Jump to content

Idíófóònù

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Idíófóònú ni ọ̀rọ̀ tí a fi máa ń ṣe àpèjúwe lọ́nà tí ó jẹ́ pé ìrísí tàbí ìtumọ̀ ohùn tí a ń ṣe àpèjúwe yóò yé ni dáadáa. Àwọn wọ̀nyí ni àbùdá Idíófóònú:

1. Idíófóònù gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kọ́ńsónáńtì.

2. Ìró ṣe pàtàkì nínú Idíófóònù yálà nípa fífarajọ ìró tí a ń ṣe àpèjúwe rẹ̀ tàbí nípa ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí a ń ṣe àpèjúwe.

3. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Idíófóònù ni a fi àpètúnpè ṣe ẹ̀dá wọn.

4. Idíófóònù kì í ṣe ìsòrí ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ nínú gírámà nítorí pé Idíófóònù lè jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé, ọ̀rọ̀ àpèjúwe tàbí nígbà mìíràn ọ̀rọ̀ orúkọ. Bí àpẹẹrẹ:

* orí kọ̀bìtì - ọ̀rọ̀ àpèjúwe

* ó ń jà kìtìkìtì - ọ̀rọ̀ àpọ́nlé

* wọ́n ń ta wòsìwósì - ọ̀rọ̀ orúkọ

Oríṣi Idíófóònù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oríṣi mẹ́ta ni Idíófóònù: firósínròójẹ, firómọ̀rísí àti àìfirómọ̀rísí.

Ídíófóònù Firósínròójẹ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó jẹ́ èyí tí ìró Idíófóònù fara jọ ti nǹkan tí a ń ṣe àpèjúwe rẹ̀. Oríṣi mẹ́ta ni ìrísí Idíófóònù yìí.

A) Onísílébù kan tí ó ní kọ́ńsónáńtì àti fáwẹ́lì kan (KF)

Ó já bọ́ gbì

Ó ń ro tó

B) Onísílébù méjì tí ó ní kọ́ńsónáńtì kan àti fáwẹ́lì méjì (KFF)

Ó pupa fòò

Ó dá páú

D) Onísílébù méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú èyí tí kọ́ńsónáńtì tí ó ju ìkan wà

Ọbẹ̀ náà ń sọ ṣọ̀ṣọ̀

Idíófóònù Firómọ̀rísí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Idíófóònù firómọ̀rísí ni èyí tí ìró Idíófóònù fara jọ ìrísí ohun tí a ń ṣe àpèjúwe rẹ̀. Oríṣi méjì ni irú Idíófóònù yìí.

A) Ìfarajọra dá lérí kọ́ńsónáńtì àti fáwẹ́lì - kọ̀ǹtì, gọ̀lọ̀tọ̀, wọrọkọ

B) Ìfarajọra dá lérí ohùn - játijàti, pálapàla, réú rèù

Idíófóònù Àìfirómọ̀rísí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Idíófóònù kan wà tí ìró wọn kò fi bẹ́ẹ̀ tọ́ka sí ìtumọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ -

Ó dúró ṣinṣin

Ó dùn ṣinṣin

Ìṣẹ̀dá Idíófóònù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àpètúnpè ni a fi máa ń ṣẹ̀dá Idíófóònù, pàápàá àwọn Idíófóònù tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ sílébù. Oríṣi méjì ni ó wà:

Idíófóònù oní-àpètúnpè kíkún

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oríṣi mẹ́ta ni èyí

A) Àpètúnpè sílébù ẹyọ kan - ọkan rẹ̀ ń dún ki ki ki

B) Àpètúnpè sílébù tí ó ju ẹyọ kan láìsí àyípadà ohùn - ṣàmùṣàmù, wàìwàì

D) Àpètúnpè sílébù tí ó ju ẹyọ kan pẹ̀lú àyípadà ohùn. Irú yìí máa ń fún Idíófóònù ni ìtumọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ - wérewère, pálá pàlà pálá

Ṣùgbọ́n kòbẹ́gbẹ́mu ni àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ wọ̀nyí nítorí pé àyípadà ohùn kò fún wọn ní ìtumọ̀ ọ̀tọ́: fùkùfúkù, wòsìwósì.

Idíófóònù oní-àpètúnpè ẹlẹ́bẹ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Apá kan irú Idíófóònù báyìí ni a máa ń ṣe àpètúnpè fún. Bí àpẹẹrẹ

* geere - geerege

* wọ́ọ́rọ́ - wọ́ọ́rọ́wọ́

Ìsọdorúkọ Idíófóònù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀nà tí a fi ń ṣe ìsọdorúkọ láti ara Idíófóònù ni kí a fi àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ò/ọ̀ tàbí a kún Idíófóònù. Bí àpẹẹrẹ

* rara - ọ̀rara

* rinrin - ọ̀rinrin

* bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀ - ọ̀bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀

Ìfarajọra máa ń wà láàárín Idíófóònù àti àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ kan ṣùgbọ́n a ó lè ka àwọn eléyìí sí ìsọdorúkọ nítorí ìyàtọ̀ ìtumọ̀ tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín wọn. Bí àpẹẹrẹ

* ṣìgìdì (kí nnkan tóbi); ṣìgìdì (ère amọ̀)

* pàkìtì (kí nǹkan nípọn); pàkìtì (irú ẹni kan ti ó nípọn)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]