Ilé-iṣẹ́ Senegal
Ilé-iṣẹ́ Senegal, tí kíkọ rẹ̀ ní èdè Faranse jẹ́ Compagnie du Sénégal jẹ́ ilé-iṣẹ́ sẹ́ńtútì kẹtàdínológún ti ìlú Faranse tó ń rí sí ìṣe àwọn agbègbè bí i Saint-Louis àti Gorée island tó jẹ́ apá kan ilẹ̀ Faranse ti Senegal.
Ilé-iṣẹ́ àkọ́kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ilé-iṣẹ́ náà gbilẹ̀ sí àwọn agbègbè kan ní French West India Company, ní ọdún 1672, ìyẹn lẹ́yìn ìwọgbèsè wọn àti fífagilé ìwé-àdéhùn rẹ̀ ní ọdún 1674. Sieur de Richemont sìn gẹ́gẹ́ bí i Gómínà agbègbè náà, láti ọdún 1672 wọ ọdún 1673, ti Jacques Fuméchon, sì jẹ́ olùdarí lẹ́yìn rẹ̀, tó sìn títí wọ ọdún1682. Compagnie royale d'Afrique àti Compagnie de Guinea gba ìṣàkóso ètò ọrọ̀-ajé ilé-iṣẹ́ náà.
Ilé-iṣẹ́ kejì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 1696, wọ́n ṣèdásílẹ̀ Compagnie royale du Sénégal, Jean Bourguignon sì jẹ́ alákòóso rẹ̀ láti oṣù kẹta ọdún 1696 wọ oṣù kẹrin ọdún 1697, léyìn náà ni André Brue gbàjọba, ó sì ṣàkóso títí wọ ọdún oṣù karùn-ún ọdún 1702. Wọ́n ṣe òwò ẹrú pẹ̀lú àwọn ará Hausa, ní Mali, àti Mauritania.
Ilé-iṣẹ́ kẹta
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 1709, wọ́n ṣèdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Compagnie du Sénégal, ẹlẹ́ẹ̀kẹta.