Ìgbìn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Igbin (Drum))
Jump to navigation Jump to search

Ìlù Ìgbìn Ìlù oriṣà Ọbàtálá ni ìlù yii ọjọ̀ àjọ̀dún Ọbàtálá ni àwọn olóòṣà yìí ńkó ijó Ìgbìn sóde. Oriṣii ìlù mẹ́rin la le tọ́ka sí lábẹ́ ọ̀wọ́ ìgbìn.

(a) Ìyá-nlá: Igi la fi n gbẹ́ ìlù yìí. Ihò ìnu ìgi naa si dọ́gba jálẹ̀. Awọ lafi ńbo oju ìgi ìlù yi lójù kan.

(b) Ìyá-gan: Ìlù yii lo tẹle iya-nla. Òun ló sì dàbí omele tàbí emele ìyá-ńlá,

(d) Keke: Ìlù yìi lo tẹle Iya-gan. Ó kó ìpa pàtàkì nínú ìgbin.

(e) Aféré: Ìlù yii lo kere jù nínú awọ ìlù mẹrẹẹrin ti a le tọka si nínú ọwọ ìlù igbin. Igi náà ni a fi n gbẹ ẹ bi i ti awọn mẹta yooku. Awọn ti n gbẹ ìlù yii máa n sojú àti ìmú sára ìgi ìlù yii.