Bámijí Òjó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Bamiji Ojo)
Jump to navigation Jump to search

Bamiji Ojo (8 October, 1939) je olukowe omo ile Naijiria.

Itàn Ìgbésíayé Bámijí Òjó[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Bámijì Òjó ní egúnjọ́ oṣù kẹwàá ọdún 1939 ní ìlú ìlọ́ràá, ní ìjọba ìbílẹ̀ Afijió ní ìpínlẹ̀ Ọ̀jọ́. Orúkọ àwọn òbí rẹ̀ ni Jacob Òjó àti Abímbọ́lá Àjọkẹ́ Òjó. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn òbí rẹ̀ ń ṣe.

Ojú ti ń là díẹ̀ nígbà náà, ẹni tí ó bá mú ọmọ lọ sí ilé-ìwé ní ìgbà náà, bí ìgbà tí ó fi ọmọ sọ̀fà tí ó mú ọmọ lọ fún òyìnbó ni. Ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ pa ìmọ̀ pọ̀ wọ́n fi sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti ìjọ onítẹ̀bọmi ti First Baptist Day School ìlú Ìlọràá ni ọdún 1946. O ṣe àṣeyẹrí nínú ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́fà, tí ó kà jáde ni ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Nígbà náà wọ́n ti ń dá ilé ẹ̀kọ́ gíga Mọ́dà (Modern School) sílẹ̀. Bámijí Òjó ṣe ìdánwò bọ́ sí ilé-ìwé Local Authority Modern School ní ìlú Fìdítì, ó wà ní ibẹ̀ fún ọdún mẹ́ta (1956-1959).

Lẹ́yìn èyí nínú ọdún 1960, Bámijí Òjó ṣe iṣẹ́ díẹ̀ láti fi kówó jọ. Nítorí pé kò sí owó lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ láti tọ́ ọ kọjá ìwé mẹ́jọ. Lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ tí ó sì kówó jọ fún ọdún kan pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí “Modern School”, ó tún tíraka láti tẹ̀síwájú lẹ́nu ìwé rẹ̀. Ó lọ sí ilé-ìwé ti àwọn olùkọ́ni ti “Local Authority Teacher Training College” ní ìlú Ọ̀yọ́ láti inú ọdún 1961 di ọdún 1962.

Ìgbà tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe iṣẹ́ tí ó wù ú lọ́kàn gan-an láti ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni iṣẹ́ tíṣà. Ó ṣe iṣẹ́ tíṣà káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ bí i Ṣakí, Edé, Ahá. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìròyìn ni ó múmú ní ọkàn rẹ̀.

Bámijí Òjó wà lára àwọn méjìlá àkókó tí wọ́n gbà ní ọdún 1969 láti kọ́ Yorùbá ní Yunifásitì Èkó. Nígbà náà ojú ọ̀lẹ ni wọ́n fi máa ń wo ẹni tí ó bá lọ kọ́ Yorùbá ní Yunifásitì.

Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni wọ́n gba Bámijí Òjó sí ilé iṣẹ́ ìròyìn ní ọdún 1970, Àlhàájì Lateef Jákàńdè ni ó gbà á sí iṣẹ́ ìròyìn ní ilé-iṣẹ́ “Tribune”ní ìlú Èkó, gẹ́gẹ́ bí igbá kejì olóòtú Ìròyìn Yorùbá. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó tin í ìyàwó nílé nígbà náà wọ́n gbé e padà sí Ìbàdàn. Ilé-iṣẹ́ wọn wà ní Adẹ́ọ̀yọ́. Ní àsìkò yìí kan náà ni Bámijí Òjó ronú pé iṣẹ́ ìròyìn ti orí Rédíò Sáá ní ó wu òun. Ó wá ń bá wọn ṣiṣẹ́ aáyan ògbufọ̀ ni ilé-iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Èyí ni ó ń ṣe tí ó fi ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ “Tribune” àti nílé iṣẹ́ “Radio Nigeria”.

Ní ọdún 1971 ni wọ́n gba Bámijí Òjó gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Ìròyìn ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria”. Àwọn tí wọ́n jìjọ ṣiṣẹ́ ìròyìn nígbà náà ni Alàgbà Ọláòlú Olúmìídé tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀, Olóògbé Àlhàájì Sàká Ṣíkágbọ́ àti Olóògbé Akíntúndé Ògúnṣínà àti bàbá Omídèyí.

