Jump to content

Atúmọ̀-Èdè (Gẹ̀ẹ́sì-Yorùbá): P

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Atumo-Ede (English-Yoruba): P)

Atumo-Ede (English-Yoruba): P

profanation, n. ìbàjẹ́, ìsọdi àìmọ́ ài`lọ́wọ̀ fún

profane, adj. (He used profane words) ó lo àwọn ọ̀rọ̀ àìmọ́

profane, v.t. sọ di àìmọ́ (They profane the name of God) Wọ́n sọ orúkọ Ọlọ́run di àìmọ́

profanity, n. ìbàjẹ́ àìlọ́wọ̀ (A string of profanities came from his lips) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbàjẹ́ ńm ti ẹnu rẹ̀ jáde

profess, v.t. and i. jẹ́wọ́ sọ ní gbangba (He professes islam) Ó jẹ́wọ́ ẹ̀sìn Mùsùlùmí

profession, n. ìjẹ́wọ́, ìpè, ìṣe (He is a lawyer by profession) Iṣẹ́ agbẹjọ́rò ni ìpè rẹ̀

professor, n. ọ̀jọ̀gbọ́n, olùkọ́ ńlá ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, olùkọ́ àgbà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga. (He is professor of Yorùbá language) Òjọ̀gbọ́n èdè Yorùbá ni

proffer, v.t. fi bùn, fi tọrẹ, là hàn

proficiency, n. ìlọsíwájú, ìmípé (He obtained a certificate of proficiency) Ó gbe èwé-ẹ̀rí ìmúpe

proficient, adj. yíyẹ, tító, pípé

profile, n. àwòrán orí tàbí ojú, àwòrán ẹ̀gbẹ́ orú tàbí ojú (I saw a portrait drawn in profile) Mo rí àwòrán tí wọ́n ya ẹ̀gbẹ́ orí sínú rẹ̀

profit, n. èrè, àǹfààní (He gained profit in his studies) Ó jẹ àǹfààní ẹ̀kọ́ rẹ̀

profit, v.t. and i. jèrè (It profited him nothing) Kò jèrè kankan nínú rẹ̀

profitable, n. ní èrè (It was a profitable investment) Okòwò tí ó bí èrè ni

profligate, adj. nínà-ánkúnàá, nífẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́, níwà burúkú (He was profligate of his inheritance) Ó ná ogún rẹ̀ nínà-ánkúnàá

profligate n. oníwà búburú, orúfẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́ (He was a profligate person) Oníwà búburú ènìyàn ni

profound, adj. jinlẹ̀, jinlẹ̀ ní ìmọ̀ (He has a profound interest in the case) Ó ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ náà

profoundness, profundity, n. ìjìnlẹ̀, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, jínjinlẹ̀ (They talked about the profundity of his) Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa jínjinlẹ̀ ìmọ̀ rẹ̀

profuse, adj. pọ̀ rékọká (He gave gratitude to God) Ó fi ọpẹ́ tí ó pọ̀ rekọjá fún Ọlọ́run

progenitor, n. baba ńlá (Odùduwà wa the progenitor of the Yorùbá) Odùduwà ni baba ńlá àwọn Yorùbá

progeny, n. ìrandíran, ọmọ (The Yorùbá are the progenies of Odùduwà) Ọmọ Odùduwà ni àwọn Yorùbá

prognosis, n. ìmọ̀tẹ́lẹ̀, ìsọtẹ́lẹ̀ programme, n. ìwé ètò ohun tí a ó ṣe ní ìpàdé, ewé iṣẹ́, ètò (What are the programmes for tomorrow?) Kí ni àwọn ètò fún ọ̀la? progress, n. ìlọsíwájú, ìmúsàn (He made progress in his studies) Ó ní ìlọsíwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ progress, v.i. lọ síwájú, mú sàn (The work is progressing steadily) Iṣẹ́ náà ń lọ síwájú dáadáa

