Grace Ebun Delano
Ìrísí
Grace Ebun Delano | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ọjọ́ kẹtàlá oṣù kọkànlá ọdun 1935 Kaduna |
Orílẹ̀-èdè | Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Núrsì |
Gbajúmọ̀ fún | Iṣẹ́ takuntakun ní ètò ibí ní Nàìjíríà |
Grace Ebun Delano (tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kọkànlá ọdún 1935, ní Kaduna) jẹ́ Núrsì àti agbẹ̀bí tí ó kópa nínú ètò "family planning" àti àwọn ǹkan míràn nípa ètò ibí ní Nàìjíríà. Ó wà lára àwọn tó dá ẹgbẹ́ Reproductive and Family Health kalẹ̀, òun sì ni adarí ẹgbẹ́ náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdun. Ní ọdún 1993, ó gba àmì-ẹ̀yẹ World Health Organization Sasakawa Award fún iṣẹ́ ribiribi rẹ̀ ní ètò ìlera ara.