Child Trafficking in Nigeria

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Child trafficking in Nigeria jẹ́ kíkó ọmọdé lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́, o sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀ ní ilẹ̀ òkèèrè àti ilẹ̀ Adúláwọ̀. Kódà a ò lè sọ wí pé ìlú kan lára rẹ̀ mọ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀. Àmọ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣe pọ̀ tó, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ò nímọ̀ tó yanjú nípa rẹ̀. Kí a sọ ojú abẹ níkóò, iṣẹ́ yìí dá lórí kíkó àwọn ọmọdé lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ nílẹ̀ Nàìjíríà.

Ki ní kíkó ọmọdé lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́? Èyí jẹ́ òwò tí àwọn ènìyàn máa ń ṣe láti gba òmìnira àwọn ọmọdé fún èèrè lókè òkun. Yálà lílo ẹ̀tàn, ìpátìkúùkù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ fi mú àwọn ọmọdé yìí ní ọ̀nà àìtọ́ lọ sí òkè òkun fún àwọn iṣẹ́ bí ọmọ ọ̀dọ̀, Aṣẹ́wo àti àwọn iṣẹ́ mìíràn tí kò bójú mu. Àwọn Ọ̀daràn lọ máa ń ṣe òwò yìí, tí a bá wòó dáadáa a ma rí wí pé kíkó ọmọdé lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ yìí ò yẹ kó jẹ́ òwò ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn láàágbayé ti mu gẹ́gẹ́ bí òwò.[1]

Látara ìwádìí àwọn àjọ́ igbìmọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò, àwọn ènìyàn bí 1.4 mílíọ̀nù ni ọdún 2021 ló wà lábé ẹ̀tàn àti ìpátìkúùkù kíkó wón lọ́nà àìtọ́ ní Nàìjíríà. Nínu iṣẹ́ yìí, a ma wo kí ni àwọn ohun tí ń fà á, kí ni àwọn ohun tó ń dá sílẹ̀ àti kí ni àwọn ọ̀nà àbáyọ.[2][3]



Àwọn ohun tó máa ń fà a.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àwọn ohun tó máa ń fa kíkó ọmọdé lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ yìí. Lára wọn ni Àìmọ̀kan, iṣẹ́, ìgbẹ̀yìn ogún jíjà tàbí ogún tó ń lọ lọ́wọ́, Àìrí ìṣe ṣe àti orírun ẹbí. Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ò nímọ̀ rárá tàbí kíkún nípa èyí. Bí àpẹẹrẹ tí àwọn ẹlòmíràn bá rí àǹfààní tó gọbọi lórí tẹlẹfísọ̀n tàbí rádìò, wọn ma bẹ mọ ni nítorí wí pé ìmọ̀ kékeré tí wọ́n nínú ò lè jẹ́ kì wọn rò ó wí pé wọn fẹ mú àwọn lẹ́rú ni. Yorùbá bọ̀, wọn ni ìfà máa ń fa ni lápò yan ni.[4]

Òmíràn tún ni iṣẹ́. Tí a bá wo awọn eniyan tí ó wà nínu ìṣe ni Nàìjíríà, a ma rí wí pé ó burú kọjá àyè. Nígbà tí ẹbi bá ń pa àwọn ọmọ ènìyàn, èyí lè mú wọn ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe. Ohùn kékeré báyìí ni àwọn Ọ̀daràn yìí ma fi tàn wọ́n.

Tí a bá wo ìgbẹ̀yìn ogún, a ma rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ lórí rẹ. Ọkàn nínú lẹ́yìn ìgbẹ̀yìn ogun gboogbò tó ṣẹlẹ̀ ni Nàìjíríà ní ọdún 1967 sí ọdún 1970. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn lo ma mú àwọn ọmọdé lọ sókè òkun tí òwò burúkú yìí. Tí a bá wo èyí tó ń ṣẹlẹ̀ ní Russia àti Ukraine báyìí a ma rí wí pé àwọn tó ní ṣe òwò yìí ń lò àǹfààní ogún yìí. Àìrí ṣe àwọn ọmọde Nàìjíríà náà ma jẹ́ kí àwọn ọníṣe ibi yìí rí wọn tètè mú lọ sí ilẹ̀ òkèèrè láìmọ̀ ohun tí wọn fẹ́ lọ ṣe ní pàtó.[5]



Àwọn ohun tó máa ń dá sílẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ohun tí Kíkó ọmọdé lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ máa ń dá sílẹ̀ ò dáadáa rárá. Ó lè mú àwọn ọmọdé yìí ní àrùn ọpọlọ, kí wọ́n fẹ́ pa ara wọn tàbí àrùn kògbóògùn nígbà míràn. Tí a bá sọ wí pé àrùn ọpọlọ, èyí ò tún sí wí pé wọn ti ya wèrè. Ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí ò lẹ́tọ̀ọ́ tí wọn bá ṣe fún wọn má jẹ́ kí ọpọlọ wọn máa à pé dáadáa. Ní ti àrùn kò gbó oògùn, tí ènìyàn tó bá ní àrùn kògbóògùn bá bá àwọn ọmọdé yìí lásẹpọ̀. Àrùn náà jẹ́ tiwọn nìyẹn.[6][7]

Àwọn ọ̀nà àbáyọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ̀kọ́ ṣe pàtàkì gan-an nínu ayé àwọn ẹ̀dá. Nígbà tí a bá kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ọmọ Nàìjíríà ní ìmọ̀ nípa Kíkó ọmọdé lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ yìí, o ma mú wọn ìmọ̀ nígbà tí ẹnì kan bá fẹ́ mú wọn.[8] Ogun jíjà ò ń ṣe ọ̀nà àbáyọ lati parí nǹkan. Èyí ni ó yẹ kí àwọn ìjọba wa mọ̀. Ní ti ìṣẹ́ àti Áìníṣẹ́ lọ́wọ́, sùúrù ni kí àwon òbí àwọn kọ́ àwọn ọmọdé. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹnikẹ́ni tó bá ní sùúrù, ohun gbogbo ló ní.[9]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "National Human Trafficking Hotline". National Human Trafficking Hotline. Retrieved 2022-03-30. 
  2. "Nigeria". United States Department of State. 2021-08-05. Retrieved 2022-03-30. 
  3. "Trafficking in Nigeria - committed to the enforcement of Women and children’s rights". Women's Consortium of Nigeria. Archived from the original on 2023-05-20. Retrieved 2022-03-30. 
  4. "Causes & Effects of Human Trafficking". The Exodus Road. 2021-07-06. Retrieved 2022-03-30. 
  5. "Human Trafficking in Nigeria". Africa Faith and Justice Network. 2017-07-28. Retrieved 2022-03-30. 
  6. Anuforom, Eunice I. (2015-02-20). "THE SOCIAL AND ECONOMIC IMPLICATIONS OF HUMAN TRAFFICKING IN NIGERIA: NAPTIP IN FOCUS". DigitalCommons@University of Nebraska - Lincoln. Retrieved 2022-03-30. 
  7. "Trafficking of Women in Nigeria: Causes, Consequences and the Way Forward". The Consortium on Gender, Security and Human Rights. Retrieved 2022-03-30. 
  8. "Causes and Solutions to Child Trafficking in Nigeria". Bscholarly. 2020-08-14. Retrieved 2022-03-30. 
  9. "20 Ways You Can Help Fight Human Trafficking". United States Department of State. 2021-01-11. Retrieved 2022-03-30.