progression, n. ìlọsíwájú, ìpọ̀sí i (He talked about the different modes of progression) Ó sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣI ọ̀nà tí ènìyàn fi máa ń ní ìlọsíwájú

progressive, adj. ń lọ síwájú (Ours is a progressive political party) Ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó ń lọ síwájú ni tiwa

prohibit, v.t. kọ̀ fún, dá dúró, ṣòfun, dí lọ́nà, dá lẹ́kun. Kà léèwọ̀ (Smoking is prohibited in our house) Wọ́n ka sígà mímu léèwọ̀ ní ilé wa

prohibition, n. ìkọ̀fún, ìdádúró, ìdínà. ìdálẹ́kun. èèwọ̀, ìsọ̀fin (There is a prohibition against the use of dirty water in that house) Èèwọ̀ wà fún ìlò omit í kò dára nínú ilé yẹn

prohibitive, adj. ìdádúró. kíkọ̀fún (They paid a prohibitive tax) Owó-orí tí ó nílò kíkọ̀fún ni wọ́n ń san

prohibito, n. adánilẹ́ẹ̀kun (He is a prohibitor) Adánilẹ́ẹ̀kun ni

project, n. ìrò, ìgbèrò (He talked about the project to establish a new school) Ó sọ̀rọ̀ nípa ìgbèrò láti dá ilé-ẹ̀kọ́ tuntun sílẹ̀

project, v.t. and i. yọrí jáde, gbìrò (He is projecting a new school) Ó ń gbìròilé-ẹ̀kọ́ tuntun

profilic, adj. ní ìbísí, híhù, léso, kún fún (She is as prolific as rabbits) Ó ní ìbísí bíi ti ehoro

prologue, n. ọ̀rọ̀ ìṣáájú (I read the prologue to the book) Mo ka ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé náà

prolong, v.t. fà gùn, mú pẹ́ sí i, dúró títí, falẹ̀, mú pẹ́ (He prolonged his holiday) Ó mu ìsinmi rẹ̀ pẹ́ sí i

promenade, n. ìgbafẹ́fẹ́, ọ̀nà ìrìn ní gbàngba

promenade, v.t. and i. rìn, gba afẹ́fẹ́ (He promenade his children along the coast) Ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ rìn ní etí òkun

prominence, n. ìyọrí, ìhàn ketekete, híhàn ketekete, ìyọrí soke (He brought it into prominence) Ó mú un wá sí ìyọrí sókè

prominent, adj. yọrí, hàn ketekete, lókìkí (He occupied a prominent position) Ipò tí ó lókìkí ni ó wà

promiscuous, adj. dàpọ̀, dàrúdàpọ̀

promise, n. ìlérí (He kept his promise) Ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ

promise, v.t. and i. ṣe ìlérí (He promised to be here) Ó ṣe ìlérí láti wá síbí

promising, adj. ní ìrètí pé yóò dárá, fúnmi ní ìrètí (It is a promising result) Èsì ìdánwò tí ó fúnmi ní ìrètí ni

promontory, n. ìyọrí ilẹ̀ nínú òkun, ṣóńṣó ilẹ̀. ògógóró

promote, v.t. gbé ga, gbé lékè, sún síwájú (I was promoted to the rank of a clerical officer) Wọ́n gbé mi ga sí ipò akọ̀wé

promoter, n. agbénilékè, aláàtiṣe

promotion, n. ìgbélékè, ìsún síwájú. Ìgbéga (He gained promotion) Ó ní ìgbéga

prompt, adj. múra, kánkán, ṣe tán, láìdára dúró, ní kán-ń-kánsì (He gave a prompt reply to my letter) Ó dá èsì ìwé mi padà ní kán-ń-kánsì

prompt, v.t. sún ṣe, mú ọ̀rọ̀ sí ìrántí (When prompted you to do it? Kí ló sún ọ ṣe é?

