Ijapa ati atioro

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ààlọ́ Ijàpá àti Àtíòro[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààlọ́ oooo

Ààlò

Ní igba kan rí ni ilu awon ẹranko, iyan mu ni ilẹ̀ naa, ìjàpá ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, òkú olè arise máṣe[1]. Ó ji lọwuro ọjọ kan, ebi npa gidigidi, alakori lọ yọjú wo ile ikounje pamọ si, kòrí nkankan nibe, òwú alantakun lo gba ibe kan, o jáde ósì bẹ̀rẹ̀ si nii ronú ohun tó le ṣe, ìjàpá ranti bí ọrẹ rẹ àtíòro ṣe nri oúnjẹ jẹ tí ojú rẹ si ń dán gbìnrìn. Ó pinnu láti lọ si ilé àtíòro nígbàtí ó dé ilé àtíhòro ó kan ilẹkun, àtíòro dáa lóhùn pé ta lo nkan ilẹkun, Ìjàpá dáa lóhùn pe èmi ìjàpá ọrẹ rẹ ni. Àtíòro bẹ̀rẹ̀ si níí i kí ọrẹ rẹ pe Ìjàpá tìrókò ọkọ yannibo, fìrì nìdí oke, a je ju olohun lọ, se kò sí tí a rí ọ? Ìjàpá ni òun wá kii ni, àtíòro nì àsìkò tí ènìyàn ma nwa kí yàn kọ nìyí, Ìjàpá ni ọrọ pàtàkì kan ní òun bá wá wípé bí ìyàn se mú tó yii àtíòro kò mọ pé ìyàn mú rárá, àti ìyàwó àti ọmọ àtíòro gbogbo wọn l'ójú wọn ndán, kinni wọn njẹ? Àtíòro ni Ìjàpá ko ṣé fi àṣírí hàn, nítorípé ẹnu re kìí mẹ́nu, opurọ ni, olofofo sì ni pẹ̀lú, Ìjàpá ni òdodo ni gbogbo ohun tí wọn sọ nípa òun ṣùgbọ́n tí ó bá fi àṣírí yìí hàn òun kò níí sí ewu, ẹnikẹ́ni kò níí gbọ́, àtíòro mí kanlẹ̀, ó ní o dára òun yóò fi han, ṣùgbọ́n ko gbọdọ so fún ẹnikẹ́ni o, Ìjàpá se ìlérí wípé ẹnikẹ́ni kò ní gbọ́ lẹ́nu òun, àtíòro ni kó máa lọ sí ilé, ko ji wa lòwúrò kùtùkùtù owurọ ọjọ kejì.[2]

Ìjàpá ji lọ si ilé àtíòro ni kùtùkùtù òwúrò, àtíòro ni o ti ya Ìjàpá ju, pe bi awon oloko ẹmu ba ti lọ si oko ẹmu ki o padà wa, Ìjàpá sa pamọ si ibikan, ìgbà to se díẹ̀ o pada kan ilẹ̀kùn àtíòro pe awon olọkọ ti lo si ọkọ ẹmu, àtíòro ni awu ile ko tii mo bi àwọn ẹlẹkọ ba ti ń polówó ẹ̀kọ ki awon wa maa lo, Ìjàpá da lóhùn pe alaseju ni àtíòro, bi ènìyàn ba fe soore, ẹ̀ẹ̀kan lèèyàn ṣé, àtíòro da lóhùn pe ìwọ Ìjàpá yii wàhálà rẹ pọ! Kò burú múra láti fò pẹ̀lú mi, gẹ́gẹ́ bi a ti mọ̀ pé ẹiyẹ ni àtíòro, àtíòro gbé Ìjàpá sí àyà rẹ láti fò lọ sí ibi tí oúnjẹ wá.

ìrìn àjò náà gbà wọn ní ọjọ́ pupọ.

Èkọ́ inú Ààlọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Ààlọ́ yìí kò wá pé ká má ja olè, ká má jẹ alainitelorun, òpùró, ati aláìmoore.
  2. Olójú kòkòrò ko le ni igbeyin rere nítorí ìgbẹ̀yìn rẹ burú jàì.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. https://yorubafolktales.wordpress.com/
  2. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales