Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): I

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Atumo-Ede (English-Yoruba): I)

Atumo-Ede (English-Yoruba): I

i: pro; (I asked her to help me.) mo, mo so fún un kí ó ràn mí lówó.

ice:n; (He put some ice in his drink to make it cold.) omi dídì; yìnyìn ó ju yìnyín sínú ohun mímú rè kí ó bàa lè tutu. ice-cream: n; (He drank ice-cream yesterday.) wàrà oníyìnyìn; ó mú wàrà oníyìnyín lanáà.

icy: adj; (My hands were icy when I came out of the water.) tutu púpò, owó mí tutu púpò nígbà tí mo jade síta nínú omi.

idea: n; (He had an idea that she would come and see him.) mú; èrò ó ní èrò pé yóò wà rí oun.

ideal: adj; (This is an ideal place to live- it has a big garden and it is very near the sea.) àpeere tí ó dára jùlo Àpeere ibi tí ó dára jùlo láti máá gbe ní ibíyìí- o ní ogbà tí o tóbi, o sì sún mó etí òkun pékípékí.

identical: adj; (The two bowls are identical.) bákan náà gégè; bá mú ohun kan náà Àwon opón méjèèji bára won mu.

identification: n; (Have youchad any identification? ìdámò N jé o ní ìdámò kankan?.

identify: v; (Can you identify the three plants in the picture?) mò; mò dájú N jé o lè mo àwon irúgbìn métèèlta inú awòrán náà?

identity: n; (Can you prove your identity?) ohun ti ènìyàn jé N jé o le so eni tí o jé?

idiom: n; (“I’ve got cold feet”doesn’t only means that my feet fell cold, it means that I am frightened- it is an idiom.) àkànlò èdè “Ese mí dì lútù”kò túmò sí èsè mi n tutu nìkan, ó túmò sí pè èrù bà mí- àkànlò èdè ní.

idle: adj; (The idel girl spent all day looking out of the window.) lẹ; láìlè sisé; omodébìnrin tí kolè sisé naa lo gbogbo ojó láti fi yojú lójú fèrèse.

idol: n; (There were some wooden idiols that the people prayed to.) ère; orisà Àwon ère igi kan wà tí àwon ènìyàn nlá máa n gbàdúrà sí.

if: conj; (If you lend me your bicycle, I will clean it for you.) (I don’t know if he will go or not.) bí tí, Bí o ba yá mí ní kèkéè rẹ n ó bá o nù. Bóyá N kò mò bóyá yóò lo tàbí ko níí lo. ignite: v; (He lit a match and ignited the dry sticks.) gbiná; dána sum; tiná bò ó sa ìsáná kan ó sì tína bo àwon ìgì gbígbe náa.

ignition: n; (Our car wouldn’t work because there was something wrong with the ignition.) ète/ èro tí o n mú okò sisé okò ayókélé wa kò lè sisé tori pé nnkan kan ti selè sí ohun tí o le mú un sisé.

ignorance: n; (Her ignorance about her own country is suprising.) àìmòkan, àìlóye; òpè. Àìlóye re nípa orílè-èdè rè yani lénu.

ignorant: adj; (Little Children are ignorant, so they go to school to learn things.) làìmò; yopè; láìmòye. Àwon omode ko mòye ohunkohun ìdi nìyí ti wón fi n lo sí ilé-èkó lati kékòó.

ignore: v; (I tried to say something but the teacher ignored me.) sàìkàsì; fojú fò dá mo gbìyànjú làti so nnkan kan sugbon olùkó ko kà mi sí.

ill: adj; (She is ill today and must stay at home.) sàìsàn ó n se àìsàn lónìí, o sì gbódò dúró nìlè.

ill: adv; (The Cruel man ill-treated his Children.) búburú okùnrìn ìkà náà se àwon omo re ni ìsekúùse.

illegal: adj; (It is illegal to take things belonging to other people.) lòdì sí òfin ó lòdì sí òfin láti máa mú ohun olóhun.

illegible: adj; (His handwriting is illegible.) tí o sòróó kà Ìsowokòwé rè sòróó kà.

