Jump to content

Atúmọ̀-èdè: Létà A

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Atumo-ede: Leta A)

Atumo-ede: Leta A

a (1A) kan: I gave him a dog. (Mo fun ní ajá kan). abandon (v); Kọ̀ sílẹ̀: He abandoned his job. (Ó kọ iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀)

abbreviation (n); ìkékúrú: Abbreviation is useful when taking lecture notes. (ìkékúrú wúlò tí a bá ń ṣe àkọsílẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́.

abdomen (n); ìkùn: The abdomen of the boy protruded because he over ate. (ikùn ọmọ náà rí róńdó nítorí pé ó jẹun yó jù).

ability (n); agbára tàbí òye: He has the ability to remember dates. (Ó ní òye ọjọ́ àti àkókò).

able (adj); lè, lágbár: He is able to do all thing. (Ó lè ṣe ohun gbogbo).

aboard (adv); nínú okò ojú omi tàbí òfúrufú; The captain welcomes you aboard this plane. (Adarí ọkọ̀ òfúrufú kì i yín káàbọ̀ sínú ọkọ̀.

abolish (v); parẹ́: Government has abolished the tax on agricultural products. (Ìjọba ti dá owó orí lori ohun ọ̀gbùn dúró.

about (adv); yíká, nípasẹ̀: What ara you talking about Kunle? (kí ní ẹ̀ ń sọ nípa Kúnlé?)

above (adv); lókè: We watched the birds above (À ń wo àwọn ẹyẹ lókè).

abroad (adv); ẹ̀yìn odi, òkè òkun: My brother is studying abroad. (Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ń kàwé lókè òkun).

abrupt (adj); lójijì, láìròtẹ́lẹ̀: He shouted abruptly. (Ó kígbe lojijì).

abscess (n); ìkójọpọ̀ ọyún: The injection Joshua got from the nurse has formed abscess. (Abẹ́rẹ́ tí nọ́ọ̀sì fún Joshua ti di Ọyún).

absent (adj); kò sí, kò wá; He was absent from work last Tuesday. (Kò wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìṣẹ́gun tó kọ́já).

absolute (adj); pátápátá; Amina has absolute freedom to choose a husband. (Amina ní òmìnìra pátápátá láti yan ọkọ).

absorb (v) fàmu: The dry Gari absorbed water easily. (Gaàrí gbígbẹ náà fa omi mu).

absurd (adj) ṣàìtọ́: He behaved in an absurd way. (Ó hùwà ní ọ̀nà tí kò tọ́).

abundant (adj); lọ́pọ̀; rẹpẹtẹ: There was an abundant rain last year. (Òjò rò rẹpẹtẹ ní èṣí

abura (n) ẹ̀yà igi kan: Olu made his furniture with abura (Olú kan àga rẹ̀ pẹ̀lú igi abura).

abuse (v); èébú: ìlòkílò: The teacher abused his power. (Olùkọ́ náà ṣI agbára lò).

acacia (n); ẹ̀yà igi kan: The old man rests under acacia tree. (Bàbá arúgbó náà ń gbatẹ́gùn lábẹ́ ogo kaṣíà).

academy (n); Ilé ẹ̀kọ́ gíga: He attends Baptist Academy. (Ó ń lọ sí ilé ìwé gíga ìjọ onítẹ̀bọmi).

accent (v); àmì ohùn: (Yorùbá is an accent language. (Èdè Yorùbá jẹ́ èdè Olóhùn).

accept: (v); tẹ́wọ́gbà: I accepted the doctors advice: (Mo gba imọ̀ràn dókítà).

acceptable (adj); ìtẹ́wọ́gbà: This work you have done is not acceptable, please do it again. (Iṣẹ́ tí o ṣe kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Jọ̀wọ́, lọ tun ṣe.

access (n); ọ̀nà, àjè: I have access to the library. (Mo lè wọ ilé ìkàwé).

