Fíímù àgbéléwò
Fíímù àgbéléwò Jẹ́ àkáálẹ̀ fọ́rán tí wọ́n lè yá tàbí tà fún ìgbádùn ẹni tí ó fẹ́ wòó.[1] Orúkọ yí jẹyọ látara kásẹ́ẹ̀tì olókùn tí wọ́n ń pè ní VHS àti Betamax, nígbà tí wọ́n ṣàmúlò videotapes láti ṣe àkáálẹ̀ fọ́nrán, ṣáájú kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ń lo irinṣẹ́ DVD àti Blu-ray. [2]
Fíímù àgbéléwò ni àwọn ènìyàn tún ma ń lò láti fi ṣe ọrọ̀-ajé nípa yíyáni gbowó àti títà rẹ̀ tàbí kí wọ́n ma ṣàfihàn rẹ̀ lórí telifíṣàn fún àwọn ènìyàn àwùjọ lóríṣiríṣi. Àmọ́, láyé òde òní, fíìmù àgbèléwò ti wà ní orí ìkànnì ayélujára loríṣiríṣi tì àwọn ènìyàn lè ṣe àkáàlẹ̀ rẹ̀ sórí ẹ̀rọ ìgbéléwọ́ wọn tàbí sórí CD wọn. Àwọn irinṣẹ́ DVD àti CD kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ mọ́ láti ìgbà tí ẹ̀rọ áyelújara ti dé ní ǹkan bí ọdún 2010 sí ọdùn 2020 tí ó sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ gidi, tí àwọn ènìyàn sì ti láǹfàní láti ṣe àmúlò ayélujára láti fi jẹ̀gbádùn àwọn fọ́rán oríṣiríṣi.
Àwọn ìtọkasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "home video". Merriam-Webster. Retrieved Apr 29, 2020.
- ↑ "home video". Collins English Dictionary. Retrieved Apr 29, 2020.