illegitimate: adj; (He is an illegitimate Child.) tí a kò bí ní ipò ìgbeyàwó, ní ònà àìtó; Omo ààlè omo ààlè ni.

illiteracy: n; (Every year whe have more schools so that we can get rid of illiteracy.) àìmòóko-mòókà odoodún lá n ní àwon ilé-ìwé sí i láti dékun àìmòóko-mòókà.

illiterate: adj; (Many people in the world are illiterate.) aláìmòóko-mòókà òpòlopò ènìyàn nlé ayé ló jé aláìmòóko-mòókà. illness: n; (He has had a bed illness, but he is better new.) àìsàn; amódi Aisan búburu se é sùgbón are re ti dá bájìí.

illuminate: v; (They illuminated our strrrts with coloured lights.) tan ìmólè si Wón tan ìmólè sí àwon ònà wa pèlú àwon iná aláràbarà.

illumination: n; (The faint illumination of that bulb will soon go out.) ìfunni ní ìmólè. Ìmóle léúléu tí o n jade lójú gílóòbù year ko ní pé ku.

illusion: n; (She is under the illusion the he loves her.) ìsìnà ètàn; irújú ó wà nínú ìsìnà pe ó féràn òun.

illustrate: v; (This picture illustrates the cotton plant.) se àpeere; se àpèjúwe Àwòrán yìí n se àpeere igi òwú.

illustration: n; (The illustrations in the magazine were drawn by Ali.) àwòrán; ìfihàn; ajúwe Alí ló ya àwon àwòrán inú ìwé ìròyìn náà.

image: n; (Muslims do not allow any image in their mosques.) àwòrán; ère Àwon mùsùlùmí kìí gba aworan ère kankan nínú àwon mosálásí won.

imagine: v; (Do you imagine I am going to stop your game? You are wrong.) rò; wòye; gbèrò se o rò pé n ó dá eré ìdárayá re duro ni? O sì í.

imam: n; (The man is an imam.) dórí èsìn musulumi; lèmómù olórí èsìn mùsùlum/ lèmó mù ní okùnrin náà.

imitate: v; (He always imitates his elder brother.) tèté; se àfarawé; sín je ó máa n sàfarawé ègbón-on rè okunrin.

imitation: n; (He learns by imitation.) (This isn’t a real gun-it’s only an imitation.) àpeere; àfarawé; ìsíje ó n kékòó pèlú afarawe/ìsínje. Ayédèrú: Eléyìí kìí se ìbon gidi-ayédèrú ni.

immediate: adj; (I live with my immediate family.) lógan; lójú kan náà tí ó sún mo pékípékí mo n gbe pèlú àwon ebíì mi to sún mo mi pékípékí. immediately: adv; (She came immediately.) lógàn; ní wérèwéré ó dé lógán.

immense: adj; (He made an immense amount of money in the business.) tóbi púpò; láìní ìwòn ó lo owo tí o pò púpò sórí isé náà.

immensely: adj; (I am immensely pleased to have this job.) púpò; lópòlopò ó wù mi púpò láti ní isé yìí.

immigrant: n; (The are all immigrant.) eni ti o ti oríle-èdè òtò wá máa gbé orílè-ede kan: àtìpò. Àtìpó ni gbogbo won.

immigrate: v; (Some people immigrated from the neighbouring country.) wá sínú ìlú kan tàbí orílè-èdè kan láti máa gbé Àwon ènìyan kan sí wo orílè-edè yìí láti orílè-èdè àmúegbe láti máa gbé.

immigration: n; (The rate of immigration is increasing nowadays.) ìsílo sí ìlú nìíràn Ìsílo sí ìlú mìíran ti n pò si láyé òde òní.

immoral: adj; (It is immoral to cheat people.) láìní ìwà rere; búburú ó buru láti máà yan àwon ènìyan je.

immortal: adj; (Many people believe that the body dies but the soul is immortal.) tí ko lè kú; tí kò lè díbàjé. Òpòlopò àwon eniyan ló gbàgbó pé are ló n ku sùgbón èmí kìí kú.

