Jump to content

Cleopatra

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Cleopatra VII)
Cleopatra
Photograph of an ancient Roman marble sculpture of Cleopatra VII's head as displayed at the Altes Museum in Berlin
ère Cleopatra.
Co-rulers Àdàkọ:Ancient Egyptian royal titulary case
Spouse
Issue
Full name
Cleopatra VII Thea Philopator
Father Ptolemy XII Auletes
Mother Presumably Cleopatra VI Tryphaena (also known as Cleopatra V Tryphaena)[note 1]
Born Early 69 BC or Late 70 BC
Alexandria, Ptolemaic Kingdom
Died 10 August 30 BC (aged 39)[note 2]
Alexandria, Roman Egypt
Burial Unlocated tomb
(probably in Egypt)

Cleopatra VII Philopator jẹ́ ọbabìnrin Ptolemaic tí Orílẹ̀-èdè Ẹ́gíptì Ayéijọ́un láàrin ọdún 51 sí 30 BC.[note 3] Ó jẹ́ ọmọ ìran Ptolemaic, àti ọmọ ẹni tí ó pilẹ̀ ìran náà, Ptolemy I Soter, ẹni tó jẹ́ ológun àti ọ̀rẹ́ Alexander the Great.[note 4] Lẹ́yìn ikú Cleopatra, Egypt di ọkàn lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà lábé ìjọba Ìjọba Rómù. Bí ó tilè jẹ́ wípé èdè tí Cleopatra kọ́kọ́ mọ̀ nias Koine Greek, òun nìkan ni ará Macedonia tí ó dárí Egypti tí ó sì tún kó èdè àwọn ará Egypti.[note 5]

Ní ọdún 58 BC, Cleopatra tẹ̀lé bàbá rẹ̀, Ptolemy XII Auletes, nígbà tí ó sá lọ Rómù lẹ́yìn ìgbà tí Egypti dìde si, tí eléyìí sì fún ọmọ rẹ̀, Berenice IV láti gba ìtẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Wọn pa Berenice IV ní ọdún 55 nígbà tí Ptolemy padà sí Egypti pẹ̀lú àwọn ológun Rómù. Nígbà tí Ptolemy fi ayé sílè ní ọdun in 51, àpapọ̀ ijoba Cleopatra àti arákùnrin rẹ̀, Ptolemy XIII bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ìjà láàrin wọn fa ogun abẹ́lé. Léyìn ìgbà Juliu Késárì ségun ọ̀rẹ́ Ptolemy XIII kan, Pompey lójú ogun, ó sá lọ Egypti. Pompey jẹ́ ọ̀rẹ́ sí Ptolemy XII, ṣùgbọ́n Ptolemy XIII rán àwọn ológun rẹ̀ láti pa Pompey lẹyìn ìgbà tí àwọn ọmọ isẹ́ rẹ̀ láàfin gbá ní ìyànjú láti pa Pompey kí Caesar tó dé. Nítorí èyí, Caesar gbìyànjú láti parí ìjà tó wà láàrin Ptolemy àti Cleopatra, ṣùgbọ́n olórí àwọn tó ń gbá Pompey ní ìyànjú, Potheinos wòye pé ìkan tí Caesar fẹ́ ṣe ma ran Cleopatra lọ́wọ́. Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ká òun àti Caesar mọ́ ààfin. Léyìn ìgbà díè tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn ológun mìíràn dé láti ran Caesar lọ́wọ́, Ptolemy XIII kú nígbà ogun tó ṣẹlẹ̀ Nílé.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]


Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tags exist for a group named "note", but no corresponding <references group="note"/> tag was found