prompter, n. aṣínilétí

promptitude n. ìmúra gírí

promptness, n. kíákíá, ní kán-ń-kánṣì

promulgate, v.t. kéde, tàn kálẹ̀, wí kiri

promulgation, n. ìtànkálẹ̀, ìkéde

prone, adj. fà sí, tẹ̀ sí (Some people are accident prone) Àwọn ènìyàn kan máa ń fà sí àgbákò

proness, n. ìfàsí, ìtẹ̀sí

prong, n. ẹ̀gún, ohun èlò bí àmúga, àmúga (He bought a three-pronged fork) Ó ra fọ́ọ̀kì oní-àmúga mẹ́ta

prong, v.t. fi gún

pronoun, n. ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ, ọ̀rọ̀ tí a lò dípò àpólà orúkọ tàbí ọ̀rọ̀-orúkọ (The word, ‘me’, is a pronoun) Ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ni ọ̀rọ̀ yìí, ‘emi’

pronounce, v.t and i. pè, sọ̀rọ̀ (How do we pronounce b-r-o-o-m?) Báwo ni a ṣe ń pe ọ-w-ọ̀?

pronunciation, n. ìpe, ìsọ̀rọ̀ (Study the pronunciation in Yorùbá) Kọ́ ìpe èdè Yorùbá

proof, n. àmì, ẹ̀rí (Is there any proof that you were at home?) Ǹjẹ́ ẹ̀rí wà pé o wà nílé?

prop, n. ìtìlẹ́yìn (He is the pop of his parents at old) Òun ni ìtìlẹyìn àwọn òbí rẹ̀ ní ọjọ́ ogbó wọn

propaganda, n. ọ̀nà ìtànkálẹ̀ (It was a political propaganda) Ọ̀nà ìtànkálẹ̀ òṣèlú ni

propagate, v.t. mú bí sí i, pọ̀ si i, tàn kálẹ̀ (Try to propagatethe news ) Gbìyànjú láti tan ìròyín náà kálẹ̀

propagation, n. ìdàgbà. Ìwú, ìpọ̀ sí, ìtànkálẹ̀ (He talked about the propagation of disease by insect) Ó sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn kòkòrò ṣe ń ṣe ìtànkálẹ̀ aìsàn propel, v.t. tì síwájú, lé síwájú, wà (bí àjẹ) (The boat is propelled by oars) Àjẹ̀ ni wọ́n fi ń wa ọkọ̀ ojú onu náà

propeller, n. àjẹ̀-ọkọ̀

propensity, n. itẹ̀sí, ìfàsí, ìfẹ́ sí (He has a propensity to exaggerate.) Ó ní ìfẹ́ sí sísọ àsọdùn.

proper, adj. yẹ, tọ́, dára. (Nothing is in its proper palce.) Kò sí nǹkan kan tí ó wà ní àyè ibi tí ó tọ́ sí i.

properly, adv. ní yíyẹ, ní títọ́, dáradára. (The telephone is’t working properly.) Telifóònù náà kò ṣiṣẹ́ dáadáa.

property, n. diun ìní, ìtásí (That building is government property.) Ohun ini ìjọba ni ilé yẹn.

prophecy, n. ìsọtẹ́lẹ̀ (She was behieved to have the gift of prophecy.) Wọ́n gbàgbọ́ pé ó ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀

prophesy, v.t. and i. sọ tẹ́lẹ̀ (The event was prophesied in the Old testament.) Wọ́n ti sọ ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn tẹ́lẹ̀ nínú Májẹ̀mu Láéláé.

prophet, n. alásọtẹ́lẹ̀, wòlíì (He is a prophet.) Wòlíì ni.

prophetess, n. wòlíì obìnrin (She is prophetess.) Wòlíì obìnrin ni.

propitiate, v.t. là níjà, ṣe àtùtù, tù lójú, (Sacrifices were made to propitiate the gods) Wọ́n rúbọ láti tu àwọn òrìṣà lójú.

