Bonnie Mbuli
Ìrísí
Bonnie Mbuli | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹta 1979 Soweto, South Africa |
Orúkọ míràn | Bonnie Henna |
Ẹ̀kọ́ | Belgravia Convent[1] Greenside High School |
Iṣẹ́ | |
Olólùfẹ́ | Sisanda Henna (m. 2005; div. 2013) |
Àwọn ọmọ | 2 |
Bonnie Mbuli (bíi ni ọjọ́ kẹta oṣù kẹta ọdún 1979[2]) jẹ́ òṣèré, agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ati ọlọ́jà ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà. Ó ṣe atọkun fun ètò Afternoon Express. Ní ọdún 2020, ó kó ipa Jasmine Hadley nínú eré Nought and Crosses tí BBC gbé jáde.
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí sì ìlú Soweto ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà ni ọdún 1979. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Dominican Convent School àti Greenside High School ni ìlú Johannesburg. Òun ni àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ mẹ́ta tí àwọn òbí rẹ bí.
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe eré nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹtàlá, ó sì kópa nínú eré Viva Families ni ọdún 1992.[3]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Invictus (2009)
- Catch A Fire (2006)[4]
- Drum (2004)
- Gaz'lam (13 episodes, 2003–2004)
- Traffic! 12 February (2014)
Igbe ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mbuli fẹ́ òṣèré àti agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí orúkọ rẹ jẹ́ Sisanda Henna, wọn sì ní ọmọ méjì. Leyin ti wọn pínyà, ó kọ ìwé ìtàn nípa ayé rẹ̀.[5]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Dominican Convent School". dominican.co.za.
- ↑ Julie Kwach (16 August 2019). "Bonnie Mbuli biography:age, husband, boyfriend, book, and Instagram". briefly.co.za.
- ↑ "Bonnie Mbuli | TVSA". www.tvsa.co.za. Retrieved 23 May 2018.
- ↑ South Africa's Henna Is on 'Fire', Washington Post, accessed July 2013
- ↑ "Bonnie hangs out dirty linen". SowetanLIVE.