Jump to content

Eré wúrà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Eré wúrà ti Ọ̀gbéni Gabriel Afoláyan ko. Wúrà yíì jẹ́ ohun tí gbogbo ènìyàn fẹ́ jogún. Àwọn alówò funfun wa láti òkè òkun láti wa wúrà yíì ẹ̀re yíì bakan náà lójẹ́ ki a mò iye owó ti wúrà yi gbẹ́wòn ti o je 1billion US dollar. Enìkan ni ìdílé kookan ni o létò láti mo ibi tí wúrà yíì wa. Nínú eré yíì bakan náà arákùnrin yíì gbìyànjú láti mú àfojúsùn re wa si ìmúsẹ láti rí wúrà náà. Wọ́n si jẹ́ ki a mò wípẹ́ Ọgbà Ẹ̀wòn ni Ìpínlè Èkìtì ni wón ni wúrà yíì wa. Nítorí àti gbẹ́ wúrà yíì, arákùnrin yíì ni láti dáràn síra re lórùn. Ònà tí o gbà gbẹ́ wúrà yíì jádẹ ní láti pàdí àpòpò pèlú àwọn ẹlẹ́wòn tí o ku tí o si tàn wón wípẹ́ òun yóò gbẹ́ ilè tí a mò sí tunnel láti jẹ́ kí wón jádẹ. Èyí fún àwọn ẹlẹ́wòn tókù láti darapò mò lai mò wípẹ́ láti gbẹ́ wúrà náà jádẹ ní o se so fún wón wípẹ́ ki wón gbẹ́ ilè. Kamá fà òrò gùn, arákùnrin yíì fi tó Ògá ẹlẹ́́wòn létí nípa ohun ti o gbẹ́ wa sílè ẹ̀wòn, o fi òrò náà tó ọ̀gbẹ́ni náà létí eni ti à mò si Àlí bàbá. Arákùnrin yíì náà darapò mo láti jẹ́ ki isé náà jee àseyorí. Arákùnrin se àseyorí nínú isé náà sùgbón o tún ri ìdojùko láti òdò ìjoba nípa Wúrà yíì sùgbón o ko jálè láti gbe sílè fún ìjoba. Léyìn eré yíì arákùnrin yíì àti àwọn ti wón jo lọ́wọ́ nínú isé yíì di ènìyàn ńlá.