propitiation, n. ètùtù, ìtùlójú.

proportion, n. ipò onírúnrú nǹkan sí ara wọn, òṣùwọ̀n, ìwọ̀n. (He slept in a room of fairly generous proportion.)Ó sùn nínú yàrá tí ìwọ̀n rẹ̀ tóbi díẹ̀.

propose, v.t. dá ìmọ̀ràn, mú wá fún ìfiyèsí, dá lábàá. (What would you propose?) Kí ni o máa dá lábàá. proposition, n. ìmúwá fún ìfiyèsí, ìmọ̀ràn, àbá (He read my business proposition.) Ó ka àbá mi lórí òwò.

propound, v.t. gbìmọ̀, gbèrò (He propounded a theory of Linguistics.) Ó gbèrò ìmọ̀ ẹ̀dá èdè kan.

proprietor, n. oluwa, olóhun, ẹni tí ó ni nǹkan, olùdásílẹ̀. (He is the proprietor of our school.) Òun ni olùdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ wa.

propriety, n. ìṣedéédé, ìbámu (The school had acted in accordance with all legal proprietice.) Ilé-ẹ̀kọ́ náà tí gbé ìgbésè ní ìṣedéédé pẹ̀lú ohun tí ó jẹ mọ́ òfin.

prose, n. ọ̀rọ̀ geere, ìwé tí a kọ ní ọ̀nà ọ̀rọ̀ sísọ tààra tí kì í ṣe lọ́nà ti orin. (He taught us about prose diction.) Ó kọ́ wa nípa irúfẹ́ ìlò-èdè nínú ọ̀rọ̀ geere.

prosecute, v.t. lépa, bá rojọ́, pè lẹ́jọ́, pẹjọ́ (The police decided not to prosecute) Àwọn ọlọ́pàá pinnu láti má pẹjọ́.

prosecution, n. ìbárojọ́, ìpèlẹ́jọ́ (Prosecution for a first minor offence rarely leads to imprisonment.) Ìpèléjọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́ṣẹ̀ tí kò le kìí sábàá mú ẹ̀wọ̀n dání.

prosecutor, n. abánirojọ́, apenilẹ́jọ́, agbẹ́jọ́rò. (He is the state prosecutor.) Òun ni agbẹjọrò ìjọba.

proselyte, n. aláwọ̀ṣe (He made a proselyte of one of them.) ó sọ ọ̀ken nínú wọn di aláwọ̣̀ṣe.

prospect, n. ìfi ojú sí ọ̀nà, híhàn, ìwò, ìrí si ìrètí ohun rere. (There is a reasonable prospect that his debts will be paid.) Ìfi ojú sọ́nà tí ó mọ́gbọ́n dání wà pé àwọn gbèsè rẹ̀ yóò di sísan.

prosper, v.t and i. ṣe rere, ṣe aásìkí, lọ déédéé fún, lọ déédéé. (The economy prospered under his administration.) Ètò ọrọ̀ ajé ń lọ déédéé ní abẹ́ àkóso rẹ̀. prosperity, n. àlàáfíà, aásìkí (The country is enjoying a period of prosperity.) Ilẹ̀ náà ń gbádùn àkókò àláàfíà.

prosperously, adv. régérégé

prostitute, n. pánṣá gà obìnrin, àgbèrè, aṣẹ́wó. (She is a prostitute.) Panṣágà obìnrin ni.

prostitute, v.t. tà fún ìwà búburú, lò ní ìfẹ́kúùfẹ́ (He prostitude his honour.) Ó ta ọ̀wọ̀ rẹ̀ fún ìwà búburú.

prostitution, n. ìfi àgbèrè àti páńṣágà ṣ òwò ṣe, fífi àgbèrè àti páńṣágà ṣe òwò ṣe. (Prostitution is bad.) Ìfi àgbèrè àti páńṣágà ṣe òwò ṣe kò dára.

prostrate, adj. ní idọ̀ọ̀bálẹ̀ (He stumbled over Ade’s prostrate body.) Ó kọsẹ̀ lára ara Adé tí ó wà ní ìdọ̀ọ̀bálẹ̀.

prostrate, v.t. dábùúlẹ̀, dọ̀ọ̀bálẹ̀, dojúbolẹ̀. (The slaves prostrated before their master.) Àwọn ẹrú náà dọ̀ọ̀bálè níwájú ọ̀gá wọn.

prostration, n. ìdáàbúlẹ̀, láìní agbára, ìdọ̀ọ̀bálẹ̀ (They were carried off in a state of prostration.) Wọ́n gbé wọn lọ ní ipò ìdọ̀ọ̀bálẹ̀.

protect, v.t. dáàbò bò (Troops have been sent to protect them.) Wọ́n ti fi àwọn ológun ránṣẹ́ láti dáàbò bò wọ́n.

protection, n. ààbò. (He was under police protection.) Ó wà ní abẹ́ ààbò àwọn ọlọ́pàá.

protect, n. aláàbò (I regard him as my protector.) Mo kà á sí àláàbò mi.

protege, n. ẹni tí ó wà ní abẹ́ ìtọ́jú ẹlòmíràn. (He is a protégé of the musician.) Abẹ́ ìtọ́jú olórin náà ni ó wà.

protest, v.t. and i. tẹnu mọ́, kìlọ̀ (She protested her innocence.) Ó tẹnu mọ́ ọn pé òun kò jẹ̀bi.

protest, n. ìkìlò. Ìkóde, ìwọ́de. (The workers staged a protest.) Àwọn òṣìṣé ṣe ìwọ́de.


protract, adj. fà gùn, mú pẹ́ (It was caused by his protracted visit.) Àbẹ̀wò rẹ̀ tí ó fà gùn ni ó fà á.

protration, n. ìfàgùn, ìmúpẹ́.

protrude, v.t.and i. tì síwájú, yọ sóde. (His stomach protruded slightly.) Ikùn rẹ yọ sóde díẹ̀.

protuberance, n. ìwú, gegele, ìyọsóde.

proud, adj. gberaga. (He was too prous to join us.) Ó ti gbéraga jù láti dàpọ̀ mọ́ wa.

prove, v.t. and i. dánwò, rídìí, làdí (Prove your point.) Làdí ọ̀rọ̀ rẹ.

provender, n. sakasáka, koríko gbígbẹ.

proverb, n. òwe. (He read the book of proverbs.) Ó ka ìwé Òwe.

proverbial, adj. di òwe, lò só òwe. (His stupidity is proverbial.) Àgọ̀ rẹ̀ ti di òwe.

provide, v.t. and i. pèsè sílẹ̀, pèsè. (We provided the hungry children with rice and vegetables.) A pèsè ráìsì àti ẹ̀fọ́ fún àwọn ọmọ tí ẹbi ń pa.

providence, n. ìpèsè sílẹ̀ Ọlọ́run fún àwọn èdá Rẹ̀ , Ọlọ́run (Bí Onípèsè) (He trusts in providence.) Ó ní ìgbékẹ̀le nínú ìpèsè sílẹ̀ Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀

provident, adj. ní ìpèsè tẹ́lẹ̀, aroti ọ̀la, mojú owó, ìpèsè sílẹ̀ de ọ̀la (Our school has a provident.) ìpèsè sílẹ̀ de ọ̀la.

provider, n. apèsè, onípèsè, olùpèsè. (Olu is the family’s provider.) Olú ni olùpèsè fún eí náà.

province, n. ìgbèríkọ, ojú iṣẹ́, agbègbè. (Nigeria was divided intoprovinces.) Wọ́n pín Nàìjíríà sé agbègbè.

