Eégún

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Eegun)
Jump to navigation Jump to search

Eegun

Ìtàn tí n ó sọ nípa bí eégún ̣ṣe délé ayé yìí, mo gbọ́ ọ láti ẹnu baba babaà mi ni kí ó tó di pé wọ́n jẹ́ ìpè Olódùmarà ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́hìn. Ìdí pàtàkì tí ó jẹ́ kí n fi ara mọ́ ìtàn náà ni pé ó fi ara jọ ìtàn tí mo kà lórí nǹkan kan náà ìwé Òmọ̀wé J.A. Adédèjì1. Ìdí mìíràn tí ó jẹ́ kí n fi ara ḿọ́ ìtàn náà yàtọ̀ sí òmíràn nip é ẹnu àwọn tí mo ṣe ìwadìí lọ́wọ́ wọn kò kò lóŕi ọ̀rọ̀ náà. Ó dà bí ẹni pé olúkálukú ni ó fẹ́ fi bu iyi kún ìlú tirẹ̀ pé ní ìĺú tòun ni awo Iségún ti bẹ̀rẹ̀. Ògbẹ́ni Táyélolú Ṣáṣálọlá tí ó ń gbé ni ìlú Oǹd́ó tilẹ̀ sọ f́ún mi pé ní ìlú Ọ̀fà ni Eégun ti ṣẹ̀. Nígbà tí mo sì fi ọ̀rọ̀ wá a lénu wò, mo rí i pé ọmọ Ọ̀fà ni baba rẹ̀. Ọmọ Iwékọṣẹ́ tún sọ fún mí pé ó dá òun lójú pé ní ìlú Òkè-igbó lẹ́bàá Oǹd́ó ni Eégún ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.

Nínú Ìdàrúdàpọ̀ yìí ni mo wá rò ó pé bí ènìyàn bá fẹ́ẹ́ mọ òtítọ́ tí ó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà, àfi bí ènìyàn bá tọ Ifá lọ nítorí pé If́a kò ní í gbè sẹ́hìn ẹnìkẹ́ni. Orísìí ìtàn méjì ni mo sì wá rí ńinú Ifá. Ṣùgbọ́n ìtàn kéjì ni mo fi ara mọ́. Ìdí tí mo sì ṣe fi ara mọ́ ọn náà nip é ó jọ ìtàn tí mo ti gbọ́ lẹ́nu baba babaà mi. Èyí nìkan kọ́: mo fi ara mọ́


1. Adédèjì J.A. The Alárìnjó Theatre: The Study of a Yorúbà theatrical Art form its Origin to the Present Times. Ph.D. Thesis (University of Ibadan), 1969, pp. 20-90.

Ìtàn kejì yìí nítorí pé ó tún là wá lọ́yẹ lórí bí orúkọ náà, “Eégún”, ti ṣe bẹ̀rẹ̀.

Ìtàn àkọ́kọ́ yìí wà nínú Odù Èjì ogbè, Ẹsẹ̀ Èkejì. Ìbéjì ni wọ́n fi Eẹgún bí. Ọ̀kán kú èkejì sì wà láàyè. Èyí tí ó wà láàyè si wá ́n sunkún ṣá. Wọ́n wá dọ́gbọ́n, wọ́n dáṣọ̣ Eégún. Wọ́n mú èyí tí ó wà ẹnìkan lórí. Ẹni tí ó gbé Eégún náà ń pe ẹni tí ó wà láàyè pé: “Mọ́ tí ì wá o, Ìhín ò rọ̀ o ò.”

Ẹsẹ Ifá náà lọ báyìí:

“Ńí ọjọ́ tí Éégún dé ayé,

Ìbejì ni wọ́n bí i.

Ọ̀kan kú, ọ̀kan wà láàyè.

Èyí tí ó wà láàyè wáá sunkún títí,

Ni wọ́n bá dọ́gbọ́n,

Wọ́n dáṣọ Eégún.

Wọ́n mú èyí tí ó wà láàyè lọ sínú igbó.

Wọ́n gbé aṣọ Eégún náà bọ ẹnìkan lórí.

