Jump to content

Ìrìnàjò lọ sínú Òṣùpá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Irinajo lo sinu Osupa)

ÌDÒWÚ OLUWASEUN ADẸ́SAYỌ̀

ÌRÌNÀJÒ LỌ SÍNÚ ÒṢÙPÁ

Osupa

Aye mẹ́jọ míràn bíi’rú ti wa lo n yi po káàkiri òòrùn. Àwa la ṣìkẹta táa jìnà sóòrùn, awọn méjì wà níwájú. Àwọn mẹ́fà wà lẹ́yìn wa. Mo ni òòrùn tí à ń wò lókè taa rò pé ó kéré mo ló tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ju gbogbo ilé ayé lọ báyé yìí ṣẹ́ ń yípo òòrùn, bẹ́ẹ̀ náà lòsùpá ń yípó ayé Mo tún sọ fún wa wípé jínjìn ilé ayé sí òṣùpá tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ọ̀rún mẹta, ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún kìlómítà 320, 000 kin. Bíi kéèyàn ó máa rin Èkó sí Ìbàdàn bíi ọ̀nà ẹgbẹ̀rún méjì bẹ́ẹ̀ náà lòṣùpá ṣe jìn sílé ayé tó téèyàn bá kúrò lórí ilẹ̀ ayé àlàfo tí ń bẹ láàrin Ilé-ayé àti òṣùpá, láàrin ilé ayé àti òòrùn láàrin ilé-ayé àti àwọn ayé mẹ́jọ tó kù lèèyàn ó kàn o, téèyàn bá ń fò lọ sókè sínú òfurufú àlàfo yìí làwọn olóyìnbó ń pè ní space ṣee mọ̀ pé bí ìgbà téèyàn bá to ǹkan ka lẹ̀ tálàfo wá wà níbẹ̀, bí Olódùmarè ṣe tàlàfo sáàrin ilé ayé àtàwọn ayé tókù, àtòòrìn àtòṣùpá rèé. Àlàfo tí à ń sọ yìí, bíi ojú sánmọ̀, ojú òfurufú ló ṣe rí ṣùgbọ́n ǹkan tí ó fi yàtọ̀ díẹ̀ ni pé kò sí atẹ́gùn nínú àlàfo yìí, kò sí kùrukùru òfuru jágédo lásán ni.

Àjá ni wọ́n kọ́kọ́ rán sínú àlàfo tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí lọ́dún 1957 Làíkà lórúkọ tájá yìn ń jẹ́, nigba tájá yi padà tí ò kú ní wọ́n bá rán ẹnìkan ta n pe ni Yuri Gagarin lọ sínu àlàfo yìí, láti orílẹ̀èdè Russia láti mọ̀ bálàfo yì sẹ rí Yuri Gagarin lẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ fò kúrò lórí ilẹ̀-àyé pátápátá lọ sinu àlàfo ta n pe ni space to wà láàrin Ilé ayé àtòṣùpá.

Lẹ́yìn èyí orílẹ̀ èdè America náà bẹ̀rẹ̀ sí ní rìnrìnàjò yii Ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín orílẹ̀èdè America lọ́ sínú òṣùpá lọ́dún 1969 Neil Armstrong ati Edwin Aldrin si lẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ wọnú ọ̀sùpá. Mo sọ fun wa wipe òǹfà kan nbẹ́ ninú ilé ayé tó má n fa gbobgo ǹkan tó bá ti wà lórí ilé-ayé tàbí súnmọ́ ilé ayé mọ́ra,

Téèyàn á bá wá kúrò lórí ilẹ̀-ayé pátápátá èàyàn gbọdọ̀ jára rẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ òǹfà yìí, mọ́to téèyàn á bá lọ ó gbọ́dọ́ lágbára gidi kò sì tún lè sáré láti bori agbára ̣ òǹfà yìí, tóò ọkọ̀ tí wọ́n gbé lọ inú òṣùpá, Rọ́kẹ́ẹ̀tì ló ń jẹ́ o, Aeroplane, ò lè rin irú ìrìnàjò yí o, e wòó iṣẹ́ ọpọlọ ni wọ́n fi se rọ́rẹ́ẹ̀tì yìí, Ìpéle mẹ́ta ni wọ́n ṣe éńjínnì mọ́to yí o, Ìpéle kínní, ìpéle kejì, ìpóle kẹta lọ sókè ibi tí àwọn èèyàn dúró sí núnú rẹ̀, ó wà lórí ìpéle kẹta lókè téńté bí wọ́n ṣe to àwọn éńjìnnì yìí bíi àgbá rìbìtì léra wọn rèé tó dúró lóòró tó wá kọjú da sánmọ̀ wọ́n tún wá jẹ́ ki ọkọ yìí ṣẹnu ṣómu ṣómú ko le máa wọnú atẹ́gùn lọ sọ̀ọ̀, Orúkọ tí wọ́n fún rọ́kẹ́ẹ̀tì yìí ni wọn n pè ni Apollo 11, Apollo 11 yìí ga lọ sókè ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà ọgọ́run mẹ́ta Ààbọ̀ ó lé díẹ̀, bíi ká sọ pé ilé alája ogóji epo tí ọkọ yìí ń jẹ kèrémí kọ́ o. Kò ṣéé fẹnu sọ.

Bíi ìgbà tèèyàn bá yin ọta ìbọn, bi wọ́ń ṣé, má n yìn-ín nuu torí ó gbọdọ̀ le sáré dáadáa kío le jára rẹ̀ gbà kúro lọ́wọ́ ̣ òǹfà tí ń bẹ lórí ilẹ̀ aye, tí wọn á bá si yin mọ́to yìí kìí séèyàn kankan ní sàkání ibẹ̀, torí ooru, èéfín àti iná nló má ń jáde ní ìdí Rọ́kẹ̀ẹ̀tì yìí.

Àwọn tó lọ inú òṣùpá, ti wọ́n wà nínú mọ́to yìí. wọ́n dera wọn mọ́ àgá ni Àwọn tó yin rọ́kéẹ̀tí yìí sókè, wọ́n jìnnà pátápátá sí ibi tí Rọ́kẹ̀tì yìí wà, ẹ̀rọ̀ kọ̀mpútà ni wọ́n fí yìn ín bi wọ́n sẹ gbéná lé Rókẹ́ẹ̀tí yìí tí à ń pè ní Apollo 11 ni 1969 dó bá dún gbòà? lọkọ̀ bá ṣí, Ó dòkè lójú sán mọ̀ Eré burúkú kí ọkọ̀ máa sáré ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá kìlómítà láàrín wákàtí kan. 10,000km/hr irú eré tí àwọn móto má ń sá lọ́nà ẹ́spùrẹ̀sì irú eré yìí lọ́nà ẹgbẹ̀rún kan leré tí rọ́kẹ́ẹ̀tì yìí bá lọ sínú òfurufú lọhun. Láàrin ìṣẹ́jú méjì ààbọ, éńjìnnì tìpéle àkọ́kọ́ ti gbé ọkọ̀ yìí rin kìlómità ọgọrun mẹ́fà 600km. lọ sínú òfunrufú.

Lẹ́yìn iṣẹ́jú méjì ààbọ̀ éńjìnnì tó wà ní ìpéle àkọ́kọ́ ti jó tán ó jábọ́ kúrò lára ọkọ̀ yìí, éńjìnnì tì péle kejì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ó sì gbé wọn rin ẹgbẹ̀rún méji, ó lé ni ọgọrun mẹta kìlómítà 2,300 kilometres láàrin ìṣẹ́jú mẹ́fà lọ́ sí nú òfururú lọ́ùnlọ́ùn, ẹńjìnnì ìpéle kejì jó tán òhun náà jábọ́, tipéle kẹta bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ẹ́njìnnì tìpéle kẹta ló wá jáwọn gbà kúrò lọ́wọ́ òǹfà tí ń bẹ nínú ayé pátápátá, wọ́n sì bọ́ sínú àlàfo tí ń bẹ láàrin ilé-ayé àtoṣùpá. Nínú àlàfo yìí, ̣ òǹfà ayé ò ní pa púpọ̀ mọ́ lórí wọn Wọ́n wá sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ni rìnrìnàjò wọn lọ́ sínú òṣùpá ní ìrowọ́ ìrọsẹ̀. Nínú àlàfo tí a ńpè ní space yìí, béèyàn bá ju ̣ ǹkan ókè kìí padà wá lẹ̀ yíó dúró pa sókè ni, kó dà gan béèyàn gan fò sókè èèyàn ò ní tètè padà wálẹ̀ tórí kò sí ̣ òǹfà kan tí ó fààyàn padà nínú àlàfo yìí ṣùgbọ́n béèyàn bá dẹ́nú òṣùpá, ̣ òǹfà ń bẹ nínú òṣúpá ṣùgbọ́n àmẹ́ kò tó tayé béèyàn bá ju ǹkan sókè nínú òṣùpá naa kìí tètè padà walẹ, ẹ má gbàgbé àti nínú àfìfo tí ń bẹ láàrin ilé-ayé àtọ̀ṣùpá àti nínú òṣùpa gan-an kò sí atẹ́gùn níbẹ̀ o báwo wá làwọn tí wọ́n ń lọ inú òṣùpá ṣé má ń mí, wọ́n má ń gbé atẹ́gùn pamọ́ sínú àpò kan ni, kí wọn o le rátẹ́gùn fi mí. Tòò wọ́n dénú òṣùpá lógúnjọ́ oṣù kẹfà lọ́dún 1969 lọ́jọ̀ Sunday ọjọ ìsinmi ló bọ́ sí ẹ̀yin tẹ́ẹbá ní kàlẹ́ńdà 1969 lọ́wọ́ ẹ wòó ọjọ́ márùn-ún ni wọ́n fi rin ìrìn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrun mẹ́ta , ó lé ní ọgọrun lọ́nà ogún kìlómítà 320,000km lọ sí nú òṣùpá, Neil Armstrong lórukọ fẹẹ̀ ẹní tó kọkọ fi ẹsẹ tẹnú òṣùpá bó sẹ́ ń sòkalẹ̀ láti inú ọkọ̀ tí wọ́n gbé lọ óní bí ó ti lẹ̀ jẹ́pé ìgbéṣẹ̀ ti òhun gbé wọnú òṣùpá ó kéré óní ìgbésẹ̀ ńlá ni fún ìran ọmọ ènìyàn. Edwin Aldrin tí wọ́n dìjọ lọ náà sọ̀kalẹ̀ sínú òṣùpá wọ́n bá ààrẹ oríléèdè Amerika Nígbànáà ààrẹ Richard Nixon sọ̀rọ̀ pé tò àwọn tí dé nú òṣùpá o. Àwọn méjéèjì bẹ̀rẹ̀ ìwádí ti wọ́n bá lọ sínú òṣùpá wọ́n fìdíẹ̀ múlẹ̀ pé erùpè, òkúta àtàwọn òkè ń bẹ nínú òṣùpá ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀dá alàyè tàbí ohun abẹ̀mí kan níbẹ̀.

Inu òṣùpa tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ọjọ́ méjì ti è oṣù kan ti wa ni ọ̀ sẹ̀ méjì gbáko lòòrùn á fi ràn. Tí gbogbo ǹkan á sì gbóná lọ́nà méjì ju omi tó ń hó lọ, ọ̀sẹ̀ méjì ni lẹ̀ tún fí má ń ṣú, gbogbo ǹkan á tún tutu lọ́nà méjì ju ice block yìnyín lọ.

Àsìkò ìgbà tóòrùn ń ràn ni wọ́n dé bẹ̀ àmọ́ aṣọ tiwọ́n wọ̀ dábòbò wọn tóoru ò fi mú wọn pa torí wọ́n dọ́gbọ́n éńjìnnì amára tutu sínú aṣọ yìí, àwọn méjéèjì lo wákàtí méjì àtìṣẹ́jú mẹ́ta dínláàádọ́ta nínú òṣùpá wọ́n ṣàwọn ìwáàdí kéèkèè ké wọ́n ri àsìá orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà síbẹ̀, wọ́n bu yèèpè inú òṣùpá àtòkúta díẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì padà, tòò àti lọ sínú òṣùpá ló le àti kúrò níbẹ̀ ò le, wọn yin ra wọn kúrò níbẹ̀ ni bi wọ́n ṣe yin ra wọn kúrò lórí ìlẹ̀ aye.

Ọjọ́ méjì ààbò ni wọ́n fi rìn padà sórílẹ̀ ayé bi wọ́n tún ṣe súnmọ́ ilé-ayẹ́ lòǹfà inú ayé bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ní fàwọ́n, eré ni awọ́n si n bá bo láti inú òṣùpá tẹ́lè leré yìí bá tún pọ̀ si, báwo lọkọ̀ se fẹ́ bà sórí ilẹ̀ pẹ̀lú eré burúkú yìí íápọọ̀tì òtì wo ló fẹ́ bà sí wọ́n sá ṣètò kí mọ́tò yí balẹ̀ sínú òkun alagbalúgbú omi ṣẹẹ mọ̀ pé okún jìn lọ ìsàlẹ̀, omi inú òkun tún dá mọ́tò yìí dúró bíi búrèkì, tòò bi wọ́n se lọ sínú òṣùpá rèé o. Lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 1969 16-7-1969 tí wọ́n sì padà sórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kẹrìnlélógún, oṣù keje kannáà lọ́dún 1969, 24-7-1969.