provincial, adj. ti agbègbè ìlú (The provincial government has many school.) Ìjọba ti agbègbè ilú náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ẹ̀kọ́

provision, n. oúnjẹ, èpèsè tẹ́lẹ̀, èsè. (I took with me a day’s provision.) Mo mú oúnjẹ fún ọjọ́ kan dání.

provocation, n. ìmúbínú, ìrusókè, ìtọ́, fórífọ́rí, ìrunú, ìfitínà. (She bursts into tears at the slightest provocation.) Lẹ́yìn ìfìtínà kékeré ẹkun ni ó máa ń bú sí.

provoke, v.t. mú bínú, rú sókè, tọ́ , yọ lóhùn, fitínà. (Don’t provoke that dog.) Máà tọ́ ajá yẹn.

provoker, n. atọ́nu, amúnibínú

prow, n. iwájú ọkọ̀ ojú omi.

prowess, n. ìgbóyà, ìláyà, (He was praised for his sport prowess.) Wọ́n yìn ún fún ìgbóyà rẹ̀ nípa eré ìdárayá. prowl, v.t. and. i. rìn kiri wá ohun ọdẹ, rìn kiri láti wá ẹran fún pípa jẹ., (The lion prowled through the forst.) Kìnìrún náà ń rin kiri inú igbó láti wá ẹran fún pípa jẹ.

proximate, adj. súnmọ́, nítòsí, létí.

proximity, n. itòsí, etí (The proximity of the school to our house makers it very popular.) Itòsí ilé wa tí ilé-ẹ̀kọ́ náà wá jẹ́ kí ó lókìkí.

proxy, n. ìrọ́pò, ìdúró fún, ìgbọ̀wọ́, ìfènìyàn-ṣènìyàn. (It was a proxy vote.) Ìbò ìdúró fún mi ni.

prudence, n. òye, ọgbọ́n

prudent, adj. amòye, ọlọgbọ́n, mèrò. (It was a prudent decision.) Ìpinnu Ọlọgbọ́n ni. prune, v.t. rẹ́ lọ́wọ́, rẹ́wọ́, ké kúrò, wọ́n kúrò, gbà lọ́wọ́. (prune out unnecessary details.) Ké àwịn àlàyé tí kò wúlò kúrò. pry, v.i. bojú wò, wádìí, tọ pinpin. (Don’t pry into the matter.) Máà tọ pinpin ọ̀rọ̀ náà.

psalm, n. orin mímọ́ (He read the Book of psalms.) Ó ka Ìwé Orin Mímọ́.

pshaw, inter. ṣíọ̀

puberty, n. àkókò tí ọkùnrin tàbí obìnrin ti dàgbà tán.

public, adj. ti gbogbo ènìyàn, mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. (Public opinion.) ajohùn ìlú.

publican, n. agbowó ède.

publication, n. ìkéde, ìtẹ̀wé sóde. ìtẹ̀wé jáde, ìtèjáde. (He talked about the publication of his first book.) Ó sọ̀rọ̀ nípa ìtẹ̀jáde ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́.

publicly, adv. ní gbangba (It was announced publicly.) Wọ́n kéde rẹ̀ ní gbangba.

publish, v.t. sọ di mímọ̀, kédée, fi lọ̀, tẹ ìwé fún títà. (They published Yorùbá books.) Wọ́n tẹ àwọn ìwé Yorùbá fún títà.

publisher, n. eni tí ó ń tẹ ìwé títà, akéde.

publishing, n. ìkéde, ìfi nǹken lọ

pucker, v.t. and i. kí iweje, kájọ, kákò, wunjọ. (This short puckers.) Ṣáàtì yìí kájọ.

puddle, n. ọ̀gọ̀dọ̀ kékeré, kòtò kékeré.

puff, n. fifẹ̀, afẹ́fẹ́ kan.

puff, v.t. and. i. fẹ́ sókè, fẹ́ jáde. (He puffed smoke into my face.) Ó fẹ́ èéfin jáde sí mi lójú.

