Isoken Ogiemwonyi
Isoken Ogiemwonyi tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ olùdarí The Obsidian Way àti oníṣòwò tó dá Zazaii sílẹ̀. Ó máa ń rán aṣọ ó sì tún máa ń pèsè àwòrán fún aṣọ rírán lóríṣiríṣi.[1]
Ètò-èkó àti iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]University of Nottingham ni Ogiemwonyi lọ ti ó sì gboyè (LLB Law Hons.) ní Law. Ó sì tún ṣe Post graduate studies ní Hospitality àti Masters degree nínú Management. Àmọ́ Ogiemwonyi pa ìwé-ẹ̀rí rẹ̀ tì láti máa ránṣọ.[2] Ogiemwonyi olùdásílẹ̀-kejì ti Winterfell Ltd, tí ó ni Le Petit Marché Nigeria àti L’Espace trademarks. Ogiemwonyi àti Wonuola Odunsi ló jẹ́ alágbàátẹrù Le Petit Marché (LPM). Ní ọdún 2012, ó kópa nínú MTN Lagos Fashion & Design Week/British Council, orúkọ ìdánimọ̀ rẹ̀ fún ayẹyẹ náà ni Obsidian.[3] Ó sì yege gẹ́gẹ́ bíi Young Creative Entrepreneur of the Year. Ní ọdún 2013, ó kópa nínú Pitti Immagine Trade show ní ìlú Florence lórílẹ̀-èdè Italy.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Your favorite newspapers and magazines.". PressReader.com. 2017-09-10. Retrieved 2020-04-30.
- ↑ "BN Making It!: From Side Hustle to Big Business – Isoken Ogiemwonyi & Wonuola Odunsi of Le Petit Marché & L’Espace". BellaNaija. 2011-12-08. Retrieved 2020-04-30.
- ↑ "Designer Biography – Isoken Ogiemwonyi For Obsidian". OnoBello.com. Archived from the original on 2022-02-22. Retrieved 2020-04-30.
- ↑ "Isoken Ogiemwonyi: Combining Being a Creative Director with Running a Business". For Creative Girls. 2016-05-12. Retrieved 2020-04-30.