Jump to content

Àwọn àdúgbò ìlú Ìkirè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Awon Adugbo Ikire)

Àwọn àdúgbò ìlú Ìkirè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1. Bodè:- Ẹnu odi ìlú látijọ́ ní ibi tí wọn ń gbà wọ inú ìlú láti ẹ̀yìn odi.

2. Ìta Àkún:- Àdúgbò ibi tí wọn ti ma ań ṣe ìpàtẹ ìlẹ̀kẹ̀ tàbí àkún fún títà ní àtijọ́.

3. Àjígbọ́:- Àdúgbò ibi tí wọn tí máa ń ṣe ara ní ọ̀sọ́ ni àtijọ́. Àpèjá orúkọ yìí gan-gan ni Àjígbọ́ lọ̀sọ́.

4. Láàkọsìn :- Àdúgbò tí odò tí wọn máa ń pọn sí ojubọ òrìṣà Akirè tàbí Ògìyán wà. Torí pé odo yìí wọn kì í sọ̀rọ̀ tí wọn ń pọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í jẹ́ kí ilẹ̀ mọ́ tí wọn á fi pọn ni wọ́n fí pè é ní “Láì kọ sìn.

5. Òkè-Móró:- Orí òkè tí àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ ti kérúbù àti sérátù ti máa ń sètò fún àwọn tí wọn ń bí abiku, ní ìgbà àtijọ́ kí àwọn àbíkú wọ̀nyí lè maa dúró sayé ni wọn ń pè ní Ọmọ-ró = > Móro.

6. Fìdítì:- Ibi tí ogun abẹ́lé láàrin Ìkirè àti orílé òwu ti pin tí wọn sì dá Ogun dúró.

7. Okè Awo:- Àdúgbò tí àwọn aláwo kọ́ ilé-dì wọn sí.

8. Òkè Ada:- Àdúgbò tí àwọn ará ìlú máa ń da ilẹ̀ sí látijọ́

9. Òkítì:- Àdúgbò tí òkè ńlá kan wà èyí tó máa ń mú kí ènìyàn yí gbirigbiri lu ilẹ̀ tó bá ti yọ ènìyàn.

10. Ìta Àgbọn:- Wọn gbin àgbọn lọ́pọ̀ ní adugbo yìí tí wọn sí ní ibi kan pàtó tí wọn ti máa ń tà á ládúgbò yìí kan náà.

11. Olóríṣà òko:- Àdúgbò tí wọn ti ń bọ òrìṣà oko.

12. Òkè Àkó:- Àdúgbò tí àwọn alamí tì máa ń fa ènìyàn lọ láàyè latijọ kí wọn tó fie tutu lé wọn kuro tó sì di ibi tó ṣe e gbé.

13. Bòòṣà:- Àdúgbọ̀ tí wọn gbé ń bọ òrìṣà ńlá.

14. Ìsàlẹ̀ Àgbàrá:- Àdúgbò yí wà ní gẹ̀rẹ́ gèré ibẹ̀ ni àgbàrá máa ń dojú kọ, odò tó tún wà ní ibẹ̀ máa ń kún àkún ya wọlé.

15. Ayé dáadé:- Àdúgbò tí wọn kọ́kọ́ ri ẹ̀rọ radio alátagbà ara ògiri mọ́ tí wọn sì fi ibẹ̀ ṣe olú ilé iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìlú ìkirè ni Ayé dára dé Ayedaade.

16. Àfàntáà:- Ibi tí àwọn ọlọ́ṣà máa ń fi ara pamọ́ sí ní ìgbà kan rí tí wọn sì máa ń dá àwọn ará ìlú lọ́nà.

17. Baakun:- Àdúgbò yí àwọn igiààkùn ló gba ibẹ̀ kí àwọn ará ọ̀fà tó ya wá sí Ìpetu-modu tó tẹ ibẹ̀ do. Ibi tí a bá ààkùn.

18. Ìyànà Ẹ̀gbá:- Àdúgbò yìí pópó ni wọn máa ń pèré tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n nígbà tí obìnrin ará Abẹ́òkuta kan wá ń ta àmàlà níbẹ̀ wọn mọ̀ ọ́ bí ẹni mo owó wọn sì máa n fi júwe pé Ìyànà tí Obìnrin ẹ̀gbá ti ń ta àmàlà.

19. Kòso:- Àdúgbò yí ni Ojúbọ Sàngó wà ní ìlú Ìpetu-Modù ṣùgbọ́n kí wọn ma ba à máa la orúkọ mọ́ sàngó lórí wọn ń pe ibẹ̀ ní kòso-Ibi tí sàngó kú sí.

20. Ẹgbírì:- Inú ẹrọ̀fọ̀ ni àdúgbò yìí àti ìgbà òjò àti ẹ̀ẹ̀rùn ibẹ̀ kì í gbẹ fún omi èyí máa ń mú kí ilẹ̀ bẹ̀ rì.