accident (n) èsì, ìjàmbá: There was an accident yesterday. (Ìjàmbá kan sẹlẹ̀ lánàá).

accommodate (v) fún láàyè: You could accommodate another student in your room (Ó le fún akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn láàyè nínú yàrá rẹ).

accompany (v); Bálọ, Bárìn, Bákẹ́gbẹ́: He accompanied Bọla to Lagos. (Ó bá Bọ́lá lọ sí Èkó).

accomplish (v) ṣe parí: I accomplished two hours work before dinner. (Mo parí iṣẹ́ wákàtí méjì kí oúnjẹ ọ̀sán tó tó).

accord (n); ọkàn naa; ifowosowopo: We are in accord about this matter. (A wà ní ọkàn naa nípa ọ̀rọ̀ yìí).

account (n) ìṣirò, ìròyìn: Edwin gave an exciting account of the football match. (Edwin ṣe ìròyìn ìdíje bọ́ọ̀lù orí pápá).

accurate (adj) déédé: My watch is more accurate than yours. (Aago mi ṣe déédé ju tìrẹ). accuse (v) fi sùn: The teacher accused Tálá of stealing. (Olùkọ́ náà fi ẹ̀ṣùn kan Tálá pé ó jalè).

accustom (v) mọ́lára, sọdàṣà: She is accustomed to eating beef. (Ó mọlára kí ó máa jẹ ẹran).

ache (v) fífọ́, ríro: Her head ached all night (orí fọ́ọ ní gbogbo òru).

achieve (v) ṣetán, ṣerere: He achieved success in his studies. (Ó ṣe rere lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀).

acid (n) ohun tó kan tàbí nínú: Some acid dropped onto Maria’s skirt and made a hole in it.

acknowledge (v) Jẹ́wọ́, gbà: They acknowledged Olu as the cleverest student. (Wọ́n gbà pé Olú ni akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé jùlọ).

acquaintance (n); ojúlùmọ̀: He is an acquaintance of mine (Ojúlùmọ̀ mi ni).

acquire (v); Jèrè: Ayo acquired his wealth through frand. (Ayò kó ọrọ̀ rẹ̀ jọ lọ́nà ẹ̀ní).

acquit (v) dáláre, dásílẹ̀ The suspect was acquitted by the court (Ilé ẹjọ́ dá arúfin náà sílẹ̀).

acre (n); gburè ilè, sarẹ: The acre of land belongs to the Chief. (Olóyè ló ni gburè ilẹ̀ náà.

across (adj); rékọjá: My friend lives in the house across the street. (Ilé tó wà ní ìfòná títì ní ọ̀rẹ́ mi ń gbé).

act (v) ìṣe, òfin: Killing the lion was an act of bravery. (Iṣé akin ni pípa kìnìún).

active (adj) yára: My little brother is very active, he never sits still. (Àbúrò mi ọkùnrin yára púpọ̀ kì í wò sùù).

actor (n); Òṣèré ọkùnrin: Hubert Ogunde was a a famous actor. (Gbajúmọ̀ òṣèré ni Ògúndé ń ṣe láyé àtijọ́).

actress (n); òṣẹ̀ré obìnrin: Liz Benson is one of the Contemporary actress. (Ọ̀kan lára àwọn òṣèrébìnrin ìwòyí ni Liz Benson ń ṣe).

actual (adj); nítòótọ́, pàápàá, gan-an: He is the actual person that stole the goat. (Òun gan an ló jí ewúrẹ́ náà).