Nítorí ìtara ọkàn tí Bámijí Òjó ní láti ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Tẹlifíṣàn ó kúrò ní “Radio Nigeria”, ó lọ sí “Western Nigerian Broadcastint Service” àti “Western Nigerian Televeision Station” WNBS/WNTV tó wà ní Agodi Ìbàdàn, nínú oṣù kọkànlá ọdún 1973. Ni ibẹ̀ ni ọkà rẹ̀ ti balẹ̀ tí àyè sì ti gbà á láti lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti gbé èdè, àṣà àti lítíréṣọ̀ Yorùbá lárugẹ. Ìràwọ̀ rẹ̀ si bẹ̀rẹ̀ sí í tàn gidigidi lẹ́nu iṣẹ́ ìròyìn. Nígbà ti Bámijí Òjó wà ní “Radio Nigeria” kí ó tó lọ sí “Western Nigerian Television Station (WNTV)” ni wọ́n ti kọ́kọ́ ran àwọn oníṣẹ́ ibẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Rédíò. Ilé iṣẹ́ Rédíò ní Ìkòyí ni wọn ti gba idánilẹ́kọ̀ọ́ yìí. Ìdí nip é tí ènìyàn bá máa sọ̀rọ̀ nílé iṣẹ́ “Radio Nigeria”nígbà náà ó gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀kọ́. Lára àwọn ètò tó máa ń ṣe lórí ẹ̀rọ Tẹlifísàn ni “Káàárọ̀-oò-jíire” àti “Tiwa-n-tiwa” túbọ̀sún Ọládàpọ̀, Láoyè Bégúnjọbí àti àwọn mìíràn ni wọ́n jọ wà níbi iṣẹ́ nígbà náà. Gbogbo akitiyan yìí mú kí ìrírí Bámijí gbòòrò si nípa iṣẹ́ ìròyìn àti ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn inú rẹ̀.

Ní ọdún 1976 ni Bámijí Òjó lọ fún ìdáni lẹ́kọ̀ọ́ ní Òkè Òkun, ní orílẹ̀ èdè kenyà níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí “Certificate Course In Mass Communication” (Ìlànà Ìgbétèkalẹ̀ lórí afẹ́fẹ́).

Nígbà tí ó di oṣù kẹwàá ọdún 1976, ni wọ́n dá àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ta sílẹ̀, Ọ̀yọ́, Òndó àti Ògùn, Bámijí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó kúrò ni ilé iṣẹ́ “Western Nigerian Broadcasting Services” àti “Western Nigerian Television Station (WNBS/WNTV) tí ó lọ dá Rédíò Ọ̀yọ́ sílẹ̀. Engineer Olúwọlé Dáre ni ó kó wọn lọ nígbà náà, Kúnlé Adélékè, Adébáyọ̀ ni wọ́n jìjọ dá ilé iṣẹ́ Rédíò sí lẹ̀ ni October 1976, wọ́n kó ilé iṣẹ́ wọn lọ sí Oríta Baṣọ̀run Ìbàdàn.

Nínú ọdún 1981 ni Bámijì Òjó tún pa iṣẹ́ tì, tí ó tún lọ fún ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ Rédíò ní ilé iṣẹ́ Rédíò tí ó jẹ́ gbajúgbajà ní àgbáyé tí wọn ń pè ní “British Broadcasting Co-operation (BBC) London fún Certificate Course.

Ní ọdún 1983 ni ó lọ sí orílẹ̀ èdè Germany fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Olóṣù mẹ́ta ní ilé iṣẹ́ Rédíò tí à ń pè ni “Voice of Germany”. Níbẹ̀ ló ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ Rédíò àti Móhùnmáwòrán. Ìgbà tí Bámijì Òjó dé ni ó jókòó ti iṣẹ́ tí ó yìn láàyò. Èyí ni ó ń ṣe títí tí wọ́n tún fi pín Ọ̀yọ́ sí méjì tí àwọn Ọ̀ṣun lọ, èyí mú kí àǹfààní wà láti tẹ̀ síwájú. Oríṣìíríṣìí ìgbéga ni ó wáyé nígbà náà ṣùgbọ́n ìgbéga tí ó gbẹ̀yìn nínú iṣẹ́ oníròyìn ni “Director of Programmes’ tí wọ́n fún Bámijí Òjó nínú oṣù kẹsàn-án, ọdún 1991, Ó sì wà lẹ́nu iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí olùdarí àwọn ẹ̀ka tí ó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ títí di ọdún 1994. Ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1994 ni ó fẹ̀yìn tì.

