Àwọn Àdúgbò Ìlú Àkúrẹ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Awon Adugbo Ilu Akure)
Jump to navigation Jump to search

Adugbo Ilu Akure

ÀKÚRẸ́: Àdúgbò

1. Àdégbọlá :- Ó jẹ́ ibi tí àwọn Ọlọ́lá má gbé jù ní ayé àtijọ́. Ó sí tún jẹ́ orúkọ ènìyàn.

2. Ìkóyí :- Ó jẹ́ ibi tí wọn ti má kó àwọn ìkó jo sí

3. Ayédùn :- Itúmọ̀ rẹ nipé ó jẹ́ orúkọ Akọni kan ní ìlú. Ẹni yìí ní ó má jagun fún nígbà náà

4. Òkè Àró:- Jẹ́ àwọn àdúgbò tí má sé ayẹyẹ Ọdún bí égún àti bẹ́ẹ̀ lọ ní ayé atijó.

5. Ìsólọ̀ :- Ó jẹ́ Ọba ti ogun lẹ́ wá sí Àkúrẹ́ ibi tí ó tẹ́ dó sí ni à pè ní ìsọ́lọ́,

6. Ẹrẹ̀kẹ̀sán:- Ó jẹ́ orukọ́ ọjá Ọba Àkúrẹ́. Ọjá yìí nìkan ni Ọba tí má se ọdún òlósùnta fún ọjọ́ méje.

7. Gbogí:- Ó jẹ ibi tí wọn tí sé orò omi yèyé láyé àtijọ́, ó sí tún jẹ́ aginjù tí àwọn ẹranko búburú má gbé.

8. Ẹringbo:- Ibẹ̀ ní wọn ti má sin orísìíríṣìí àwọn ẹranko tí ó lágbára láwùjọ.

9. Ìjọ̀kà:- Jẹ́ Ọ̀kan lárà àwọn orúkọ̀ ilẹ̀-iwé girama tí ó wá, ìdí níyí tí wọn fí pé orúkọ àdúgbò náà ní ìjọ̀kà

10. Olúwàlúyí :- jẹ́ ibi tí ènìyàn ńlá kan tẹ́dó sí

11. síjúwádé:- Jẹ́ ibi tí ọmọ-ọba Ilé-Ifẹ́ tẹ́dó sí, orúkọ́ rẹ si ni wọn fí pé.

12. Osínlé :- Ibẹ́ jẹ́ ibi tí àwọn òrìṣà sínlẹ̀ sí tàbí tí wọn rí sí. Ibẹ̀ sin i wọn wọlẹ̀ sí

13. Okúntá eléńlá :- Ó jẹ́ ibi tí òkúnta ńlá ńlá pó sí.’

14. Ìrò – Ó jẹ́ ibi tí wọn tí má sé orò láyé àtijọ́.

15. Òkè ìjẹ́bú:- Ibi tí òkè pọ̀ sí jù ni Àkúrẹ́ ìdí níyí tí wọn fí pé ní ibi tí òkè fi ìdí sí

16. Ìdí àágbá:-jẹ ibi tí wọn má kó goro jọ sí.

17. Ọjà osódí:- jẹ́ ibi tí àwọn àgbààgbà olóyé ìlú má gbé láyé àtijọ́ ibẹ sì ni wọn tí má ṣe ìpàdé fún ètó ìlú.

18. Alágbàká:- jẹ Ibi tí omi ÀKÚRẸ̀ tí pín sí yẹ́lẹ́yẹ́lẹ́, ibẹ̀ ní orirún omi tí sàn lọ si oríṣìíríṣìí ọ̀nà.

19. Ijọmu :- Ó jẹ́ orúkọ́ ibi tí ìjọ kọ́kọ́ tí bẹ́rẹ̀, ìdí nìyí tí wọn fí pé ní ìjọmu.

20. Àrárọ́mì:- Ibẹ̀ ní àrálépó kọ́kọ́ tẹ̀dó sí. Ó sí tún jẹ ibi tí ó gba jù ní Àkúrẹ́.

21. Àlá:- jẹ ibi tí orirún omi ÀKÚRẸ́ ibẹ̀ sí ni omi mejiji Àkúrẹ́ tí pádé.

22. Odò ìjọ́kà:- ò jẹ̀ orúkọ́ àdúgbó tí ó lágbárá, ibẹ̀ sí ní àwọn àkínkánjú alejo ma tẹ̀dó sí

23. Ọba Adésida road:- Jẹ orúkọ ọba Ìlú Àkùrẹ́.

24. Ìlésá garage:- jẹ́ ibi tí ó já sí’ ọ̀nà ilésá.

25. Owódé :- jẹ́ ibi tí ó gbájúmọ́ ibẹ̀ sí ní ọ̀dọ́ ńgbé jù.

26. Isìnkàn:- Jẹ́ ibi tí wọn má sín òkú àwọn olóyé ńlá ńlá sí ní ayé àtijọ́.

27. Ondo road-Ó jẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ondo.

28. Orítáọ́bẹ́lẹ́:- Ó jẹ́ orítá mẹta ó sí tún jásí ibi tí ilé ẹ́rọ gbóhúngbáróyè Àkúré.

29. Iròwò:- Jẹ́ orúkọ Ilú kekéré kan láyé àtijọ ìlú yìí wà lára Àkúrẹ́.

30. Àrákàlẹ́:- Jẹ́ òkìtí Ibẹ̀ ni wọn ti rí àwọn ènìyàn tí ó dí òkìtì láyé àtijọ́. Ibẹ̀ sí ní wọn ti má jẹ́ oyè jù.