Cysticercosis
Cysticercosis | |
---|---|
Magnetic resonance image in a person with neurocysticercosis showing many cysts within the brain. | |
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta | |
ICD/CIM-10 | B69. B69. |
ICD/CIM-9 | 123.1 123.1 |
DiseasesDB | 3341 |
MedlinePlus | 000627 |
Cysticercosis jẹ́ àkóràn àrùn inú ẹran ara, èyítí ọmọ inú (cysticercus) aràn mùjẹ̀mùjẹ̀ pẹlẹbẹ inú ẹran ẹlẹ́dẹ̀ (Taenia solium) má a nṣe òkùnfà rẹ̀.[1][2] Àwọn ààmì àìsàn náà lè farahàn lára ènìyàn ní ṣókí, wọn sì lè má farahàn rárá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Àwọn ohun líle kan tí kìí dun ni, tó tó bíi sẹntimita kan sí méjì, lè wú sórí awọ ara àti ẹran ara ẹni, tàbí kí ènìyàn ní àwọn ààmì àìsàn ètò iṣan nínú ara bí àrùn náà bá kan ọpọlọ ẹni.[3][4] Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tàbí ọdún àwọn ohun tó wú sí ni lára wọ̀nyí lè bẹ̀rẹ̀ síí dun ni, wọ́n lè wú síi, kí wọ́n tó wá lọ sílẹ̀. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ntẹ̀síwájú, èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun tó má a nsábà ṣe òkùnfà gìrì.[3]
Èyí a má a sábà wáyé lára ènìyàn bí ènìyàn bá jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tó ní ẹyin aràn mùjẹ̀mùjẹ̀ pẹlẹbẹ nínú. Ewébẹ̀ tí a kò sè dáradára jẹ́ orísun tó wọ́pọ̀ jùlọ.[2] Àwọn ẹyin aràn mùjẹ̀mùjẹ̀ pẹlẹbẹ a má a wá láti inú ìgbẹ́ ènìyàn tó ti ní àgbàlagbà aràn náà lára, oríṣi ipò àìsàn tí a mọ̀ sí taeniasis.[3][5] Taeniasis jẹ́ àrùn ọ̀tọ̀, a sì má a wáyé nípa jíjẹ àpò tí omi gbè sí, nínú ẹran ẹlẹ́dẹ̀ tí a kò sè jiná.[2] Àwọn ènìyàn tí nbá àwọn ẹni tó ní aràn mùjẹ̀mùjẹ̀ pẹlẹbẹ náà lára gbé ni ó wà lábẹ́ ewu tó ga jùlọ láti kó àrùn cysticercosis.[5] A lè ṣe ìwádìí àrùn náà nípa fífa omi, ọyún tàbí ẹ̀jẹ̀ jáde láti inú àpò tí omi gbè sí nínú ara.[3] Yíya àwòrán ọpọlọ pẹ̀lú fífi ẹ̀rọ kọmputa ya àwòrán onígun mẹta àwọn àgbékalẹ̀ ètò inú ara ènìyàn (CT) tàbí lílo iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ òòfà irin láti fi yàwòrán àwọn àgbékalẹ̀ ètò inú ara (MRI) jẹ́ àwọn ìlànà tó wúlò jùlọ láti fi ṣe ìwádìí àrùn náà nínú ọpọlọ. Iye ìwọ̀n funfun inú ẹ̀jẹ̀, tí a npè ní eosinophils, nínú omi inú ọpọlọ àti ẹ̀jẹ̀ ni a tún má a nlo gẹ́gẹ́ bí atọ́ka.[3]
A lè dènà àkóràn àrùn bí ó ti yẹ nípasẹ̀ ìmọ́tótó ara ẹni àti àbójútó ìlera. Lára èyí ni: síse ẹran ẹlẹ́dẹ̀ dáradára, àwọn ilé ìyàgbẹ́ tí ó tọ́ àti níní ànfàní sí omi tí ó mọ́ lásìkò tó yẹ. Ìtọ́jú àwọn ènìyàn tó ní taeniasis ṣe pàtàkì ní dídènà ìtànkálẹ̀ rẹ̀.[2] Ó ṣeé ṣe kí a máṣe nílò láti ṣe ìtọ́jú àrùn náà tí kò bá kan ètò iṣan inú ara.[3] Ìtọ́jú àwọn ẹnití ó ní neurocysticercosis lè jẹ́ nípasẹ̀ àwọn egbògi tí a npè ní praziquantel tàbí albendazole. A lè nílò àwọn wọ̀nyí fún àsìkò pípẹ́. Àwọn Steroid, fún mímú ibití ó wú lọ sílẹ̀ nígbà ìtọ́jú, àti àwọn egbògi tí ndènà gìrì ni a tún lè nílò pẹ̀lú. A má a nṣe iṣẹ́-abẹ nígbà mìíràn láti yọ àpò tí omi gbè sí náà kúrò.[2]
Aràn mùjẹ̀mùjẹ̀ pẹlẹbẹ inú ẹran ẹlẹ́dẹ̀ wọ́pọ̀ púpọ̀ ní Eṣia, Gúsù Sàhárà Afirika, àti Amẹrika Latini.[3] Ní àwọn agbègbè kan, a gbàgbọ́ pé iye tó tó mẹẹdọgbọn nínú ọgọrun (25%) àwọn ènìyàn agbègbè náà ni ó ní àkóràn àrùn yìí.[3] Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ní ìtẹ̀síwájú dáradára, kò wọ́pọ̀ púpọ̀ rárá.[6] Káàkiri àgbáyé, ní ọdún 2010, ó ṣe òkùnfà ikú àwọn ènìyàn tó tó 1,200, èyí tó lọ sókè láti ènìyàn 700 tó kú ní ọdún 1990.[7] Cysticercosis tún má a nran àwọn ẹlẹ́dẹ̀ àti máálúù ṣùgbọ́n wọn kìí sábà fi ààmì àìsàn kankan hàn nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn kìí gbé ilé-ayé pẹ́ títí.[2] Àrùn náà ti wáyé lára àwọn ọmọ ènìyàn jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá.[6] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àrùn àwọn orílẹ̀-èdè ipa ọ̀nà oòrùn tí a kò bìkítà fún.[8]
References
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Roberts, Larry S.; Janovy, Jr., John (2009). Gerald D. Schmidt & Larry S. Roberts' Foundations of Parasitology (8 ed.). Boston: McGraw-Hill Higher Education. pp. 348-351. ISBN 978-0-07-302827-9.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 "Taeniasis/Cysticercosis Fact sheet N°376". World Health Organization. February 2013. Retrieved 18 March 2014.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 3.4 3.5 3.6 3.7 García HH, Gonzalez AE, Evans CA, Gilman RH (August 2003). "Taenia solium cysticercosis". Lancet 362 (9383): 547–56. doi:10.1016/S0140-6736(03)14117-7. PMC 3103219. PMID 12932389. http://linkinghub.elsevier.com/retrieve/pii/S0140-6736(03)14117-7.
- ↑ García HH, Evans CA, Nash TE, et al. (October 2002). "Current consensus guidelines for treatment of neurocysticercosis". Clin. Microbiol. Rev. 15 (4): 747–56. doi:10.1128/CMR.15.4.747-756.2002. PMC 126865. PMID 12364377. http://cmr.asm.org/cgi/pmidlookup?view=long&pmid=12364377.
- ↑ 5.0 5.1 "CDC - Cysticercosis".
- ↑ 6.0 6.1 Bobes RJ, Fragoso G, Fleury A, et al. (April 2014). "Evolution, molecular epidemiology and perspectives on the research of taeniid parasites with special emphasis on Taenia solium". Infect. Genet. Evol. 23: 150–60. doi:10.1016/j.meegid.2014.02.005. PMID 24560729. http://linkinghub.elsevier.com/retrieve/pii/S1567-1348(14)00053-7.
- ↑ Lozano R, Naghavi M, Foreman K, et al. (December 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604. http://linkinghub.elsevier.com/retrieve/pii/S0140-6736(12)61728-0.
- ↑ "Neglected Tropical Diseases". cdc.gov. June 6, 2011. Retrieved 28 November 2014.