawo ni àpò yen se tobi tó. however: adv; (However you do it, it will be all right.) (He greeted my parents, he greeted me however.) lónàkónà; bí o ti wù ní ònà yòówù Ní ònà yòówu tí o se é yoo dára Bákan náà O kí àwon òbí ó sì tún kí emi pèlú bákan náà. howl: v; (The dog howled when it was shalt in the house.) bí ajá. Ajá náa n hu nígbà ti won tì í mole. howl: n; (The Child gave a howl of pain.) híhu; kike hihu ìrórá in omo náà hu. hug: v; (He hugged his little daughter.) fi owó méjèèji kó móra ó fowo méjèèji kó omobìnrín kékeré rè móra. hug: n; (He gave his little daughter a hug.) ifowókánmora: Ìdìmóra; Ifàmóra O fún omódébìnrin re ni ìfàmóra

huge: adj; (There were twenty people eating, so she hade a huge bowl of rice.) títobi; nlá ogún ènìyàn ló n jeun; eyí mú kí o se abó irési nla kan.

hum: v; (Beas were humming outside the window.) kùn yùn-ùn Àwon oyin n kùn yùn-un in ojú fèrèsè ní ìta.

human: adj; (Human ear cannot hear as much as the dog’s ear.) ti ènìyan Eti ti omoènìyàn ko le gbóràn dáadáa eti ajá

humane: adj; (The army gave their prisoners humane treatment.) seun; láàánú. Àwon omo ogun náa n láàánú sí àwon eléwòn wón.

humanity: n; (Kindness is the basis of humanity.) (He is wicked, he lacks humanity.) ìwà ènìyàn; Ìsoore ni òpákùtèle ìwà omo ènìyàn. Inú rere. Ó burú, kò ní inú rere.

humble: adj; (The doctor was humble about his work, although he had cured a lot of people.) (He lived in a humble hut.) tí o ní ìrèlè; onísègùn náà ní ìrèlè pèlú isée re bí ó tile jé pé ó ti wo òpòlopo ènìyàn sàn. tí ó kéké jojo /tí kò lólá o gbé ahéré kékeré.

humbly: adv; (He greeted his father humbly.) tìrèlè tìrèlè; pèlú ìrèlè ó kí bàbáa rè tìrèlè tìrèlè.

humid: adj; (The weather is hot and humid.) tutu; rin ojú ojó móorú o sí tún rin.

humidity: n; (On a wet day, the humidity is high.) ìtutu; òrinrin Nìgbà ti ojú ojó bá tutu. Òrinrín ojú ojó máa n pò

humiliate: v; (My mother told everyone of lthe silly things I had done as a Child and I felt humiliated.) rè sílè; tè lórí ba. Ìyáà mí so àwon ohun èègò ti mo ti se ní kékere fún gbogbo ènìyàn; èyì mu mi ni ìrèsílè ní okàn mí.

humiliation:n; (It was a humiliation for me.) ìrèsílè; ìrèlóríba Ó jé ìresílè kan fún mi.

humility: n; (The doctor talked about his work with humility.) ìrèlè onísegùn náà sòrò nípa isé rè pèlú ìrèlè.

humorous: adj; (He told me a humourous story.) apanilérìn-ín ó so ìtàn apanilérìn-ín fún mi.

humour: n; (I like the man because he has a good sense of homour.) èfè mo féràn okùnrin náà torí pe o féràn èfè.

hump: n; (There is an aminal called a camel which has a hump.) ikéEranko kan wà tí a n pe ní rakùnmi tí o máa b ní iké.

humus: n; (The humus is very fertile.) ìlèdú Ìlèdú náà lóràa dáadaa.

hundred: n; (Twenty times five is equall to hundred.) ogórun-ún; òrún ogún lónà márùn-ún jé ogórùn-un. hundred: adj; (He gave me a hundred cows.) ogórùn-ún; òrún o fún mi ni ogórùn-un màálu.

hundredth: adj; (This is the hundredth time I’ve told you to wash your face!.) tí ó jé ìgbà ogórun-ún Eyi ni ìgbà ogórùn-un ti mo ti so fún o pé kí o máa bójú ré!.

hung: v; (He hung the cloth.) fi kó; so rò ó fi aso náà kó.

hunger: n; (If you have nothing to eat for a day, you feel geat hunger.) ebi Tí o ko ba rí nnkan kan je fún ojó kan, ebi púpò yóò pa o.

hungry: adj; (The hungry lion killed the goat.) tí ebi n pa kìniún tí ebi n pa naa pa ewúré.

hunt: v; (Some people hunt birds as a sport.) sode; dode Àwon èèyàn kan máà n dode àwon eye gégé bí eré ìdárayá.

hunter: n; (A man who hunts animal or birds is a hunter.) ode ode ni okùnrin tí o n dode àwon eranko tàbi àwon eye.

hunrl: v; (He husled the brick through the window.) fi soke kíkan kíkan; jù tágbára tagbára.Ó fi bíríki náa sòkò; kíkan láti ojú fèrèsé.

hurricane: n; (Many houses were badly damaged in the hurricane.) ìjì líle òpòlò àwon ilé ló bàjé nínú nínú ìjì líle náà.

hurry: v; (I am late- I must hurry(up).) yára síra mo tip é-mo gbódò yára

hurry: n; (You always seem to be in a hurry.) ìsírá; ìyára; ìkánjú o máa n wà ní ìkánjú/ìyára ni ìgbà gbogbo.

hurt: v; (I hurt my leg when playing football.) pa lára; se lose; fi pa. Mo fie se mi pa nígbà ti mo n gba bóòlù alafesegbá.

hurt: n; (I experience left me with a feeling of deep hurt.) ìpalára Ìrírí náa mú ìpalára okàn tí ó le bá mi.

husband: n; (My husband is a farmer.) oko; okolóbìnrìn Àgbè ni okò mi.

hut: n; (The man who works in the garden keeps his tools in a hut.) ahéré okùnrin tí o n sise nínú ogbà náa máa n ko àwon ohun elo re sínú ahere kan.

hutch: n; (He kept the cats in a hutch.) àgò ó pa àwon ológìnní náà mó sínú àgò.

hubrid: n; (A mule is a hybrid because its parents are a house and a donkey.) àdàmòdì Àdàmòdì nì ìbákasíe torí pé esin àti ràkunmi ni wón bí í.

hydro-electric: n; (Hydro-electric prower is generated when there are rivers and mountains.) ináa mònàmóná tí a sèdá pèlú omi A le sèdá máa mònàmóná tí ti a fi omi se nibi ti àwon òkè pèlú àwon odò bá wà.

hyena: n; (The hunter killed two hyenas.) ìkoòkò ode náà pe ìkooko méjì.

hygiene: n; (Hygiene when you are about or your may become ill.) èkó nípa ìlera ó dara kí ó ní èkó nipe ìlera nígbà ti o bá n se ounje bí ì béè ko o lè dì aláìsàn.

hygienic: adj; (The food is not hygienic.) mó; ní ìmótótó oúnje náà ko ní ìmótótó.

hymn: (They have started saying the hymns.) orin mímó; orin ìsìn won to bèrè sí ni ko awon orin ìsìn náà.

hypocrisy: n; (He abores hypocrisy.) ìwà àgàbàgebè; ìwà àìsìótó ó kórìíra ìwà àgàbàgebè.

hypocrite: n; (You are just a bunch of hypocrites.) alágàbàgebè òkùúrú alágàbàgebè ni gbogbo yín.