A.D. Lẹ́yìn ìkú Olúwa wa: This Church was built in 1950 A.D. (A kọ́ ìlé ìjọsìn yìí ní ẹgbẹ̀rún méjì ọdún ó dín díẹ̀ lẹ́yìn ikú Olúwa wa).

adapt (v); bádọ́gba: mólára, wà fún: It is sometimes difficult to adapt to town life. (Ó máa ń ṣòrọ nígbà míràn kí ìgbé ayé ìgboro tó mómi lára).

add (v); fikún: There were seven eggs in the basket I added three, so now there are ten. (Ẹyindìyẹ méje ló wà nínú apẹ̀rẹ̀, mo fi mẹ́ta kún un, ní bá yìí ó ti di mẹ́wàá. adder (n); paramọ́lẹ̀: Adder is a poisonious snake. (Ejò olóró nì paramọ́lẹ̀).

address (n); bá sọ̀rọ̀, kọ̀wé sí: Always address elders with respect. (Máa bá àwọn àgbà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀).

adequate (adj); tó: There is an adequate amount of food for everyone. (Oúnjẹ tó tó wà fún gbogbo ènìyàn).

adjective (n) Àpèjúwe: She sang a beautiful song. (Ó kọ orin dádùn).

adjust (v) tún ṣe, tò léṣẹsẹ: Olù adjusted his trousers. (Olú tún ṣòkòtò rẹ̀ ṣe).

administer (v); ṣàkóso: The government administers the Country. (Ìjọba ń ṣàkóso orílẹ̀, èdè).

administrator (n); alákòóso: The Principla is the administrator of the school. (Ọ̀gá ilé ìwé ni alákòóso ìlé ìwé náà).

admiral (n); Olórí ọkọ̀ ogun: My brother is an admiral. (Olórí ọkọ̀ ogun ojú omi ni ẹ̀gọ́n mi).

admire (v); jọmi lojú, yìn; wuyì lójú: I admire his Kindness. (Ìwà rere rẹ̀ jọmi lójú).

admit (v) gbà sílẹ́, jẹ́wọ́: He admitted his failt. (Ó jẹ́wọ́ àìṣe déédé rẹ̀).

adolescent (adj) Ọ̀dọ́ rẹ̀. Adolescent life is full of mistakes. (Ìgbà ọ̀dọ́ kún fún àṣìṣe).

adopt (v) sọdọmọ: The childless couple adopted a child at last. (Tọkọtaya tí wọ́n yàgàn náà ti fi ọmọ kan sọmọ nígbẹ̀yìn). adore (v); júbà; fẹ́ràn lọ́pọ̀lọpọ̀: The boy adores chocolate. (Ọmọkùnrin náà fẹ́ràn ìpápánu púpọ̀).

adult (n); àgbà: Olu is now an adult. He can take decisions on his own. (Olú ti dàgbà báyìí. Ó lè dá romú, kí ó sì ṣe ìpinnu lórí ohun tí ó kàn án.

advance (v); ìlọsíwájú, àgbàsílẹ̀ owó. We are more advanced in techonology. (A ti lọ síwájú nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ).

advantage (n); àǹfààní: There are lots of advantages in doing good. (Àǹfààní púpọ̀ ló wà nínú síṣe rere).

adventure (n); ìdáwọ́lé: He went into a lot of adventures in order to learn more. (Ó dáwọ́lé oríṣìíríṣìí ń kan kí ó lè ní ìmọ̀ si).

adverb (n); ọ̀rọ̀ àpọ́nlé: She sang a song beautifully today. (Ó kọrin dáradára ló nìí.

advertise (v) kéde, polówó; The supermarket was advertising salt at a good price. (ilé ìtàjà náà ń polówó iyọ̀ ní owí pọ́ọ́kú).

advise (v); dárúmọ̀ràn, dámọ̀ràn; ìmọ̀ràn: She advised me to beware of dog. (Ó gbàmí nímọ̀ràn wípé kí n ṣọ́ra fún ajá).

aerial (n); lójúsánmọ̀, lójúọ̀run: The aerial of my radio is fanlty. (Ọ̀pá redio mi kò dára).

aeroplane (n); bààbú, ọkọ ofurufu: There was a plane crash at Abuja. (Ìjàmbá ọkọ̀ òfúrufú ṣẹlẹ̀ ní Àbújá).

affair (n); ìṣe: The party was a very noisy affair. (Ayẹyẹ náà jẹ́ aláriwo).

affect (v); mú lọ́kàn, kàn: This new rule will not affect me as lam leaving the school. (Òfin tuntun yìí kò kàn ní torí pé mò ń fi ilé ìwé náà sílẹ̀.

affectionate (adj); nífẹ̀ẹ́: Her mother writes her long, affectionate letters. (Ìyá rẹ̀ kọ lẹ́tà ìfẹ́ gígùn si).

afford (v); ní agbára láti ṣe ǹkan. My father says he can’t afford a car. (Bàbá mí ní àwọn kò ní agbára láti ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́).

afraid (adj); bẹ̀rù, fòyà, kọmimú: Olu says he’s not afraid of lion. (Olú sọ wí pé òun kò bẹ̀rù kìnìún). after (prep); lẹ́yìn, tẹ̀lé: Tomorrow is the day after today. (Ọ̀la ni ó tẹ̀lẹ́ òní). Ọ̀sán (n) afternoon: Come again this afternoon. (Padà wá ní ọ̀sán yìí).

afterwards (adv); Nígbèyìn: We want to the film and afterwards we walked home together. (A lọ síbi sinimá, nígbẹ̀yìn a jọ rìn lọ sílé).

again (adv); ẹ̀wẹ̀, lẹ́ẹ̀kejì: I liked the book so much that I read it again. (Mo gbádùn ìwé náà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ tó jẹ́ pé mo tún un kà).

against (prep); lòdìsí: Our teacher is against bad habits. (Olùkọ́ wa lòdìsí ìwà ìbàjẹ́).

agbádá (n) agbádá: The agbada he put on made him look twice his age. (Agbádá tí ó wọ̀ mú u dàbí àgbàlagbà).

age (n); Ọjọ́ orí: Mary’s age is eight. (Ọjọ́ orí Maria ti tó ọdún mẹ́jọ).

age (v); dàgbà, gbó: He has aged because of hard labour. (Ó ti gbó nítorí ìṣẹ́ agbára).

agent (n) Aṣojú: My father is a postal agent. (Aṣojú ilé ìṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ni bàbá mi).

agnostic (n); aláìgbàgbọ́: Olú is an agnostic. (Aláìgbàgbọ́ ni Olú).

ago (adv); kọjá, sẹ́yìn: We came to live here six years ago. (A dé síbí ní ọdún mẹ́fà sẹ́yìn).

agony (n); inira, ìrora: The wounded man was in agony. (Inu ìrora ni ọkùnrin tí ó ṣèṣe n nì wà).

agree (v); sàdéùn, fohùnsọ̀kan: I agree with you. (Mo fohùn sọ̀kan pẹ̀lú rẹ).

agriculture (n); iṣẹ́ àgbẹ̀: Agriculture is important because we all have to eat. (Iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe pàtàkì nítorí wí pé gbogbo wa ni a máa jẹun).

ahead (adv); ní wájú: We shall have to cross that river ahead of us. (A máa rékojá odò tí ó wà ní wájú wa).

ahmadiyya(n); Ẹ̀yà èṣìn mùsùlùmí: Alhajì Yusuph is of Ahmadiyya Sect. (Ẹ̀yà Ahmadiyya ni Alhaji Yésúfù).

aid (n) ìrànlọ́wọ́: A dictionary is an aid to learning English. (Ìwé asọ̀tumọ̀ jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì). aid (v); gbọwọ́, Olùgbọ̀wọ́: He aided the criminal. (Ó ṣe Olùgbọ̀wọ́ ọ̀daràn náà).

aim (v); Èrò, fojúsùn: He aimed to be the best football player in the school. (Ó gbèrò láti jẹ́ òṣèré orí pápá tí ó dára jùlọ ní ilé ìwé).

aim (n); fojúsùn: He aimed at the lion. (Ó fojúsun kìnìún náà).

air (n); Afẹ́fẹ́: The air is refresling. (Afẹ́fẹ́ náà tura).