immunize: v; (Have you been immunized against yellow fever.) fún lóògùn láti fí dènà irúré àìsàn kan. N jé wón ti fún o lóògùn láti fi dènà ibàa pónjú?.

immunization:n; (Immunization against serious illness is very important.) ìfúnlóògun láti fí dènà àìsàn tàbí àrùn Ifúnlóògùn /Ìloògùn láti fí dìnà àìsàn búburú se pàtàki.

impatient: adj; (It is of no use getting impatient when you are waiting for the train to come.) laíní; sùúrù; ní wàràwàrà kò ye kí ènìyàn se aláìnísùúrù ni sùúrù tí o bá dúró de rélùwéè/ okò ojú irin láti dé.

imperative: adj; (“Go away”is an imperative sentence.) (It is absolutely imperative that we make a quick decision.) tasetàse; ti àse ‘Maa lo”jé gbólóhùn ase tí ko seé yè tàbí tí kò seé fí falè ó ye ni kankan kí a tete se ìpinu.

impertinent: adj; (She scolded her son for being impertinent.) yájú ó bá omo rè okùnrin wí tóri pè ó yájú.

impertinence: n; (She scdded hers son for his Impertinence.) òyájú ó bá omo rè okùnrin wí tórí ìwà òyájú tí o ní.

implement: n; (The men mending the road had left their implements in a hut.) ohun èlò isé Àwon okùnrìn tí ó n tún ojú ònà náà se ti fi àwon ohun èlò isé won sílè sínú ahéré kan. implore: v; (She implored the robber not to take all her money.) bè; bèbè ó be adigunjalè náà kí ó má kó gbogbo owó òun.

impolite: adj; (I think it was impolite when I asked the old woman how old she was. láìyénisí; láìmásà Mo rò pe kò yémisi nígbà mo bèrè lówó obìnrin agbàlagbà náà pé omo odún mélòó ni?

import: v; (We imported machinery we cannot make in our country.) (Machine is one of our imports.) mú láti òkèèrè wòlú A ra àwon èro tí a kò lè se ní oríle-èdè wa wòlú láti òkèèrè. Èró jé òkan lára àwon ojà tí a máa n kó wòkú láti òkèèrè.

importance: n; (The importance of telling the truth cannot be doubted.) pàtàkì pàtàkí òtíto sísò ko se e fowó ró ségbèé.

important: adj; (It is important that we tell the trugh.) tí o se pataki ó se patakí kí a so òtító.

impose: v; (A new tax was imposed on the people of the country.) bù fún; gbé lé lórí Wón gbe owó orí tuntun ni sísan le àwon ènìyàn orílè-èdè náà lórí.

impossible: adj; (I cannot come today if it is impossible.) tí kò seése N ko lè wa lónìí tí ko bá seé se. impress: v; (The teacher was not impressed with my work.) jo lójú Isé mi kò jo olùkó náà lójú.

impression: n; (The talk made a great impression on me.) àmì; èrò okàn tàbí ìwòlókàn òrò náà ní àmì gidigídí lára mi.

impressive: adj; (His work was very impiessive.) lámì; joni lójú Isé rè joni lójú jojo.

imprison: v; (He was imprisoned for two years.) há mó mú túbú fi sí èwòn Wón jù u séwòn fún odùn méjì.

imprisonment: n; (He was given two year imprisonment.) ìhàmò-inú-túbú; ìfisínú-èwon ó gba ìfusínu-èwon odún méjì.

improve: v; (I think you should improve your hardwriting: at the present- it is very bad.) tún se; mú dára sí í Mo ro pé ó ye kí o tún ìsowokòwéè re se, ní bàyìí ó burú yìí.

improvement: n; (There have been great improvements in your work’but your writing still needs improverment.) atúnse; imúdára-síi. Àwon àtúnse gidi ti n wà nínú iseè rè sugbón ìsowókòweé rè sì n fé àtúnse.

impulse: n; (I had an impulse to go and visit my uncle in Lagos.) òòfà okan Mo ní òòfà okàn láti lo be abúrò bàbáà mi wò lékòó.

impulsive: adj; (He is impulsive, always doing whatever comes into his mind without thinking about what will happen.

ní oòfà okàn ó máa n ní òòfà okàn, nípa sise ohun yóòwù tó bá ti wá sí i  lókàn láìro ohun tí yòó selè.

in: prep; adv; (We live in Africa.) ní A n gbé ní Áríríka.

inadequate: adj; (The food was inadequate for ten people.) tí ko tó/ láìtó óúnje náà ko tó fún ènìyàn méwàá.

imcapable: adj; (Since her accident, she has been incapable of walking.) láìlèse; láìlágbára. Lati ìgbà tí o tí ní ìjànbá, kò tíì légbára àtilè rìn. inch: n; (My finger is two inches long.) idámejìlá ìwon ese kan. Èékánná mi gùn tó ìdáméjì nínú idáméyìlá ìwon ese kan.

incident: n; (There is an interesting incident in the story where the boy goes to his friend’s party.) ìsèlè; alábàápàde Ìsèlè tí ó dùn móni wá nínú ìtàn náà, níbi tí omokùnrin náà ti lo sí ibi àsè oreé rè.

incline: v; (The road inclined towards the top of the mountain.) tè sí; wó sí ònà náà lè sí apa ibi orí òkè náà.

inclination: n; (My inclination is to study at an art college.) ìfé okàn Ifé okàn mi ni láti kékòó nílé èkó giga ti isé-onà.

inclide: v; (I inclided my uncle in the list of people to thank.) fi pèlú; kà kún; kà mó Mo ka ègbón iyá ni mó àwon tó ye ká dupe lówóo won.

income: n; (Part of her income comes from her shop, and part from teaching dancing in the evenings.) owó tí a pa wolé Apá kan lára owo tí ó pa wolé wá láti bi ilé ìtàjà re, apa kan láti ara èkó ijó jíjó tí o n kóni ni ìròléìròlé.

incomplete: adj; (The materials are incomplete.)  tí kò pé; sàìkún Awon ohun èbò náà kò pé.

inconvencent: adj; (This table is at an inconvencent hight – it is just too high for me to see what is on it.) sàìrorùn; sàìye Gba labile yìí sàìrorùn fún mi- ó ti ga jù fún ni lati rí rí ohun to wà lóríi rè.

inconvenience: n; (The inconvencence of this table annoys me.) àìrorùn, Àìrorùn tábìlì yìí n bí mi nínú.

incorrect: adj; (The answer to the question is incorrect.) tí kò rí béè; tí ko bam u Idáhùn sí ìbéèrè náà ko bamu.

increase: v; (My wages has increased this year.) fi kún; pò si owó osù mi tip ò sí ní odún yìí. increase: n; (I have had an increase in my wages.) ìbísíi; àsun kún; àfikun Mo ti ní àfikún nínú owo osù mi.

indeed: adv; (He runs very fast indeed.) nítòòtó; gidigidi ó máa n yára sára dáadáa nítòótó.

indefinite: adj; (I am staying for an indefinite time.) (I asked him when he would go abroad, but he gave me an indefinite answer.) tí kò lópin Mo n dúró fún àsìkò tí kò lópin. tí kò dájú Mo bèèrè lòwó rè àsìkò tí yóò lo sí òkè òkun sùgbón o fún mí ni ìdáhùn tí kò dàjú.

independent: adj; (She lives away from home, she is independent. olómìnìra; ti òmìnira o n gbe nibi tí o jìnà sílé, o ni omínira.

independence: n; (America gained its independence in 1776.) òmìnira Ilè Améríkà gba òmìnira ní odún 1776.

index: n; (The texts have many indexes.) ìtókasí Àwon ìwé náà ni àwon ìtókasi púpò.

indicate: v; (Was there any evidence to indicate that he planned to return?) fi hàn, tóka sí N jé èrí kankan wà láti tóka sí wí pé o gbèrò àti padà?.

indication: n; (There is no indication that you have worked hand.) ìtókasé, àpeere kò sí ìtokasí pe o sise dáadáa. 

