Esther Agbájé
Esther Agbájé jẹ́ ọmọ ọdún márùnlélọ́gbọ̀n òṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn sí ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láti ṣojú Ìpínlẹ̀ Minnesota. [1] [2] Bàbá rẹ̀ jẹ́ Àlùfáà ìjọ Episcopal ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó fi Amẹ́ríkà ṣe ìbùgbé. Ìyá rẹ̀ jẹ́ afowóṣàánú tí ó kọ́ ìbùgbé fún àwọn ọmọ aláìlóbìí. [3] Esther ni yóò ṣojú agbègbè District 59B ní Ìpínlẹ̀ Minnesota nílé Ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. [4]
Ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Agbègbè kan ní St. Paul nílùú Brainerd lágbègbè Faribault lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Nàìjíríà bíi sio. Ó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ òfin ní Harvard Law School kí ó tó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Minnesota lọ́dún 2017. Bẹ́ẹ̀ náà kàwé gboyè nínú ìmọ̀ òṣèlú, (Political Science) ní The George Washington University ní Amẹ́ríkà. Ó kàwé gboyè dìgírì kejì ní University of Pennsylvania kí ó tó dára pọ̀ mọ́ òṣèlú. [5] [6] [7]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lọ́dún 2019, Esther gba àmìn-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò tó dára jù lọ ní Ìpínlẹ̀ Minnesota fún akíkanjú àti akitiyan rẹ̀ nínú iṣẹ́ agbẹjọ́rò, pàápàá jù lọ nípa jíjà fún ẹ̀tọ́ àwọn ayálégbé. Kí ó tó di àsìkò yìí, ó ti ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tí Amẹ́ríkà, U.S. Department of State. [8]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Oyeleke, Sodiq (2020-11-04). "US election: Nigerian-American, Esther Agbaje, wins legislative seat". Punch Newspapers. Retrieved 2020-11-05.
- ↑ "Another Nigerian, Agbaje, Wins Legislative Seat In United States". Sahara Reporters. 2020-11-04. Retrieved 2020-11-05.
- ↑ "About". Esther for State Representative. 2019-10-21. Archived from the original on 2020-11-05. Retrieved 2020-11-05.
- ↑ Nathaniel, Soonest (2020-11-04). "US Polls: Dabiri-Erewa Hails Victory Of Another Nigerian-American, Esther Agbaje". Channels Television. Retrieved 2020-11-05.
- ↑ Dernbach, Becky Z. (2020-08-26). "Esther Agbaje aims to be first Nigerian American in Minnesota legislature". Sahan Journal. Retrieved 2020-11-05.
- ↑ "Esther Agbaje". Ballotpedia. 2020-11-03. Retrieved 2020-11-05.
- ↑ "Three Nigerian-Americans win in U.S 2020 elections". Premium Times Nigeria. 2020-11-04. Retrieved 2020-11-05.
- ↑ "Candidate Profile for Esther Agbaje". iVoterGuide.com. 2020-11-03. Retrieved 2020-11-05.