Ní ọdún tí ó tẹ̀lé, nínú oṣù kìíní ọdún 1995 ni Bámijì Òjó dá ilé iṣẹ́ tirẹ̀ náà sílẹ̀. Èyí tí ó pa orúkọ rẹ̀ ní ‘Bámijí Òjó Communicatio Center’.

Bámijì Òjó tin í iyàwó bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run sì ti fi ọmọ márùn-ún dá a lọ́lá.

Oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn móríyá àti ìkansáárásí ni Bámijí Òjó gbà nígbà tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ijọba. Fún orí pí pé àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀ tí ó fi hàn ní ilẹ̀ Germany. Ó gba onírúurú ẹ̀bùn fún àṣeyọrí àti àṣeyege ní òpin ẹ̀kọ́ náà. Pẹ̀lú ìrírí àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ ní ‘London’ àti ‘Germany’ó di ọmọ ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí ‘Overseas Broadcasters’ Association’.

Ní ọdún 1990 ni ọ̀gágun Abudul Kareem Àdìsá fún Bámijí Òjó ní ẹ̀bùn ìkansáárá sí, èyí ni ‘Ọ̀yọ́ State Merit Award for the best producer or the year’. Fún ìmọ rírì ètò tí ó ń ṣe ní orí ‘Television Broadcasting Co-operation Ọ̀yọ́ State (BCOS)’ Ṣó Dáa Bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ń jé àǹfààní rẹ̀, Aláyélúwà Ọba Emmanuel Adégbóyèga Adéyẹmọ Ọ̀pẹ́rìndé 1. ni ó fi oyè Májẹ̀óbà jẹ́ ti ilú Ìbàdàn dá a lọ́lá, nínú oṣù kọkànlá ọdún 1994. 1.5 Bámijì Òjó Gẹ́gẹ́ Bi Ònkọ̀wé Ìwé Ìtàn Àròsọ Yorùbá

Ìwé kíkọ jẹ ohun ti Bámijì Òjó nífẹ̀ẹ́ sí. Ọba Adìkúta jẹ́ ọ̀ken lára ìwé méjì sí mẹ́ta tí ó ti kọ jáde.

Ìwé àkọ́kọ́ tí Bámijì Òjó kọ jáde ni Mẹ́numọ́. Ìwé yìí jáde ni ọdún 1989.

Lẹ́yìn èyí ni Bámijì Òjó kọ ìwé rẹ̀ kejì. Ọba Adìkúta tí ó jáde nínú oṣù kẹta ọdún 1995.

Nígbà tí Bámijì Òjó wà ní ilé iṣẹ́ “Radio Nigeria” ni ó ti kọ́kọ́ kọ ìwé kan tí ó pè ní Àṣà Àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá. Ìwé yìí wà lọ́dọ̀ àwọn atẹ̀wétà tí ó gbàgbé sí wọn lọ́dọ̀ tí kò sì jáde di òní olónìí.

Bámijì Òjó gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí ó ní ìtara ọkàn. ó tún ní àwọn ìwé méjì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí yóò jáde ní àìpẹ́. Àkọ́kọ́ ni Ṣódaa Bẹ́ẹ̀. Ìwé yìí jẹ́ àbájáde ètò kan tí ó ṣe pàtàkì lórí Rédíò.

Òmíràn ni ètò Èyí Àrà. Bámijí Òjó ni ó dá ètò náà sílẹ̀¸ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹrin ọdún 1984. Ní ilẹ̀ Yorùbá pàápàá jù lọ “South West”, òun ni ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kò sí ilé iṣẹ́ Rédíò tí ó síwájú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ètò yìí “Phone In” Èyí Àrà.

  • A.O. Adeoye (2000), ‘Ìtàn Ìgbésí Ayé Bámijí Òjó’, láti inú Àtúpelẹ̀ Ìwé Ọba Adìkúta tí Bámijí Òjó ko.’, Àpilẹ̀kọ fún Òyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀ Nigeria.