Ìlú Ìrèlè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ilu Irele)

Ilu Irele Akinyomade (2002), ‘Ìlú Ìrèlè’, láti inú ‘Ipa Obìnrin nínú Ọdún Èje ní Ìlú Ìrèlè.’, Àpilẹ̀kọ fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria, ojú-ìwe 3-12.

ÀPÈJÚWE ÌLÚ ÌRÈLÈ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Ìrèlè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì àti èyí tí ó tóbi jù nínú Ìkálẹ̀ Mẹ̀sàn-án (Ìrèlè, Àjàgbà, Ọ̀mi, Ìdèpé-Òkìtipupa, Aye, Ìkọ̀yà, Ìlú tuntun, Ijudò àti Ijùkè, Erínjẹ, Gbodìgò-Ìgbòdan Líṣà). Ìlú yìí wà ní ìlà-oòrùn gúṣù Yorùbá (SEY) gẹ́gẹ́ bí ìpínsí-ìsọ̀rí Oyelaran (1967), Ó sì jẹ ibìjókòó ìjọba ìbílẹ̀ Ìrèlè. Ìlú yìí jẹ́ ọkan lára àwọn ìlú tí ó ti wà ní ìgbà láéláé, àwọn olùgbé ìlú yìí yòó máa súnmọ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbàá. Ní apá ìlà-oòrun, wọ́n bá ilú Sàbọmì àti Igbotu pààlà, ní apá ìwọ̀-oòrùn ìlú Ọ̀rẹ̀ àti Odìgbó pààlà, ní àriwá tí wọ́n sì ba ìlú Okìtìpupa-Ìdèpé àti Ìgbòbíní pààlà nígbà tí gusu wọ́n bá ìlú Ọ̀mì pààlà. Ìrèlè jẹ́ ìlú tí a tẹ̀dó sórí yanrìn, tí òjò sì máa ń rọ̀ ní àkókò rẹ̀ dáradára. Eléyìí ni ó jẹ́ kì àwọn olùgbé inú ìlú yìí yan iṣẹ́ àgbẹ̀ àti iṣẹ́ ẹja pípa ní àyò gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òòjọ́ wọ́n ṣé wọ́n ní oko lèrè àgbẹ̀. Ohun tí wọ́n sábà máa ń gbìn ni ọ̀pẹ, obì tí ó lè máa mú owó wọlé fún wọn. Wọ́n tún máa ń gbin iṣu, ẹ̀gẹ́ kókò, kúkúǹdùkú àti ewébẹ̀ sínú oko àrojẹ wọn. Nígbà tí ó dip é ilẹ̀ wọn kò tó, tí ó sì tún ń ṣá, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i, àwọn mìíràn fi ìlú sílẹ̀ láti lọ mú oko ní ìlú mìíràn. Ìdí èyí ló fi jẹ́ pé àwọn ará ìlú yìí fi fi oko ṣe ilé ju ìlú wọn lọ. Lára oko wọn yìí ni a ti ri Kìdímọ̀, Lítòtó, Líkànran, Òfò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀làjú dé, àwọn ará ìlú yìí kò fi iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ẹja pípa nìkan ṣe iṣẹ́ mọ́, àwọn náà ti ń ṣe iṣẹ́ ayàwòrán, télọ̀, bíríkìlà, awakọ̀, wọ́n sì ń dá iṣẹ́ sílẹ̀. Wọ́n ní ọjọ́ tí wọ́n máa ń kó èrè oko wọn lọ láti tà bíi ọjà Arárọ̀mí, Ọjà Ọba, àti Ọjà Kónyè tí wọ́n máa ń kó èrè oko wọn lọ láti tà bíi ọjà Arárọ̀mí, Ọjà Ọba, àti Ọjà Kóyè tí wọn máa ń ná ní ọrọọrín sira wọn. Àwọn olùsìn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ pọ̀ ni Ìrèlè. Wọ́n máa ń bọ odò, Ayélála, Arẹdẹ-lẹ́rọ̀n bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n máa ń ṣe ọdún egúngún, Ṣàngó, Ògún, Ọrẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀sìn àjòjì dé wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ń yi padà lati inú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wọ́n sí ẹ̀sìn mùsùmùmí àti ẹ̀sìn kirisitẹni. Bí ojú ṣe ń là si náà ni ìdàgbàsókè ń bá ìlú yìí. Oríṣìíríṣìí ohun amúlúdùn ni ó wà ní ìlú Ìrèlè, bíi iná mọ̀nà-mọ́ná, omi-ẹ̀rọ, ọ̀dà oju popo, ile ìfowópamọ́, ilé ìfiwé-ránṣẹ́, ilé-ìwé gígá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

ÌTÀN ÌLÙ ÌRÈLÈ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìrèlè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ilẹ̀ Yorùbá tí m bẹ ni ìha “Òǹdó Province” ó sì tún jẹ́ ọ̀kan kókó nínú àwọn ilẹ̀ mẹ́ta pàtàkì tí ń bẹ ni “Ọ̀kìtìpupa Division” tàbí tí a tún ń pè ní ìdàkeji gẹ́gẹ́ Ẹsẹ̀ Odò tí ọwọ́ òwúrò ilẹ̀ Yorùbá. Ìwádìí fí yé wa wí pé ọmọ ọba Benin tó jọba sí ìlú Ugbò1 tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ Olúgbò-amẹ̀tọ́2 bí Gbáǹgbá àti Àjànà. Gbáǹgbá jẹ́ àbúrò Àjànà ṣùgbọ́n nígbà tí Olúgbò-amẹ̀tọ́ wàjà, àwọn afọbajẹ gbìmọ̀pọ̀ lati fi Gbáǹgbà jẹ ọba èyí mú kí Àjànà bínú kuro ní ìlú, ó sì lọ tẹ ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́3 pẹ̀lú Gbógùnrọ́n arakunrin rẹ̀. Láti ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́ ní Àjànà tí lọ sí ìlú Benin, ò sí rojọ́ fún Ọba Uforami4 bí wọ́n ṣe fí àbúrò oùn jọba, àti pé bí oùn náà ṣe tẹ ibikan dó. Oùn yóò sì jẹ Ọba “Olú Orófun”5 sí ìbẹ. Ọba Uforami sì fún Àjànà ní adé, Àjànà padà sí Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, ó bí Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún àti Ògèyìnbó, ọkùnrin sì ni àwọn mejeeji. Kò pẹ́, kò sí jìnà, Àjànà wàjà. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji lọ si Benin lati jọba. Ògèyìnbó lọ sí Benin lati jọba. Ó dúró sí ọ̀dọ̀ Oba Benin pé baba òun tí wàjà, òun yóò sí jọba. Ọ̀rúnbẹ̀mékún náà lọ sí ọ̀dọ̀ Ìyá Ọba Benin pé òun náà fẹ jọba nígbà tí baba òun ti kú. Ọba Benin ń ṣe orò ọba fún Ògèyìnbó nígba tí Ìyá ọba ń ṣe orò fún Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún. Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún mu Olóbímítán ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí akọ́dà Ọba Benin tí yóò wà gbé oúnjẹ fún Ìyá Ọba, rí í wí pé ọrọ̀ tí ọba ń ṣe fún alejo ọdọ̀ rẹ̀ náà ní Ìyá ọba ń ṣe fún ẹni yìí. Èyí mú kí akọ́dá ọba fi ọ̀rọ̀ náà tó kabiyesi létí. Ní ọba ni ọmọ kì í bí ṣáájú iyaa rẹ, ó pe Ògèyìnbò kó wá máa lọ. Nígbà tí àwọn méjèéjì fí lọ sí Benin, Gbógùnrọ̀n tí gbe “Àgbá Malokun”6 pamọ́ nítorí ó tí fura pé wọn kò ní ba inú dídùn wá. Ògèyìnbó dé Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, kò rí Àgbá Malòkun mọ́, ó wa gbé Ùfùrà, ó wọ inú ọkọ ojú omi, o sí tẹ isalẹ̀ omi lọ, oùn ní ó tẹ ìlú Erínjẹ dó. Ní àkókò tí Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún fí wà ní ìlú Benin, Òlóbímitán, ọmọ rẹ̀ máa lọ wẹ̀ lódò Ìpòba7 àwọn ẹrú ọba sí màa ń ja lati fẹ èyí ló fá ìpèdè yìí “Olóbímitán máa lọ wẹ̀ lódì kí ẹru ọba meji máa ba jìjà ku tori ẹ”. Èyí ní wọ́n fi ń ṣe ọdún Ìjègbé ní ìlú Benin. Ní ìgbà tí ó ṣe Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún àti Olóbímitán padà sí ìlú Ìgbẹ́kẹ̀bọ́, ṣùgbọ́n Gbógùnrọ̀n sọ fún wí pe àbúrò rẹ̀ (Ògèyìnbó) i ba ibi jẹ́ kò sì dára fún wọn lati gbé, wọ́n kọja sí òkè omi wọn fi de Ọ̀tún Ugbotu8, wọn sọkalẹ, Olóbímitán ní òun…àbàtà wọ́n wá tẹ́ igi tẹ́ẹ́rẹ́ lorí rẹ̀ fún, èyí ní wọn fí ń kí oríkì wọn báyìí: “Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún a hénà gòkè” . Àgbá Malòkun tí gbógùnrọ̀n gbé pa mọ́ kò le wọ inú ọkọ́ ojú omi, wọn sọ ọ́ sínú omi, títí dì òní yìí tí wọ́n bá ti ń sọdún Malòkun ní ìlú Ìrèlè, a máa ń gbọ́ ìró ìlù náà ní ọ̀gangan ibi wọ́n gbé sọ ọ́ somi. Wọ́n tẹ̀dó sí odó Ohúmọ. Oríṣìíríṣìí ogun ló jà wọ́n ní odí Ohúmọ, lára wọn ní Ogun Osòkòlò10, Ogun Ùjọ́11, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Olumisokun ọmọ ọba Benin, ìyàwò rẹ̀ kò bímọ nígbà tó dé Ìrèlè ó pa àgọ́ sí ibikan, ibẹ̀ ní wọn tí ń bọ Malokun ni ìlú Ìrèlè. Lúmúrè wá dò ní ìlú Ìrèlè, ó fẹ Olóbímitán ṣùgbọ́n Olóbímitán kò bímọ fún un èyí mú kí ó pàdà wa si ọdọ baba rẹ̀, Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún, olúmísokùn wá fẹ Olóbímitán ní odó Ohúmọ. Wọ́n bí Jagbójú àti Oyènúsì, ogun tó jà wọn ní ní odó Ohúmọ pa Oyènúsì èyí mú kí Jagbójú sọ pé “oun relé baba mi”. Mo relé. Bí orúkọ àwọn to kọ́kọ́ jọba ni ìlú Ìrèlè ṣe tẹ̀lé ara wọn nì yìí:

  • Ọ̀rúnbẹ̀mẹ́kún
  • Jagbójú
  • Yàbọ́yìn
  • Akingboyè
  • Ọ̀gàbaléténi
  • Méṣèénù
  • Olómúwàgún
  • Adépẹ̀yìn
  • Adétubọkánwà
  • Feyísarà
  • Ọlarewaju Lẹ́bí

Odú Ifá tó tẹ Ìrèlè dó[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

"Ègúntán Ọ̀bàrà

Ègùntán á ṣẹ

Ọ̀bàrà á ṣẹ

A díá fún Ìyá túrèké

Wọ́n ni kó lọ ra ewurẹ́ wá lọ́jà

Owó ẹyọ kan ní wọn fún

Ègùntán ní ìyá òun yóò ra ewúrẹ́ méjì

Ọ̀bàrà ni ìyà òun yóò ra ewúrẹ́ kan

Túrèké ra ewúrẹ́ kan

Ṣùgbọ́n ó lóyún

Kí ó tó délé ewúrẹ́ bí mọ" .

ORÍKÌ ÌLÚ ÌRÈLÈ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

" Ìrèlè ẹgùn,

Ibi owó ń gbé so,

Tí a rí nǹkan fi kan

Ìrèlè ẹgùn,

Ó gbẹ́ja ńlá bọfá,

Èṣù gbagada ojú ọ̀run

Ó jókòó ṣòwò ọlà

Malòkun ò gbólú

Ọba-mi-jọ̀ba òkè.

Àtètè-Olókun

Iwá òkun, òkun ni

Ẹ̀yìn òkun, òkun ni

A kì í rídìí òkun

A kìí rídìí Ọlọ́sà

Ọmọ Ìrèlè kò ní opin

Ìdí ìgbálẹ̀ kì í ṣẹ́

Aṣọ funfun tí Malòkun

Ọpẹ ni ti Malòkun" .

Àwọn nǹkan èèwọ̀ fún ọmọ bíbí ìlú Ìrèlè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Ẹran òkété
  • Ẹ̀rọ́ kókò
  • Ẹran Ajá
  • Ẹ̀kọn

ÌTỌSẸ̀ Ọ̀RỌ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1 Ugbò = Orúkọ ìlú kan ní ìlú Ìlàjẹ ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.

2 Olúgbò-amẹ́tọ̀ = Orukọ ọba ìlú Ugbò nígbà náà.

3 Gbáǹgbà àti Àjànà = Orukọ ènìyàn.

4 Ìgbẹ́kẹ̀bọ́ = ìlú kan ní jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìpílẹ̀ Ìlàjẹ

5 Ọba Ùfóràmí = Orúkọ Ọba Benin.

6 Olú Orófun = Orúkọ oyé ọba ìlú Ìrèlè.

7 Àgbá Malòkun = Orúkọ ìlù kan ni tí wọ́n ń lù ní ọjọ́ ọdún Malòkun.

8 Ìpòbà = Orúkọ omi kan ní ìlú Benin

9 Ugbotu = Orukọ ìlú àwọn Ìlàjẹ kan ni.

10 Ohúmọ = Orúkọ omi kan ni.

11 Ogun Òsòkòlò = Orúkọ ìlú kan tó kó ogun ja ìlú Ìrèlè.

12 Ùjọ́ = Orúkọ àwọn ẹ̀ya ènìyàn kan ni

Awon Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]