Èdè Abínibí
Ìrísí
(Àtúnjúwe láti Ede Abinibi)
- N ò réni tó fèdè elédè ronú rí
- Àfi ti wa
- E wo gbogbo àwon ìlú ńlá
- Àwon ìlú kàǹkà-kàǹkà
- Ní gbogb ayé yíká kódà tée délèe Kùsà 5
- Irú èdè wo ni wón fi ń kómo?̣
- Èdèè-bílèe wón ni wón ń lo
- Wón sì ti digi osè, wón ti dàràbà
- E wAmerika, e wo Rósíà, ké e wáá wòlú Èèbó
- E ó ri pédèe won ni won fi ń ronú 10
- Ni wón fi tóbi
- Sùgbón bíi tèmi tìre kó
- Ká tóó pèrò ní Yoòbá
- Ká tóó yí i sÉèbó
- Gbogbo tepotiyọ̀ inú ọ̀rọ̀ 15
- Ti gbákúla
- Bóo la se lé fèdè elédè ronú jinlè
- Wón fomo odún méta sílé èkó
- Pé ó máa ko Faransé, ó máa kÉèbó
- Ó se, omó gbó Faransé díè, ó gbÉèbó díè 20
- Torí pó jómo-on Yoòbà
- Ó fi Yoòbá sàbùlàa won
- Òró di sákálá sokolo sòkòlò sákálá
- Ó ń relé kò délé
- Ó ń roko kò délé 25
- Àfóòfótán ojú a sì dásòólè
- Àdàlú èdè a fa hówùhówù dání
- Omo ò ní í lè dánú olóódoó rò
- Ohun a bá so fún un náà ní ó so padà bí ayékòótó
- Omo a délé 30
- A ní ‘Dádì, Yò bíládù fuù’
- Kò kúkú gbó, kò yé e páà
- Wón ti ní bí wón se ń so
- Séni tó se un tí ò dáa nù un
- Omo o sì mò péyìí yo bàbá òun sílè 35
- Bákan náà ni gbogbo èèyàn sorí lójúu won
- Won a kéyelé pò mádìye bó se wu wón
- Won a kó terú tomo tìwòfà pò
- Sé kò kúkú sówò nílúu won
- Ko sagba lómo ajá, àkóbí ajá, abíkéyìn béè 40
- N náà ni awon omo naa yoo se
- Ajísebí Èkó, Èkó ní í kúú sí
- Èyí tí ò yé won
- Po jèyí tó yé won lo
- N ò kúkú ráwon omo báwí ní tiwon 45
- Ohun a fi kó won ni wón gbà
- Wón ní amúkùn-ún, erù ré wó
- Ó ni e ò wòsàlè
- Mo ń bá ògá ilé ìwé pàtàkì kan
- Fòrò jomitoro òrò ńjó kan 50
- Ògá yìí kàwé a ò rírú e rì
- Ìwé tó kà tó bàmbà bamba
- Mo ní ‘Ògá, e bá n parí òwe yìí
- Edákun e fiyè dénú’
- Mo ní 55
- ‘Òní, àgbé pokó mó
- Òla, àgbé pokó mo’
- Wéré, Ogá ti kó sí mi lénu
- Ó lóun ti mò yóókù
- Kí n máà déènà penu 60
- Ó ní
- ‘Lótùn-ún-ùn-la, àgbè á gbókó ńbi ó fi pamó sí
- À bé è réèmò, èyàn èèyàn-àn mi
- Èèmò lu kutu pébé tan
- Ó tún lu pèbé pèlú è 65
- Àgbàlagbà ló se báun parí òwe
- Ta ni ò mò péparí òwe ùn ni pé
- Ojo tókó ó pàgbè mó ń bò
- Táriwó á so
- E jòwó, e má se fojú òpè wògá 70
- Òpò ló ń pòwè Láwúwo
- Tó se bí gidi làwón ń se
- Ení jìn sí kòtò
- Ló dá lésè
- Ení forí tì í dópìn-in 75
- Àfàìmò kó mó daláàrúù
- Nnkan àrà gbáà
- Omo Oòdùa ò fálà fédèe rè mó
- Èdè tó ládùn tó yìí
- Le fowó òsì tì dànù 80
- Níbi orirí ti ń sunkún ilé
- Tówìwí ń sunkún àtibò oko
- Ibè le ti ta won-nle
- Tèdè elédè
- A wí tán 85
- Wón lédèe wa ò kún tó
- Wón lósàn tó wò tí ò dùn
- Bí ò kúkú wò, ó tó
- Kí làǹfààni olówó tí kò níyì?
- E sé, a dúpé 90
- Ó tán n bó kù?
- E máa pónró ńbíbà
- E máa so tiyín di sáré pegbé
- Ilé eni lèmí mò pónà pèkun sí
- Wón ní sòkòtòo Yoòbà ò balè 95
- Wón ní bá a gbá a létí
- Tá a kàn án ńkòó
- Tinú è ni yóò se
- E kú isé
- Èyin ologbón, èyin òmòràn 100
- ‘Òmòràn tí í mo tinú ìgbín nínú ìkarahun’
- Wón ní bá a bá ń fi Yoòbá kékòó
- A ó ti se pògòrò òrò tí ń be ní sáyéǹsì?
- A ó ti se pojíbírà àti joméńtìrì?
- A ó ti se poósínjìn? 105
- A ó ti pe kábóńdàosàìdì?
- Ti pai-áárú-sukuàdì ń kó?
- Sùgbón gégé bí mo se so sáájú
- Èyí tí ò yée yín
- Pò jèyí tó yée yín lo 110
- Tá ni ò mobi tóbìn-in fi ń tò?
