Jump to content

Fila Abeti Aja

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Abetí ajá, túmọ̀ sí "bí etí ajá". Ó jẹ́ orísun Yorùbá, ìlú Ìbàdàn. Abetí ajá yìí ni fìlà tí a fi aṣọ òkè tàbí aṣọ àdìre rán. Ó jẹ́ apá kan ti aṣọ ọkọ ìyàwó máa ń wọ̀ nígbà ayẹyẹ ìgbéyàwó tàbí tí ọba, ẹni ọlọ́rọ̀ àti ẹni oyè máa ń wọ̀. Aṣọ òkè tí a fi ṣe fìlà abetí ajá yìí tún lè túmọ̀ sí aṣọ ipò gíga. Ó ní àgbékọjá méjì tó dàbí etí tó n má ń gbọ̀n bo etí, ìdí èyí ni wón máa ń pè é ní abetí ajá nítorí ó dàbí etí ajá. A máa ń wọ fìlà etí ajá yìí gẹ́gẹ́ bí aṣọ orí láti ṣe àfikún àwọn aṣọ abínibí bíi agbádá. Àṣà fìlà Yorùbá yìí dàbí ìgùn onígùn mẹ́ta tí ó ní etí méjì tí ó yọ jáde bí etí ajá. Àṣà yìí wọ́pọ̀ láàrin ọ̀dọ àti àgbàlagbà Yorùbá. Bákan náà, àwọn onílù ìbílẹ̀ Yorùbá kan fẹ́ràn láti wọ fìlà abetí ajá yìí. O lè wọ irú fìlà Yorùbá yìí kí o sì yí ipò àwọn ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ padà; wọ́n lè ṣe ìtọ́ka sí òkè, tàbí ṣe pọ̀ díẹ̀. Àṣà yìí jẹ́ ìgbà àtijọ́ àti pé ó jẹ́ olókìkí púpọ̀ pẹ̀lú aṣọ aṣọ-òkè àtijọ́.

Àwọn Ìtọ́ka Sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]