Awon omobìrin Zelophehad
Ìrísí
Àwon omobìrin Zelophehad Àwon omobìrin Zelophehad tí a dárúko nínú Bíbélì nínú ìwé Númérì jé omo ìyá márun, orúko won ni Mahlah, Noa, Hoglah, Milcah ati Tirzah. Wón jé òdómobìrin nígbà tí àwon omo Israel n jáde kúrò ní ilè Egypt tí wón sì n gbáradì lati wo ilè ìlérí. Wón gbéjó wá sí àkíyèsí àwùjo àwon omo Israel nípa ètó omobìrin àti ojúse láti jogún ohun ìní bàbá won ní ìwòn ìgbà tí kò bá sí àrólé. Zelophehad jé arákùnrin ti èya Manasseh, ó ní omobìrin márun àmó kò bí omokùnrin, nítorí ìdí èyí kò ní àrólé.