Ingrid Andersen
Ingrid Andersen (tí wọ́n bí ní ọdún 1965) jé akéwì ti orílẹ̀-èdè South African.
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìlú Johannesburg ni Andersen gbé jù, ó sì ń ṣiṣé ní Grahamstown ní Eastern Cape fún ọdún márùn-ún kí ó tó kó lọ sí KwaZulu-Natal Midlands ní ọdún 2007.
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i apolongo orí-ìtàgé láti ọdún 1980, lásìkò fífí ìfẹ̀hónú fún ìṣẹ̀lú, orí-ìtàgé ti ọjà àti PACT. Bí South Africa ṣe ń ṣètò ìdìbò olómìnira àkọ́kọ́, Andersen kópa nínú ètò ìdàgbàsókè ìlú, gẹ́gé bí i olùásílẹ̀ Rosebank Homeless Association àti alámòójútó Community Engagement ní Rhodes University. Ó ṣiṣẹ́ ní University of KwaZulu Natal ní ẹ̀ka ṣíṣe alágbàwí fún ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn, ìwòsàn àti ìlàjà, ó sì ṣíjú sí Alternatives to Violence Project.
Àwọn ewì rè àkọ́kọ́ ni, Excision, tí ó gbé jáde ní National Arts Festival ní ọdún 2005. Wọ́n ṣe àtúnwò ìwé yìí ní Wordstock, nínú ìwé-ìròyìn Arts Festival WordFest, gẹ́gẹ́ bí i "èyí tí a ṣe dáradára, tó lọ tààrà...Andersen lo gègé rẹ̀ dáadáa bí i òǹkọ̀wé alátinúdá" (Warren 2005).[1]
Láàárín ọdún márùndínlógún séyìn, South African literary journals ti ṣàfihàn àwọn ewì rẹ̀ bí i Imprint, Green Dragon, Aerial, Slugnews, Carapace àti New Coin. Ó ṣe àgbéjáde iṣẹ́ rẹ̀ ní WordFest ní ọdún 2004 àti 2005. Bákan náà ní Hilton Arts Festival ní ọdún 2009. Ó ṣe ìrántí olùdámọ̀ràn rẹ̀, ìyẹn Lionel Abrahams, ní ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1990. Piecework, ni àkọ́lé ewì rè kejì, èyí tí Modjaji Books ṣàtẹ̀jáde, ní ọdún 2010.
Andersen ni olóòtú Incwadi, tó jẹ́ ìwé àkọsílẹ̀ àwọn ewì àti àwòràn ilẹ̀ South African ti orí ayélujára.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Andersen, Ingrid (2004) (in en). Excision. Ingrid Andersen. ISBN 978-0-86810-411-9. https://books.google.com/books?id=uNzyAAAAMAAJ&q=Her+debut+poetry+collection,+Excision,+was+launched+at+the+National+Arts+Festival+in+2005.+It+was+reviewed+in+Wordstock,+the+Arts+Festival+WordFest+newspaper,+as+%22well-crafted,+controlled+and+concise...a+strong+debut+collection+containing+sensitive+and+poignant+sketches...Andersen+wields+her+pen+with+surgical+precision%22+(Warren+2005.
- LitNet: 20 December 2005: Michelle McGrane in conversation with Ingrid Andersen
- "Four powerful new EC poets". Saturday Dispatch 2 July 2005. p. 14
- Warren, Crystal. "Out into the world" Wordstock, 7 July 2005. p 2