Erica Nlewedim
Erica Ngozi Nlewedim tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá Osú kẹta Ọdún 1994 jẹ́ ọmọ orílẹ̀ ède Nàìjíríà, àríwòse, gbajúgbajà asàfihàn orí amóhùnmáwòran àti alákóso Beluxia hair.
Ó jáwé olúborí níbi ìdíje àwọn ọmọbìrin tí ó rẹwà jùlọ ní orílẹ̀ ède Nàìjíríà ní ọdún 2014 tí wọ́n sì yán láti jẹ́ ọ̀kan lára akópa nínú gbajúgbajà Ètò "Big Brother Naija (season 5) (Lock Down Edition)"
Ìgbésí ayé àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Erica sínú ẹbí Eric Ike Nlewedim ní Umuahia ní ìpínlẹ̀ Abia ní agbègbè ilà oòrùn Nàìjíríà. Ó dàgbà sí ìlú Èkó. Ó jẹ́ akẹ́ẹ̀kọ́ jáde ilé ẹ̀kọ́ girama Victory Grammar School tí ó sì tẹ̀ síwájú ẹ̀kó rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Covenant University níbi tí ó ti kẹ́ẹ̀kọ́ jáde gẹ́gẹ́ bí alámòójútó òwò síse, ó sì tún tẹ̀ síwájú láti lọ kẹ́ẹ̀kọ́ ní Met Film School ní London.
Isẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àríwóse
Erica bẹ̀rẹ̀ isẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ tí ó ní sí isẹ́ àríwòse tí ó sì ní ilé isẹ́ rẹ̀ Beluxia hair. Isẹ́ Àríwòse rẹ̀ àkọ́kọ́ wá láti ọ̀dọ Natures Gentle Touch tí ó se èròjà ẹ̀sọ́ irun kí ó tó lọ darapọ́ mọ́ ìdíje àwọn ọmọbìrin tí ó rẹwà jùlọ ní orílẹ̀ ède Nàìjíríà ní bi tí ó ti sojú ìpínlẹ̀ kogi. Ó gba ẹ̀yẹ ẹni tí ó rẹwà jùlọ nínú àwòrán.
Isẹ́ eré síse
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2015 lẹ́yìn tí ó jáde ilé ẹ̀kó Met Film School, ó bẹ̀rẹ̀ isẹ́ tí ó yàn láàyò tí ó sì kópa ìsáájú nínú eré oníse Secrets and Scandals. Ó ti kópa nínú àwọn eré lórísirísi bí Royal Castle àti Being Farouka. Erica kó ipa takuntakun nínú eré aláwàdà Hire a Woman níbi tí orúkọ rẹ̀ tí ń jẹ́ Nifẹmi. Àwọn àgbà òsèré ilẹ̀ Nàìjíríà bí Alexx Ekubo, Nancy Isime, Uzor Arukwe ni ó kópa nínú eré náà. Ó tún kópa pàtàkì nínú eré Made in Heaven tí gbajúgbajà òsèré bí Richard Mofe-Damijo, Toyin Abraham and Ayo Makun kópa níbẹ̀.
Àfihàn orí Amóhùnmáwòrán
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2020 Erica kópa nínú Èto "Big Brother Naija (season 5) (Lock Down Edition)". Wọ́n já kúrò làárín wọn ní ọjọ́ kẹfà osù kẹ̀sán ọdún 2020. Lẹ́yìn èyí, wọ́n sètò owó U.S dollars ($100K) fún nípasẹ̀ GoFundMe, tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ báa dá owó tó tó fourteen thousand U.S dollars. kí ó tó kúrò, Erica tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn tí ó ti sẹ̀ wípé ìdààmú ìmọ́lára tí òhún dojúkọ ló jẹ́ kí òhun wu àwọn ìwà tí òhun wù sí wọn.
Isẹ́ tí ó bu òǹtẹ̀ lù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Erica bu òǹtẹ̀ ìsowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé isé bí Aaron Cosmetics, Access Bank plc and Maltina.
Eré tí ó ti kópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eré ìgbà díẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọdun | Eto | Ipa |
---|---|---|
Di asiko yi | Bieng Farouk | Afẹsọna Farouk |
Ere ilẹ Naijiria
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọdun | Akọle | ipa |
---|---|---|
2019 | Made in Heaven | Osere |
2016 | Poka Messiah | Osere |
2019 | Hire a Woman | Osere |
Awọn itọkasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- "11 things you didn't know about BBNaija's Erica". Vocal Media. November 27, 2020.
- ↑ "BBN Naija: Erica Biography and net worth". 360 Reporters.
- ↑ Jump up to:3.0 3.1 "Erica". Africa Magic. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ Olowolagba, Fikayo (2020-09-07). "BBNaija 2020: I don't hate Laycon — Erica". Daily Post Nigeria. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "BBNaija: Photos of Erica's father, Erik Ike Nlewedim pops up". ABTC.
- ↑ Posner, Abigail (2020-08-11). "Meet BBNaija 2020 housemate Ngozi "Erica" Nlewedim". Legit.ng. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "Erica Nlewedim". IMDb. Retrieved 2020-09-28.
- ↑ Says, Jemimah (2014-07-09). "Official Photos: Most Beautiful Girl in Nigeria (MBGN 2014) Contestants". SilverbirdTV. Retrieved 2020-09-28.
- ↑ Premium Times, Premium Times (2014-07-20). "19-year-old Iheoma Nnadi wins MBGN 2014 contest". Premium Times. Retrieved 2020-09-28.
- ↑ "I am here to stay, says Nollywood actress Erica". P.M. News. 2019-10-11. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "Being Farouk". m.startimestv.com. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ BellaNaija.com (2019-04-02). "Family Goals ?! Erica Nlewedim Had a 'Hire A Woman' Screening Party With Family". BellaNaija. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "Mofe-Damijo, AY, Kosoko light up Made In Heaven". Retrieved 2020-09-11.
- ↑ Olowolagba, Fikayo (2020-09-07). "BBNaija 2020: Erica breaks silence after disqualification". Daily Post (Nigeria). Retrieved 2020-09-11.
- ↑ Odutuyo, Adeyinka (2020-09-07). "Kiddwaya, Laycon, others talk about Erica's disqualification from show". Legit.ng. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "Erica disqualified from Big Brother Naija". Premium Times. 2020-09-06. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "Erica disqualified from Big Brother Naija". Premium Times. 2020-09-06. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "Wetin fans dey do to ginger Erica, disqualified Big Brother Naija housemate". BBC. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "Fans launch $100k fundraiser for Erica BBNaija disqualified housemate". P.M. News. 2020-09-06. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "BBNaija: Nigerians blast Erica fans for opening GoFundMe account, donating over $14k to her after disqualification". Vanguard News. 2020-09-07. Retrieved 2020-09-11.
- ↑ "BBNaija: "I don't hate you" Erica has a message for Laycon (Video)". ABTC. November 27, 2020.
- ↑ "BBNaija: Erica Apologizes for talking down on her fellow housemates (Video)". Linda Ikeji. November 27, 2020.
- ↑ "Erica: I'll love to apologise to everyone". The Nation.
- ↑ BellaNaija.com (2019-03-29). "Meet Erica Nlewedim The New Nollywood IT Girl". BellaNaija. Retrieved 2020-09-11.