Ẹni tí ó gbé Eégún náà ń pé

Èyí tí ó wà láàyè pé:

Mọ tíì wá o,

Ìh́in ò rọ̀ o ó.

Èyí tí ó wà láàyè bẹ̀rẹ̀ síí sunkún,

1. Abimbọ́la Wandé, Awọn Odù Mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndímlógún. (memio), pp. 3-4.

Eégún náà yára wọ inú igbó lọ.

Aṣọ tí a dà bo alààyè lórí

Ni à ń pè ní ẹ̀kú Eégún.

Ẹ̀kú ayé o,

Ẹ̀kú ọ̀run,

N à ń pè ní èjìgbèdè ẹ̀kù.”

Ìtàn ke jì wà nínú ìwé Ọ̀mọ́wé J.A. Adédèjì tí mo ti tọ́ka sí tẹ́lẹ̀. Ńińu Odù Ọ̀wọ́nrínsẹ̀ ni ó wà. Ìtàn náà lọ báyìí: Nígbà TÌ Ọ̀wọ́nrín tí ọ́ ń gbé ní Ìsányín dolóògbé, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta - Arúkú, Arùḱu àti Aròḱu-rọja-má-tà kò ní owó lọ́wọ́ lati fi ṣe òkú bàbáa wọn. Ìrònú ọ̀ràn náà pọ̀ dé bi pé èyí Arúkú tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún gbogbo wọn fi ìlú sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èyí àtẹ̀lé rẹ̀, Arùkú, mú ìmọ̀ràn wá pé kí àwọn ó ta òkú náà1. Èyí àbúrò wọn, Aròkú-rọja-má-tà, bá kiri òkú náà lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ti kiri fún ìgbà díẹ̀ tí kò ti rí ẹni ra òkú náà ni ó ti sú u, ó sì wọ́ òkú náà jùnù sínú igbó; ó bá tirẹ̀ lọ. Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, èyí ẹ̀gbọ́n di baálé ilé, ó sì gba ipò bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ológbìín. Gẹ́gẹ́ bí ipò rẹ̀ òun ni ó sì wá di Ológbo2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé abuké ni, Aláàfin fún un ní ìyàwó kan, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìyá Mòsè. Ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọd́un, Mòsè kò gbọ́ mokòó

1. Wọn a máa ta òkú láyé àtijọ́ fún àwọn olóògùn tí wọn fẹ́ lo ẹ̀ya ara òkú náà.

2. Akígbe tí ́o sì máa ń ru ọ̀pá oyè Aláàfin. rárá; ó kàn ń fọwọ́ osùn nu ògiri gbígbẹ ni. Èyí ni ó mú kí ọkọ rẹ̀ Ológbìín tọ Ọ̀rúnmìlà lọ. Nígbà tí ó débà tí ó débẹ̀, ó ńi “emi ló dé tí ìyàwó òun fi rọ́mọ lẹ́hìn adìẹ tó bú púrú sẹ́kún?” Ọ̀rúnmìlà sì sọ fún un pé àfi tí ó bá lè ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún baba rẹ̀ tí ó ti kú kí ìyàwó rẹ̀ ó tó lè bímọ.

Ní àkókò yìí, Ìyá Mòsè ti lọ́ sọ́dọ̀ Amúsan láti lọ ṣe ìwádìí ohun tí ó fa sábàbí. Bí Ìyá Mòsè ti ń bọ̀ láti odò Asà níjọ̀ kan ni elégbèdè kan jáde sí i láti inu igbó tí ó sì bá a lòpọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ìyá Mosè ṣe bẹ́ẹ̀ lóyún. Mòsè kò sì lè jẹ́wọ̀ bí ó ṣe lóyún fún ọkọ rẹ̀. Ó sì fọ̀n ọ́n ó di ọ̀dọ̀ Ọlọ́pọndà tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Ìyá Mòsè. Níbẹ̀ ni ó ti bí ìjímèrè. Ìtìjú a máa pa gbajúmọ̀. Nígbà tíìtìjú pọ̀ fún Mòsè, ó tún fọn ọ́n, ó di ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Bí ó sì ti ń lọ lọ́nà ni ó ju ìjímèrè sínú igbó. Ṣé ọkọ rẹ̀ kò kúkú mọ nǹ̀̀kan tí ó bí. Nígbà tí ó dijọ̀ keje ni Ato tí ó jẹ́ ìyàwó Ògògó tí ó jẹ́ ọmọ Ìgbórí rí ìjímèrè igbó. Ní àkókò tí a ń wí yìí. Ológbìín ti gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Ó ti lọ sí ọ̀dọ̀ Ọ̀rúnmìlà, Ifá sì ti sọ fún un pé sùúrù lẹbọ. Ifá ní kí Ológbìín máa tọ́jú abàmì ọmọ náà, ṣùgbọ́n kí ó tún ṣe ẹ̀yẹ ìkọhìn fún baba rẹ̀ nìpa lílọ sí igbó níbi tí wọ́n ti rí abàmì ọmọ náà láti lọ ya eégún baba rẹ̀. Àwọn ohun tí Ifá pa láṣẹ ètùtù náà ni ẹgbẹ̀rin àkàrà, ẹgbẹ̀rin ẹ̀kọ, ẹgbẹ̀rin pàsán àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹmu. Igbó tí wọn ti ṣe ètùtù náà ni a mọ̀ sí igbó ìgbàlẹ̀ di òní olónìí.

Aláràn-án òfí tí ó jẹ́ ìyekan Ológbìín ni ó gbé aṣọ òdòdó tí baba Ológbìín tí ó ti kú ń lò nígbà ayé rẹ̀ bora, tí ó sì tún gbé abàmì ọmọ náà pọ̀n sẹ́hìn, tí ó sì ń jó bọ̀ wá sí àárín ìlú láti inú igbó náà pẹ̀lú ìlù àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lẹ́hìn rẹ̀. Ológbìín ti fi lọ̀ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún baba òun tí ó ti kú nítorí náà nígbà tí wọ́n rí Aláràn-án Òrí nínú aṣọ òdòdó, wọ́n ṣe bí Ológbìín tí ó ti kú ni, pàápàá tí abàmì ọmọ tí ó pọ̀n dà bí iké ẹ̀hìn rẹ̀. Àwọn ènìyàn ń sún mọ́ ọn láti wò ó dáadáa ṣùgbọ́n pàṣán tí wọ́n fi ń nà wọ́n kò jẹ́ kí wọn sì wọ ilé baba Ológbìín tí ó ti kú lọ. Bí àwọn ènìyàn ti ń wò ó ni wọ́n wí pé:

“Ẹ wo begun ẹni tó kú ti gún tó!

Egungun náà gún lóòótọ́!

Egungún gún! Egungún gún!”

Báyìí ni àrá ọ̀run náà ṣe ṣe káàkiri ìlú tí ó sì ń súre fún àwọn ènìyàn. Nígbà tí ó sì ṣe ó wọ káà lọ. Wọ́n sì pe Ato kí ó máa tọ́jú abàmì ọmọ náà. Wọ́n sì ń pe abàmì ọmọ náà níOlúgbẹ̀rẹ́ Àgan. Nínú káà yìí ni Ògògó tí ó jẹ́ ọkọ Ato, ti ń wo ọmọ náà nígbàkúùgbà. Àwọn ènìyàn inú ilé a sì máa pe Ògògó ní Alàgbọ̀ọ́-wá1. Alágbọ̀ọ́-wá yìí ni ó sì di Alágbàá (baba Maríwo) títí di òní olónìí. Odù Òwọ́nrínsẹ̀ náà nìyí:

“Arúkí,

Arùkú,

Aròkú-rọjà-má-tà.

Òkú tá a gbé rọjà tí ò tà;

1. Ìtumọ̀ èyí ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó wá.

La gbé sọ sígbó.

Òun la tún gbé wálé,

Tá a daṣọ bò,

Tá a ń pè léégún.

A dÌfá fún Ọ̀wọ́nrín Ìsányín

Tó kú tí àwọn ọmọ rẹ̀

Kò rówó sin ín.1

Bí a bá sì tún wo oríkì eégún, ọ̀rọ̀ nípa bí eégún ṣe kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ yóò túbọ̀ tún yé wa sí i. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀, oríkì ni ọ̀rọ̀ tí ó júwe ìwà, ìṣe2 àti Ìtàn ìbí àwọn òrìṣà, ènìyàn àti àwọn nǹkan mìíràn. Oríkì Egúngún náà lọ báyìí:

“Egúngún Ajùwọ́n,

Lùkùlùkù gbúù-gbúù!

A-rágọ̀ gbálẹ̀,

Egúngún kìkì egungun

T’Ògògó!

Òkú yìí gbérí!

Ẹni ará kan

Tí ń jí jó awo.

1. Adédèjì, J.A. The Alárinjó Theatre. The Study of a Yorùbá theatrical Art from its Origin to the Present Times. Ph.D. Thesis (University of Ibadan 1969). Pp. 60-88.

2. Babalọlá, A Àwọn Oríkì Orílẹ̀, pp. 11.


Ọ̀ṣọ̀ràn lokùn ń dè lÁgburè.

Ìgbà tí n kò ṣòràn okùn,

Kí lẹ mókùn so mí lápá sí?

Ọmọ kẹ́kẹ́ mo ṣá,

Mo mú ṣèwe lÁgburè.

Gọ̀ǹbọ̀ ni mo wà,

Mo mú ṣèwe nIgbórí1

‘Torí Ìgbórí mi lỌ̀yọ́ Mọ̀kọ.

Baba Arúkú,

Baba Arùkú,

Baba Aròkú-rọjà-ma-tà.

Òkú tá a gbé rọjà

Tá ò tà,

Òun la dáṣọ fún

Tá à ń pè léégún.

Ikú ‘i lÓdò.

Ọmọ atòkú jẹun,

Ọmọ atáyé solẹ̀ nÍgbàlẹ̀.

Baba Ato kékeré

A-bẹnu wẹ́jewẹ́jẹ.2

Báyìí a ti mọ̀ bí eégún ṣe kọ́kọ́ dé inú ayé nígbà ìwáṣẹ̀.

1. Àwọn Tápà ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.

2. Adédèjì, J.A. The Alárìnjó Theatre; (The Study of a Yorùbá Theatrical Art from its Origin to the Present Times.) Ph.D. Thesis (University of Ibadan 1969). Pp. 60.88.

Ṣùgbọ́n láyé òde òní ń kọ́? Báwo ni a ṣe ń ‘ṣẹ́’ eégún? Ó ṣòroó sọ pàtó pé kò níí sí ìyàtọ̀ díẹ̀ láti ìlú dé ìlú lórí ọ̀rọ̀ bí a ṣe ń ‘ṣẹ́’ eégún. Ṣùgbọ́n bí ìyàtọ̀ kàn tilẹ̀ wà náà, kò pọ̀ rárá. Mo léèrò wí pé àwọn obìnrin kò ní í mọ ìdí abájọ. Obìn in a sì máa mọ awo, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá tilẹ̀ mọ ọ́n, wọn kò gbọdọ̀ wí. Àgbàlagbà Ọ̀jẹ̀ nikan ni wọ́n ń ‘sẹ́’ eégún rẹ̀ bí ó bá kú. Bí a bá ti fẹ́ ‘ṣẹ́’ eégún ẹni tí ó ti kù yìí, a ó wá pàsán1 mẹ́ta, a ó wá aṣọ fúnfún tí ó tóbi, a ó tún wá ẹni tí kò sé kò yẹ̀ gíga ẹni tí a fẹ́ ‘ṣẹ́’ eégún rẹ̀ náà. Ìtàn sọ fún mi pé láyé àtìjọ́, tí wọ́n bá pe òkú Òjẹ̀ nígbà tí wọn kò bá tíì sin ín, pé ó maa ń dáhùn tí yóò sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n eke ti dáyé, aáṣà ti dÁpòmù, nǹkan ò rí bí í ti í rí mọ́ nítorí pé a kò lè ṣe é bí a ti í ṣe é tẹ́lẹ̀.

Bí àwọn èròjà tí a kà sílẹ̀ wọ̀nyí bá ti dé ọwọ́ àwọn àgbà Òjẹ̀, a ó mú ọkùnrin tí kò sé kò yẹ̀ gíga òkú Òjẹ̀ náà lọ sínú igbó ìgbàlẹ̀. Àwọn àgbà Ọ̀jẹ̀ nìkan ni wọ́n lè mọ ẹni náà. Lẹ́hìn èyí, àwọn Òjẹ̀ yókù àti àwọn ènìyàn yóò máa lu ìlù eégún ní ibi tí wọn ti pa pẹrẹu lẹ́bàá igbó ìgbàlẹ̀ náà. Ọ̀wẹ́wẹ́2 ni ìlù tí a ń wí yìí. Tí wọ́n bá ti ń lu ìlù báyìí, àgbà Ọ̀jẹ̀ kan yóò máa mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú pàṣán yẹn, yóò

1. Òpá àtòrì tí a fi irin gbígbóná ṣe ọnà sí lára tí àwọn tí ó máa ń tẹ̀lé eégún lọ sóde fi ń na ènìyàn.

2. Aparun tàbí igi tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, tí a sì ṣe é pelẹbẹ pẹlẹbẹ̀.

Sì máa fin a ilẹ̀ lẹ́ẹ́mẹ́ta mẹ́ta. Bí ó bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni yóò máa pe orúkọ ẹni tí ó ti kú náà tí a sì fẹ́ ‘sẹ́’ eégún rẹ̀ yìí. Nígbà tí ó bá ti fi pàṣán kẹta na ilẹ̀ lẹ́ẹ́kẹ́ta tí ó sì tún pe orúkọ ẹni tí ó ti kú náà, ẹni tí ó ti wà nínú igbó ìgbàlẹ̀ yóò dáùn, yóò sì máa bọ̀ pẹ̀lú aṣọ fúnfún báláú lọ́rí rẹ̀. Àwọn ènìyàn yóò sì máa yọ̀ pé baba àwọn dáhùn, pé kò tilẹ̀ kú rárá.

Bí babá bá ti jáde báyìí ni àwọn ènìyàn yóò máa béèrè oríṣìíríṣìí nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, tí baba náà yóò sì máa dá wọn lóhùn. Nígbà tí ó bá ti jó dáadáa fún ìgbà díẹ̀, yóò súre fún àwọn ènìyàn kí ó tó padà bá inú igbó ìgbàlẹ̀ lọ. Bí eégún ṣe ń jáde lóde òní nìyí ní ìlú Oǹdó.

BÍ EÉGÚN ÀTI ÒGBÉRÈ EÉGÚN ṢE DÉ ÌLÚ OǸDÓ

Gẹ́gẹ́ bí yóò ti hàn níwájú, kì í ṣe èdè tí àwọn ará Oǹdó ń fọ̀ lẹ́nu ni wọ́n fi ń kógbèérè: èdè Ọ̀yọ́ ni wọ́n ń lò. Èyí jẹ́ ìtọ́kasí kan láti fi hàn pé láti Ọ̀yọ́ ni eégún ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ kí ó tó tàn ká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá. Ní ayé àtijọ́, nígbà tí ogun àti ọ̀tẹ̀ pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ogún kó láti ìlú kan dé òmíràn. Àwọn mìíràn lè ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ kí wọn ó sì padà sílé nígbà tí wọn bá ti ra ara. Àwọn mìíràn a tilẹ̀ kúkú jókòó sí ìlú náà wọn a sì fẹ́ Ìyàwó níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ àṣà kò ṣeé fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò gbàgbé ẹ̀sìn wọn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé e

  • B.A. Akíndúró (1977), Bí Eégún ṣe Bẹ̀rẹ̀’, DALL OAU, Ifẹ̀ Nigeria