1. Ilé Atóbatélè : Ìwàdìí fi yé mi pé enití ó pilèsè ìlè yìí eni pàtàkì àti alákíkanjú tí ìsesí àti ìhùwàsí rè láàrin àwùjo fi ara jot í oba ìlú. Nígbàtí ó wà pàpà je oba, ibi tí ó fi se ibùgbé tèlè ni wón ńpè ní ilé Ató-Oba-télè lónìí. Ìwádìí tún fi yé mi pé wón máa ńki àwon omo bíbí ilé yìí báyìí. “Òrìsà-ńlá wùmí Atóbatélè. Omo ládèkàn, Omo Àmúlé lámùlé orí kò rerù, orí dada ponponran.

2. Ilé Arósùn: Ìwádìí fi yé mi pé enitó pèsè ilé yìí jé àgbè tó féràn láti máa gbin èfó òsùn tàbí ilá. Èyí ló fà á ti wón fi ńpe ilé yìí ní Arí-Òsùn-pa-ojà. Wón sì máa nkì wón ní “Arósùn pajà tilátilá omo oba adélé tejiteji

3. Ilé Sagbá: Nínú ìwádìí, mo rí I dájú pé omùtí ni enitó pèsè ilé yìí. Ìwádìí tún fi yé mi pé óní ojú igbá tí òmùtí yìí fi máańmu otí. Èyí tó jásí pé ó máa ń sa ìgbá mu otí. Bí orúko ìlé yìí se jeyo nì yìí. wón sì máa ńki àwon omo bíbí ìlé yìí ní “Sagbá mutí sàwo mùko, sa eni –rere bátan sa àgbààgbà bárìn, àwa òní bá enití kò sunwòn tan nílé tiwa.

4. Ilé ejilolá: Enìtó pèsè ilé yìí jé alágbède. Àwon alágbède ló sì máa ńjé “Eji” Èyí ló fá a kíkì wón ní “Ejíwándá ará ìlágbède”. Bí orúko ilé yìí se jeyo nì yí nípasè pipe ilé yìí ní Ejìlolá léyìn Olùpilèsè rè.

5. Ile onílù: Ìwádìí fi yé mi pé enitó pèsè ilé yìí yan ìlù lílù láàyò ó sì mu gégé bí isé. Èyí ló fà á tí wón fi ńpe ilé yìí ní ilé onílù.

6. Ile Alábe: Nínú ìwádìí mi, mo ríi dájú pé enitó pèsè ilé yìí máa ńkolà. Èyí ló fà á tí wón fi npe ilé yìí ní ilé alábe.

7. Ilé kéye: Enitó pèsè ilé yìí jé olóògùn háńhán tí ó máa ńkó eye àjá. Mo rí èyí gbó nínú ìwádìí mi. Ìdí ni yí tí a fi ńpé ìlé yìí ní ilé kéye dòní.

8. Ilé Olúkúnlé: Ìwádìí fi yé mi pé okùnrin pò jojo nínú ilé Olupilèsè yìí. Èyí tó fà á tí wón fi ńpe ní ilé olúkúnlé nítorí ìgbàgbó àwon Yorùbá pé “Olú” ni Okùnrin jé nínú omo.

9. Ilé búoyè: Ìwádìí fi yé mi pé omo oba ni àwon omo ilé Búoyè àti wípé àwon ni wón kókó dé ìlú Ìkirè. Enití ó kókó dé agbo-ilé yìí ni ìwádìí fi yé mi pé ó ńjé Búoyè. Èyí ló fà á tí wón fi ńpe ilé yìí ní ilé Búoyè.

10. Ilé sèsan: Okùnrin kan ti orúko rè ńjé Òbísèsan ni ìwádìí so pé ó te àdúgbò náà dó. Gégé bí olùpilèsè, wón ní láti máa pe àdúgbò ibití arákùnrin yìí ńgbé ní ilé sèsan ní ikékúrú.

11. Ilé Fáfióyè: Ìwádìí fi yé mi pé ifá ló fi enití ó kókó dé sí agbo ilé yìí je oyè. Èyí ló fà á tí won fi ńpé ilé yìí ní ilé Fáfióyè.

12. Ilé òjísé: Ìwádìí fihàn gbangba pé enitó pèsè ilé yìí jé olóyè kan pàtàkì tó máa ńjé isé pàtàkì fún Oba. Ìdì nì yí tí wón fi ńpe ilé yìí ní ilé òjísé. 13. Ilé Alusèkèrè: Ìwádìí fi yé mi pé alusèkèrè ni olùpìlèsè ìlé yìí. Èyí ló fà á tí wón fi ńpe ìlé yìí ni ilé Alusèkèrè.

14. Ile kósùn: Ìwádìí fi yé mi pé olùpìlèsè ilé yìí kì í páyà tàbí bèrù ní àkòkò tí rògbòdìyàn bá bé sílè láàrin ìlú. Ó máa ńsùn pèlú ìfòkànbalè lásìkò làásìgbò. Èyí ló fà á orúko ilé yìí “ilé kósùn-ko-nà-tán”.

15. Ilé olórìsàoko: Ìwádìí fi hàn mí pé òrìsàoko ni orìsà tí olùpilèsè ilé yìí máa ńbo. Èyí tó fa sáàbàbí orúko ilé yìí ILÉ OLÓRÌSÀOKO.

16. Ìyànà Ègbá: Ìwádìí fi hàn gbangba pé ni ìgbà ìwásè àwon ègbá pò jojo ni agbègbè yìí. Èyí ló fún ìyànà agbègbè yìí ní orúko Ìyànà Ègbá.

17. Ilé elékuru: Ìwádìí fi yé mi pé Olùpilèsè ilé yìí féràn láti máa bo Èsù. Òrìsà tí a mo oúnje rè sí èkuru. Èyí ló sì tún fà á tí olùpilèsè náà fi féran láti máa je èkuru. Ìdí nìyí ti ilé yìí fi ńjé ilé Elékuru.

18. Ilé Balógun: Ìwádìí fi yé mi pé enìtó kókó je balógun ni ìlí Ìkirè ló pèsè ìlé yìí. Èyí ló fà á ti ìlé yìí fi ńjé ilé Balógun.

19. Ilé Omódá: Ìwádìí fi hàn mí pé Oba lóni ìlú. Ibití omo oba fúnra rè dúró sí ni a mò sí Omódá ní ìlú Ìkìrè lónì í.

20. Ile Orí-Eérú: Àdúgbò kan ní ilú Ikìrè tí ìwádìí fi hàn pe eérú ti séyo láì mo ìdí rè ni à ńpè ní Orí-Eérú.

21. Ilé súnmóyè: Ìwádìí fi yé mi pé orúko arákùnrin tó pèsè àdúgbò yìí ni a mò sí súnmóyè. Eléyìí tí ó fa orúko àdùgbò yìí.

22. Ilé láàkoosìn: Ìwádìí fi yé mi pé olóyè kan tó ńjé Osìn wo ìlú Ìkirè wá fún àbèwò. Ibití Oba ti téwógbà á ni à ń pè ni láàkoosìn – Olá-kò-ko-osìn.

23. Ilé Ìsàlè-Àbàtà: Àdúgbò kan ti àbàtà tip ò jojo ni à ń pè ní Isale-Àbàtà.

24. Ilé Òkè Awo: Ìwádìí fi hàn pé olórí àwon awo ìlú ló te àdúgbò yìí dó.

25. Ilé Késińjó: Ìwádìí fi yé mi pé bàbá kan máa ńso esin kan mólè ní àdúgbò yìí, esin náà sì máa ńjó lóòrèkórèè. Èyí ló fà á tí wón fi ńpe àdúgbò yìí ní késińjó.

26. Ilé Òkè Olá: Ìwádìí fi hàn mí pé gbogbo àwon tó ńgbé àdùgbò yìí lóní owó lówó ní ìgbà ìwásè. Èyí ló faa orúko rè yìí òkè olú. Wón máa ńki àwon ará àdúgbò yìí pé “Omo olá tó pò títí, Olá tí ò ní pèkun. Olá tí pò títí, Olá tí ò lábùkù.

27. Ilé Sábó: Ìwádìí fi hàn mí pé ìbití àwon Haúsá máa ńsábo sí tàbí tí àwon Haúsá tí máa ńse àtìpó ni à ń pè ní sábó.

28. Ilé Mòsà: Ìwádìí fi yé mi pé ibití a gbé mo òrìsà tí a sì gbé ńbo ó ni à ńpè ni Mòsà.

29. Ilé Kúògbó: Ìwádìí fi hàn mí pé arákùnrin tó pilèsè ilé yìí jé ìríjú gbogbo ìlú. Àìsàn ńlá kan se tó béè gè tí won fi kó ilé ohílèkùn ńlá kan fún un gégé bí ifá se wí. Látàrí gbogbo èyí, ìwádìí fi yé mi pé ikú pàpà mulo. Èyí ló fà á ti wón fi ńpe ilé yìí ní ìlé ikú-kò-gbó-ìlèkùn.

30. Ìlé pàràkòyí: Ìwádìí fi yé mi pé olórí àwon onísòwò ìlú tí orúko ńjé pàràkòyí ló pilèsè ilé yìí. Èyí ná fi máa ńki àwon omo ilé yìí ni “Pàràkòyí ògá-ìsòwò”. Ní àkotán, ìwádìí fi yé mi pé kò sí àdúgbò tàbí agbo-ilé tí orúko tó ńjé kò ní ìdí. (see Yoruba Place names)