Bizunesh Deba
Òrọ̀ ẹni | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 8 Oṣù Kẹ̀sán 1987 Ethiopia |
Sport | |
Orílẹ̀-èdè | Ethiopia |
Bizunesh Deba ni a bini ọjọ kẹjọ, óṣu September, ọdun 1987 jẹ elere sisa lobinrin ti ilẹ Ethiopia to da lori ere sisa ti ọna jinjin[1]. Arabinrin naa ṣè dada julọ ni ọdun 2014 ninu Marathon ti Boston pẹlu wakati 2:19:59[2].
Àṣèyọri
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ni ọdun 2004, Deba kopa ninu ere sisa ti ilẹ Japan pẹlu wakati 15:52.33 fun metres ti ẹgbẹrun maarun. Lati ọdun 2009, Deba ti yege ninu Marathon ti California, Marathon ti San Diego, Marathon ti Los Angeles, Marathon ti Boston, Marathon ti Twin Cities[3][4].[1] Arabinrin naa pari pẹlu ipo ọkan lara mẹwa to dara julọ ni Marathon ti New York City. Ni ọdun 2011, Deba kopa Marathon ti San Diego to si pari pẹlu wakati 2:23:31. Deba kopa ninu Marathon ti New York City pẹlu wakati 2:23:19 to si pari pẹlu ipo keji. Ni ọdun 2013, Deba kopa ninu Marathon ti Houston ni wakati 2:24:26 to si pari pẹlu ipo keji. Ni 2014, Deba kopa ninu Marathon ti Boston to si yege pẹlu wakati 2:19:59. Ni ọjọ keji, óṣu November, ọdun 2014 Deba gbe ipo kẹsan lori papa iṣere ti awọn óbinrin ninu Marathon ti New York City pẹlu wakati 2:31:40. Ni ọdun 2015, Deba pari pẹlu ipo kẹta ninu Marathon ti Boston pẹlu wakati 2:25:09[5][6].