Chemama
Ìrísí
Chemama jẹ́ orúkọ àdúgbò tí ó wà ní àríwá eti odò Senegal, ní Mauritania: ilẹ̀ náà tó kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n ní àríwá eti odò náà. Òun ni agbègbè fún iṣẹ́ àgbẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Mauritania.
Ìgbà òjò ní agbègbè Chemama jẹ́ láàrin ọdún oṣù karùn-ún sí oṣù kẹsàn-án, òjò tí ó ń rọ̀ ní agbẹ̀gbẹ̀ Chemama sì kéré níye.
Àwọn olùgbé àgbègbè náà jẹ́ àwọn ẹ̀yà Maures tí ó kó láti orílẹ̀ èdè Mauritanian àti àwọn aláwọ̀ dúdú tí ó kó láti àwọn orílẹ̀ èdè láti gúúsù Chemama.
Nígbà ìjọba akónilẹ́rú, àwọn Maure ma ń wá láti kó àwọn ǹkan iyebíye ní agbẹ̀gbẹ̀ náà. Ní àwọn ọdún 1980s, àgbègbè náà jé ibi tí ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn ìjà ẹ̀yà tí ṣẹlẹ̀, èyí sì mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláwò dúdú orílẹ̀ èdè náà kó lọ orílẹ̀-èdè Senegal ní ọdún 1989.