Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó
Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó àti Òkè-Igbó Láti ọwọ́ C.O. Ọdẹ́jọbí DALL, OAU, Ifẹ̀ Nigeria.
Dérìn Ọlọ́gbẹ́ńlá nì orúkọ ẹnì tí ó tẹ Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó dó1. Ọmọ ìlú Ifẹ̀ nì Ọlọ́gbẹ́ńlá, ó sì jẹ́ akíkanjú àti alágbára ènìyàn. Ìwádìí fi hàn pe, ọba Òṣemọ̀wé Oǹdó ló ránṣẹ́ sí Ọọ̀nì Abewéelá pé, kí ó rán àwọn ọmọ-ogun wá, kí wọ́n lè ran òun lọ́wọ́ latí ṣẹ́gun àwọn tí ó ń bá òun jà. Ọdún 1845 ni ọba Abewéelá rán Ọlọ́gbẹ́ńlá àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ jẹ́ ìpè ọba Òṣemọ̀wé ti Oǹdó2
Wọ́n sì tẹ̀dó sí Òkè-Igbó. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ní ọdún 1845 yìí kan náà, Ọlọ́gbẹ́ńlá kò padà sí Ifẹ̀ mọ́, ó kúkú fi Òkè-Igbó ṣe ibùjókòó rẹ̀. Gbogbo aáyan àwọn Ifẹ̀ láti mú kí Ọlọ́gbẹ́ńlá padà sí Ifẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti ṣẹ́gun ní Oǹdó ló já sí pàbó. Ní ọdún 1880 ní wọn fi jẹ Ọba èyí ni Ọọ̀ni ti Ifẹ̀, ṣùgbọ́n kò wá sí Ifẹ̀ wá ṣe àwọn ètùtù tí ó rọ̀ mọ́ ayẹyẹ ìgbádé ọba, Òkè-Igbó ni ó jókòó sí1 Òkè-Igbó yìí ní ó wà tí ọlọ́jọ́ fi dé bá a ní ọdún 18922.
Ní ọdún 1982 ni àwọn ara Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó kan fi ibinu ya kúrò lára Òkè-Igbó3, nítorí ọ̀rọ̀ ìlẹ̀. Oko-àrojẹ àwọn Òǹdó ni Òkè-Igbó kí ó tó dip é Ọlọ́gbẹ́ńlá àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi ibẹ̀ ṣe ibùjókòó wọn4. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé lórí ilẹ̀ Òǹdó ni Òkè-igbó wà ṣùgbọ́n àwọn Ifẹ̀ ni ó ń gbé ìlú náà. Nígbà tí àwọn Òyìnbó ń pín ilẹ̀ Yorùbá sí ẹlẹ́kùnjẹkùn, wọ́n pín Òkè-Igbó mọ́ Òǹdó. Ohun tí ó ṣẹ́lẹ̀ lẹ̀yín náà nip è àwọn Òǹdó ń fẹ kí àwọn tí ó wà lórì ilẹ̀ àwọn ní Òkè-Igbó máa san owó-orì wọn sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ Oǹdó. Bákan náà ni àwọn Ifẹ̀ ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó wà ní Òkè-Igbó san owó-orí wọn sí àpò ìjọba ìbílẹ̀ Ifẹ̀ nítorí pé Ifẹ̀ ni wọ́n1. Yàtọ̀ sí àríyànjiyàn tí ó wà lórí ibi tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn Òkè-Igbó san owó-orí sí, àwọn akọ̀wé agbowó-orí tún máa ń ṣe màgòmágó sí iye owó-orí tí àwọn èniyàn bá san2. Èyí ni pé ọ̀tọ̀ ni iye owó tí ó máa wà ní ojú rìsíìtì tí àwọn akọ̀wé agbowó-orí ń fún àwọn tí ó san owó-orí, ọ̀tọ̀ ni iye tí wọ́n máa kó jíṣẹ́. Gbogbo èyí ló dá wàhálà sílẹ̀ ní Òkè-Igbó ní àkókò náà. Ọba Ọọ̀ni Adérẹ̀mí ni ó pa iná ìjà náà nígbà tí ó pàṣẹ ni oḍún 1932 pé kí ẹni tí ó bá mọ̀ pé Ifẹ̀ ni òun, kúrò ní Òkè-Igbó, kí ó fo odò Ọọ̀ni padà sẹ́yìn kí ó tó dúró. Àwọn tí ó padà sí òdìkejì odò Ọọ̀ni ní oḍún 1928 ati ọdún 1932 ni a mọ̀ sí Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó lónìí.
Ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó, àwọn àdúgbò wọ̀nyí ló wà níbẹ̀: Ilé Badà, Oríyangí, Kúwólé, Aṣípa-Afolúmọdi, Mọ̀ọrẹ̀, balágbè, Fáró, Ìta-Akíndé, Odò-Odi, Òkè-Ẹ̀ṣọ̀, Òkèèsodà, Olú-Òjá àti Ọdọ́. Díẹ̀ lára àwọn àdúgbò wọ̀nyí wà ní Ifẹ̀, fún àpẹrẹ, Oríyangí, Mòọ̀rẹ̀, Òkè-Ẹ̀ṣọ̀, àti Òkèèsodà. Bákan náà ló jẹ́ pé gbobgo ọdún ìbílẹ̀ tí wọ́n ń ṣe ní Ifẹ̀ náà ni wọ́n ń ṣe ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó. Bí a bá tún wo ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó, ẹ̀yà ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni. Nítorí náà a gba orin èébú ní Òkè-Igbó àti Ifẹ̀ẹ́tẹ̀dó.
Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ Ẹ́meè C.O. Ọdẹ́jọbí