indicator: n; (High profit is one of the indicators of company good performance.) (His left hand indicator is flashing.) atóka; asàfihàn; àmì Èrè goboi jé ara àwon àmi pé ilé-isé náa sisé dáadáa. ète ti ó máa n se àfihàn nnkan fúnni. Ète are okò tí ó wà ní apa otún okò rè ti o n sàpèjúwe pé okò fé yà sí apá òtún n tàn.

indigenous: adj; (The coconut palm is indigenous to Africa.) tì ilè; ti ilú náà Ilè Afíríkà ni igi àgbon náà wà.

indignent: adj; (I was indignant because Samuel had been punished linfairly.) bínú; runú Mo bínú torí pè won je sámúétì níyà lónà àìtó. indignantly: adv; (“It isn’t fair”! She said indignantly.) pètú ibínú; pèlú ìrunú“kò dáa béè”! ó sòrò pèlú ìbínù.

indigo: n; (He dyed his cloth with indigo.) aró olóun búlúù ó pa aso rè lároó búlúù.

indirect: adj; (He went to the house by am indirect road.) tí kò se tààrà ó gba ònà ti ko se tààra lo sí ilé náà.

indirectly: adv; (He gave her the book indirectly.) láìse tààrà ó fún un in iwé náà láìse tààrà.

individual: (The Children had individual desks.) ení kòókan; olúkúlùkú olúkúlùkù àwon omo náà ni aga rè.

individually: adv; (Individually, I like the Children, but I find them too noisy in a group.) níkòòkan Mo féran àwon omo náà níkòòkan sugbon lápapo mo rí pé won náa n pariwojù.

indoor: adj; (If it rains, we play indoor games.) ti inú ilé Nígbà tí ojo bá n rò, a máa n se àwon eré ìdárayá tó je mo ti inú ilé.

indoors: adj; We stayed indoors because it was raining.) nínú ilé A dúró nínú ilé torí pé òjò n rò.

industry: n; (Our town has a lot of industries.) ilé-isé; ibi ìsòwò Ilú wa ní òpòpo ilé-isé.

industrial: adj; (That is an industrial town.) tí ó ní òpòlopò àwon ilé-isé Ilú tí ó ní òpòlopò ilé-isé nìyen.

industrious: adj; (The man is industrious.) lápon okùnrin náà láápon.

infancy: n; (From his infancy he has been interested in machines.) ìgbà omodé; ìgbà èwe Láti ìgbà omódé re ló ti ní ifé nínú àwon èro.

infant: n; (The nurse told the young mothers about medical care for infants.) omo owó olùtójú àwon alàìsan náà so fún àwon òsóóró abiyamo nipa síse itójú àwon omo owó won pèlu oògun ìtójú. infect: v; .(One of the Children had a fever, and three other Children in his class were infected with it.) ràn mó òkan nínú àwon omo náà ní àìsàn ibà, èyí tí ó ràn mó àwon omo méta yòókù tí wón wà nínú kíláásì rè

infection: n; (Have you got an infection.) akóràn; arànmó Tàbí o ti ní àkóràn àìsàn.

infections: adj; (An infections illness is one that you can give to other people.) tí o le ranni Àrùn tí ó lè ràn in irúré àrùn ti o lè kó ran àwon mìíràn.

infinite: adj; (ifinite space surrounds the Earth.) láìlópin ; láìnípèkun Aàyè tí kò lópin ló yí ilé po

infinitively: adv; (It is infinitively very much easier to drive a can than to understand how it works.) gidigidi; púpòpúpò ó rorùn gidigidi láti wa okò ayokélé ju láti mò bí ó ti n sisé lo.

infinity: n; (He gazed into infinity.) àsìkò tàbíààyè tí kò ní ìpekun ó bojú wo ibi tí kò ní ìpekun.

inflate: v; (The types of the bicycle must be inflated to the right pressine.) (He inflated the price of the goods.) fi aféfé kún A gbódò fé ìwòn atégùn tó ye sínu awib táyà kèkè náà. Fè sókè; sún sókè Ó sún owó ojà náà sókè.