Eye okin
Ìrísí
Ẹyẹ Ọ̀kín jẹ́ ọlọ́jà láàrin àwọn ẹyẹ. Ó jẹ́ arẹwà ẹyẹ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìyẹ́ aláràǹbarà ní ara rẹ̀. Ó jẹ́ ẹyẹ tí ó máa ń rìn ní orí ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kì í sááàbá fò bí àwọn ẹyẹ yòókù. Takotabo ni ẹyẹ ọ̀kín. Kò sí ẹni tí yóò rí ẹyẹ ọ̀kín tí kò ní fẹ́ràn rẹ̀ nítorí ẹ̀bùn ẹwà tí Elédùá fi jíǹkí rẹ̀ láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹyẹ.