Dorcas Coker-Appiah

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Dorcas Ama Frema Coker-Appiah (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹjọ ọdún 1946) jẹ́ àgbẹjọ́rò ti orílẹ̀-èdè Ghana àti a-jà-fẹ́tọ̀ọ́-obinrin àti olùdarí àgbà fún Gender Studies and Human Rights Documentation Centre, tí a tún mọ̀ sí "Gender Centre", ní Accra, Ghana. Ó ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe ní oríṣiríṣi ilé-iṣẹ́ tó ti ń ṣe ìgbélárugẹ jíjà fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ní ìlú rè àti ní àgbááyé.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dorcas Ama Frema Coker-Appiah tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹjọ ọdún 1946 ní Wenchi, ní iletò àwọn ọmọ Britàin ní Gold Coast (tó ti wá di Ghana).[1] Ní ọún 1970, Coker-Appiah gba oyè bachelor's degree nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin láti University of Ghana.[1]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1974, Coker-Appiah jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹgbé FIDA Ghana, òun sì ni igbá-kejì Ààrẹ láti ọdún 1988 wọ ọdún 1989, lẹ́yìn náà ni ó di Ààrẹ ní ọdún 1990 wọ ọdún 1991.[2] Òun ni Ààrẹ FIDA àti alámòójútó ìgbímọ̀ tó ń gbé ìwé jáde fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.[2]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 "Dorcas Coker-Appiah's CV" (PDF). ohchr.org. ohchr.org. Retrieved 9 November 2017. 
  2. 2.0 2.1 "WIPSEN-Africa: Board of Directors". WIPSEN-Africa.org. Retrieved 10 November 2017.