pugilist, n. ẹni tí ó ń fi ìkúùkùù jà, ẹni tí ó ń kan ẹ̀sẹ́

pugnacious, adj. oníjà. (He is a pugnacious man.) Oníjà Ọkùnrin ni.

pugnacity, n. ìwà oníjà.

pull, v.t. and i. fà (I will pull you.) N ó fà ọ́

pullet, n. ọmọ adìyẹ

pulley, n. ohun ẹ̀rọ láti fi gbé ohun tí ó wúwo sókè.

pulpit, n. àga ìdúró wàásù. (The plan was condemned from the pulpit.) Wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀rò náà láti orí àga ìdúró ìwàásù.

pulsate, v.t. and i. lù kìkììkì (He has a pulsating headache.) Orí fífọ́ rẹ̀ ń lù kìkììkì.

pulse, n. ìlù kìkì ti ọkàn, ẹ̀wà (The doctor felt his pulse.) Dókítà yẹ ìlù kìkì ọ̀kàn rẹ̀ wò.

pulverize, v.t. and i. gún kúnná, lọ̀ (He pulverixed bones.)Ó gún àwọn egungun kúnná.

pump, n. ẹ̀rọ ìfa omi láti inú kànga. pump, v.t. fà sókè, fà sínú, fa afẹ́fẹ́ sí. (The engine was used for pumping water out of the well.) Wọ́n ń lo ẹ̀rọ náà láti fa omi sókè láti inú kànga.

pumpkin, n. elégédé.

punch, n. lílu ihò sí, ìlu ihò sí, ìlu. (He bought a hole punch.) Ó ra irin-inṣẹ́ ìlu ihò.

punch, v.t. lu ihò, lù, nà, kàn ní ẹ̀ṣẹ́. (She punched him on the nose.) Ó kàn án ní ẹ̀ṣẹ́ ní imú.

punctilious, adj. Kíyè sí nǹken kínníkínní (He was a punctilious host.) Olùgbàlejò tí ó máa ń kíyè sí nǹken kínníkínní ni.

punctual, adj. ṣe ní àkókò, ṣe gẹ́ẹ́ (She has been punctual) Ó ti máa ń ṣe nǹkan ní àkókò.

punctuality, n. ìṣe nǹken ní àkókò gam-an

punctually, adv. lákòókò gan-an (They always pay punctually.) Wọ́n máa ń sanwó lákòókò gan-an.

punctualte, v.t. fi àmì sí ìwé kíkà, bí àpẹẹrẹ “àmì ìdánudúró, .”

puncture, n. ihò kékeré.

puncture, v.t. and i. gún. (The tyre has punctured) Nǹkan ti gún táyà náà.

pungent, adj. mú, tanilára. (He bought a pangent snuff.) Ó ra aáṣáà tí ó mú.

punish, v.t. je. Níyà, ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ (He was punished for coming to school late.) Wọ́n jẹ ẹ́ níyà fún pípẹ́ dé ilé-ẹ̀kọ́.

punishment, n. ìyà, ìjìyà, (What is the punishment for murder?) Kí ni ìjìyà fún ìpànìyàn?.

punt, n. ọkọ̀ ojú omi kékeré

puny, adj. kékeré, aláìlera. (The lamb was a puny little thing.) Aláìlera ni ọ̀dọ́ àgùntàn náà.

pupil, n. ọmọ ilé-ẹ̀kọ́, akẹ́kọ̀ọ́ (How many pupils does the school have?) Akẹ́kọ̀ọ́ mélòó ni ilé-ẹ̀kọ́ náà ní?

pupil-Teacher, n. tíṣà kékeré tí ó ń kọ́ iṣẹ́ lábẹ́ẹ tíṣà àbà. (He is a pupil-teacher.) Tíṣà kékeré tí ó ń kọ́ iṣẹ́ lábẹ́ẹ tíṣà àgbà ni.

