Ilé-ìwé sekondiri

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ilé-Èkó Girama

Ilé-ẹ̀kọ́ girama jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ ọlọ́dún mẹ́fà tí ó kàn lẹ́yìn ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.[1]. Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ilé-ẹ̀kọ́ girama ti ọ̀jẹ̀-wẹ́wẹ́ ọlọ́dún mẹ́ta akọ́kọ́ (junior secondary), nígbà tí ìkejì jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama ti àgbà ọlọ́dún mẹ́ta (senior secondary). [2]. Lẹ́yìn ìpele ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ yí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yí yóò ní ànfaní láti kọ ìdánwò àṣekágbá tí a ń pè ní (Junior Waec) kí wọ́n lè yege láti wọ ilé-ẹ̀kọ́ ìpele girama ti àgbà. [3], lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ẹ̀kọ́ ti ìpele àgbà yí, wọn yóò tún ṣe ìdánwò àṣekágbá níbi tí wọn yóò ti kópa nínú ìdánwò tí àjọ WAEC gbé kalẹ̀ fún wọn. Wọ́n tún lè ṣe Neco, NABTEB kí wọ́n lé wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ fáfitì tàbí àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀. [4]

Àwon Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "» Nigerian Educational System". 2016-04-20. Retrieved 2022-03-03. 
  2. "Nigeria Education System". Scholaro. Retrieved 2022-03-03. 
  3. "Nigeria". StateUniversity.com. Retrieved 2022-03-03. 
  4. "higher education". Encyclopedia Britannica. 2016-03-03. Retrieved 2022-03-03.