Iru

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Iru ni ohun ti a mọ si locust beans ni ede gẹẹsi. Iru jẹ eronja ọbẹ ni ilẹ Yoruba ati ni agbegbe miran. A maa nfi iru si ọbẹ lati fi jẹ ki oni adun ati orun daadaa. Awọn ọbẹ ti a le fi iru si ni ọbẹ ila, ọbẹ ewedu, ọbẹ ẹfọ, ọbẹ ata, ọbẹ egusi, ọbẹ ọgbọnọ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Iru ni ilẹ Yoruba pin si oriṣi meji, iru woro ati iru pẹtẹ. Iyaatọ laarin mejeeji ko pọ. Iru pẹtẹ rọ, o si maa nfọ sinu ọbẹ. Sugbọn iru woro maa nduro sinu ọbẹ nitori pe ole. Iru jẹ eronja ọbẹ to ṣara lore.[1] Awọn ọmọ ilẹ Yoruba ni igbagbọ pe iru ni anfaani ti on ṣe fun oju lọpọlọpọ. Nitori eyi, wa maa sọ fun ẹni ti oju dun ki o ma jẹ iru daadaa. Akiyesi iru ni pe o gbọdọ kun fun iyọ ki o ba le pẹ nilẹ.

Awọn Itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Odumade, Omotolani (2018-04-13). "Health benefits of Iru". Pulse.ng. Retrieved 2018-10-15.