puppy, pup, n. Ọmọ ajá (He bought a puppy) Ó ra ọmọ ajá ken.

purchase, v.t. rà (They purchased the land for N 100,000.) Wọ́n ra ilẹ̀ náà ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà.

purchase, n. ohun tí a rà. (He filled his car with his purchases.) Ó kó àwọn ohun tí ó rà kún inú káà rẹ̀

purchaser, n olùrà. pure, adj. mọ́, dá ṣáká, funfun ní ìwà. (He bought a bottle of pure water.) Ó ra ìgò omit í ó mọ́ kan. purge, v.t. wẹ̀ mọ́, wẹ̀ (He was purged of sins.) Wọ́n wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ purification, n. ìwẹ̀nùmọ́ (He bought a water purification plant.) Ó ra ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ omi.

purifier, n. aláwẹ̀mọ́

purify, v.t. wẹ̀ mọ́, sọ di mímọ́ (One tablet will purify the water in 10 minutes.) lògùn oníhóró ken yóò sọ omi yẹn di mímọ́ ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá.

purity, n. mímọ́, ìwà mímọ́ (They tested the purity of the water.) wọ́n yẹ mímọ́ omi náà wò.

purloin, v.t. jí jalè, (We purloined a couple of old computers from work.) A jí àwọn kọ̀ǹpútà mélòó kan tí o ti ogbó láti ibi iṣẹ́

purloiner, n. Olè.

purple, adj. ẹlẹ́sẹ̀ àlùkò, àwọ̀ àlùkò. (That is a purple flower.) Àdòdó aláwọ̀ àlùkò nìyẹn.

purport, n. ìtumọ̀, ìdí, ìtorí. (What is the purport of what he sand?) Kí ni ìtumọ̀ ohun tí ó sọ?

purpose, n. ète, èrò, ohun tí a ń lépa. (Our campaign’s main purpose is to raise money.) Ète ìpolongo wa ni láti kó owó jọ

purpose, v. pète, rò. (They purpose to make a further attempt.) Wọ́n pète láti gìdánwò sí.

purposeless, adj. àṣedànù, láìní àǹfààní, láìní ète, láìní ìpinnu, aláìní àǹfààní. (It was a purposeless destruction.) Ìparun aláìní àǹfààní ni.

purr, v.t.and i. kùn bí olóógìnní (He purred with satisfaction.) Ó kùn bí olóógìnní fún ìdùnnú.

purse, n. àpò owó. (I took ten naira out of my purse.) Mo mú náírà mẹ́wàá jáde láti inú àpò owó mi.

purser, n. olùtọ́jú owó nínú ọkọ̀ ojú omi.

pursue, v.t. and i. lépa, sáré lé. (He pursued the robber.) Ó lépa olè náà.

pursuer, n. lépalépa, alépa.

pursuit, n. ìlépa, ìtẹ̀lẹ́ (She traveled to ìbàdàn in pursuit of heppiness.) Ó rin ìrìnàjò lọ sí ìbàdàn fún ìlépa ìdùnnú.)

purtenace, n. ìkópọ̀ inú ẹran.

purvey, v.t. and i. rà onjẹ silẹ̀, pèse silẹ fun.

purveyor, n. olutà ohun jijẹ.

pus, n ọyún.

push, v.t. and i. tì, bì, rọ́, tàri.

puss, pussy, n. ológbò, ologini.

put, v.t. and i. fi-sí.

putrefy, v.t. and i. bà-jẹ́, ra.

putrid, adj. rirà, bibàjẹ́.

putty, n. ẹmọ́, àtè.

puzzle, n. iṣoro, isúju, rú ni lojú, ohun gígọ

puzzling, adj. rurúju, rú ni lojú.

pygmy, n. aràrá.

pyjamas, n.pl. aṣọ àwọsun.

pyramid, n. ibiti a nsinku awọn ọba Egipti si. pyre,n. ikójọ igi lati fi sùn okú.

python, n. òjolá.