- Tée ní ó kòdí sígbó
- Ó joun pé ò mohun tédè ń jé
- Ló jé e móon sò yú-ùn
- Àìmòkan, àìmòkàn 115
- Ló kúkú n báayín-ín jà, o jàre
- E kò mò pé
- Bí gbogbo omo káàárò o ò jíbí?
- Bá pé báyìí la ó máa pé nǹkan-an wa
- Òyìyè tí ń yè é ò sí 120
- Báyìí là ń se ńlèe wa
- Èèwò ibòmín-ìn
- Bá a bá so pé
- Báyìí la ó mó on poósínjìn
- Tá a sì fún kábó-ńdà-osàìdì lóóko 125
- Tá ni yóò ya sùtì ètè
- Tí ó so pé Sàngó ò ponmo-on re?
- E tilè so pé Yoòbá ò kún tó
- Ǹjé èyín mò pé
- Se lèdèé mó-on ń dàgbàá sí i 130
- Ó dàbí aso
- Tokan gbó tá a mú mí-ìn
- Èyin ti lo sápótí ìsúra
- Ké e wá à won èdè té e ti pa tì
- Ké e mú nínú-un won 135
- E fi fáwon nǹkan wònyí lóóko tuntun
- Bá a tilè sì ta á bó tì
- Kì ló so pé á mó lo sédè mí-ìn
- Loo yá oóko tá a ó máa pohun tuntun
- Púpò nínú Èèbó té è ń wò un 140
- Ara èdèe won kúkú kó nísèǹbáyé
- Mímú ni wọ́n mú láti ara èdèe Látín-ìn-nì, Gíríìkì àti Hébéérù
- Kò sóròò Matimátíìkì kankan ni Èèbó
- Tí kì í sèdèe Lárúbáwá ló ti wa 145
- Tá ni Lárúbáwá wáá sun mó jù nínú àwa àti Èèbó?
- Bóo ni tèmi tìre ti wáá jé
- Omo ìyáà mi?
- Ohun tí ò sì yée yín ni pé 150
- Òpò èdè ló sáà ti wo tiwa
- Tí kò sì se wá ni háà!
- Bóyá o ti gbàgbé àwon òrò
- Bí ‘àlàáfíà’, ‘àlùbáríkà’ àti ‘Dàńsíkí’
- Tí wón tinú Haúsá di ti wa 155
- N ò sèsè lè so tÈèbó
- Ìyún-ùn pò bíi kàasíǹkan
- Kí ló dé tá a tepele mó yìí
- Ká fóhun gbogbo lórúko
- Kó di ti wa?
- Bóya ògòrò èdè
- Tó wà ńlèe wa
- Ló ń ko yín lóminú
- Pé bí Haúsá bá ń fi ti è kómo
- Tí Íbò ń se bákan náà 165
- Ìgbà wo lòròo wa
- Ò ní í dàbí ilé gígaa Bábéélì?
- Ìdáhùn síyún-ùn-ùn ò le, òrée wa
- Bóko ò jìnà, ilá kó tì
- Orin tí kò sòro í dá 170
- Kì í sòro í gbè
- Bá a bá so pé ìsá ǹsalùbó
- Peerepe sì lègbèe rè
- Ìjà ò sí ńsóòṣì
- Sàdúrà n sàmín ni 175
- Bí Íbò bá ń fèdè abínibí kómo
- A ó tún rò ó kó dákun fiyè dénú
- Kó fòkan nínú Haúsá tàbí Yoòbá
- Kómo náà pèlú
- Bí Yoòbá bá ń lo tirè 180
- A óò ní kó fi òkan
- Nínú Haúsá tàbí Íbò kún un
- Bá Haúsá náà sì ni
- Yóò fi òkan nínúun
- Yoòbá tàbí Íbò tì í 185
- Kò ní í pé, kò ní í jìnà
- Tá a ó fi máa gbóraa wa
- Lágbòóyé
- Ìyún-un ni pé
- A fewé àdúgbò kàgbo omo 190
- Gbogbo rè a sì kú dùn-ún-ùn
- Bí ojú tó ti kékeé fọ
- Sé tójú bá ti kékeé fó
- Se ní í kú mòràn-ìn moran-in
- Òròo wa a sì dayò 195
- À sì fopé fÓlúwa
- A kúkú mọ̀ pédèe wa è é jé béè
- Àwa la tajà eèpè
- Tá a ń gbowó òkúta
- A ko fìlà fún wèrè 200
- Wèrè sì féé lo fìlà gbó
- N ò kúkú bá won wí
- Àbí ta ni a ó gbókó fún
- Tí ò ní í roko sódò ara è
- Àsá ló sì ń mádìyee wa sòle 205
- Òjò ló sì ń pàyèrèpè lówó
- Tó fi deni àkolù
- Kì í sì í règà títí
- Kómó inú rè má gbòn lebelebe
- Yóò balè yóò balè 210
- Ni labalaba fi ń wogbóó lo
- Bí wón se ń dìrò mápáá tó
- Apáa won ò kúkú ní í kápá
- Bí wón dìrò mọ́gi osè
- Apáa won ò ní í kósè 215
- Òjò iwájú ì í pahun
- Gbogbo epe tí a bá se lu Onítibí
- Ara ní í fi í san
- Ológbò o ní í fìgbà kan kúkú ìwò sílè
- Ìjímèrè ò ní í bá won kúkú òwòowòó 220
- Èdèe Yorùbá ò ní í kú mó wa lójú
- E dákun, e sàmín è.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |