Elfenesh Alemu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Elfenesh Alemu ni a bini ọjọ kẹwa, óṣu June ni ọdun 1975 ni Lemo Arya, Arsi Zone jẹ elere sisa ti ọna jinjin órilẹ ede Ethiopia. Arabinrin naa gbajumọ lori ere ti Marathon[1][2][3].

Àṣèyọri[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Elfenesh ṣọju órilẹ ede Ethiopia ninu Olympics Summer ti ọdun 2000 ati 2004. Arabirnin naa kopa ninu Marathon ti Idjije Agbaye lori ere sisa lẹmẹrin lati ọdun 1997 de 2003. Alemu yege ninu idije marathon agbaye to waye ni ọdun 1994. Arabinrin naa gba ami ẹyẹ idanilọla ti idẹ ninu Ere gbogbo ilẹ Afirica ni ọdun 1995[4]. Alemu jẹ óbinrin ilẹ Ethiopia akọkọ to yege ninu marathon ti Amsterdam ni ọdun 1997. Alemu kopa ninu Marathon ti Nagano Olympic ni ọdun 2000. Ni ọdun 2002, Alemu gbe ipo kẹta ninu Marathon ti Boston[4]. Ni ọdun 2003, arabinrin naa yege ninu marathon awọn obinrin agabye to waye ni ilẹ Tokyo[5]. Ni ọdun 2009, Alemu gbe ipo kọkanla ninu Marathon ti Chicago. Arabinrin naa wa lara marathon ti Mumbai ti ọdun 2011 to si gbe ipo kẹta pẹlu wakati 2:29:04.

Itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. African Championship Marathon
  2. Race Winners
  3. Elfinesh ALEMU Profile
  4. 4.0 4.1 Boston Marathon
  5. Winner in Tokyo in 2:24:47