Iyàrá Ìdáná

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Olùdáná nínú ilé ìdánál

Iyàra ìdáná jẹ́ ibi tí a tí n pèlò tí a sì ti n dáná (se) oúnjẹ.[1]

Yàra ìdáná jẹ́ ibìkan tí ayàsọ́tọ̀ nínú ilé ìgbé fun iṣé oúnjẹ sísè lóríṣíríṣi. [2]Yàra ìdáná jẹ́ ibi tí a tí n pèlò tí a sì ti n dáná (se) oúnjẹ. Nítorí áwọn ohun èlò ìdána tí ó póríṣíríṣi tí an ṣe àmúlò àti pẹ̀lú onírurú ènìyàn tí o ń wọ iyàrá ìdáná mú kí ó jẹ́ ibi tí ó léwu. Láti ìgbà púpọ̀ sẹ́hìn ni yàrá ìdáná ti jẹ́ ibi ti àwọn ẹbí ti n darapọ̀ ṣe ọ̀yàyà.

Láti ìgbà púpọ̀ sẹ́hìn ni àwọn ènìyàn ti mọ rírì àti máa ṣe àyípadà àwon nkan àmúlò, tàbí ilé ìdáná gan fún ra rẹ̀ ní mímọ pàtàkì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ti àwọn yàrá tókù ní ìrísí tí yio mù rọrùn lati ṣe àmúlò bí ó ti yẹ.

Ṣíṣe ágbéyẹ̀wò yàrá ìdáná ìgbálódé jẹ́ ohun tí o n gbajú-gbajà si ní ojoojújmọ́, sùgbón o ṣe pàtàkì kí a ni lọ́kan láti ṣe ní ọ̀nà tí yoo fi mú kí iṣẹ́ ìdáná rọrùn ju ìgbà àtijọ́ lọ. 

Ṣíṣe idanilẹkọ bí a ti ṣe nlo àwọn ohnu èlò ilé ìdáná àti ilé ìdáná gan fúnrarẹ̀ yio jẹ́ kí iṣẹ́ ilé ìdáná wúni lórí, àtipé, àdìnkù yio bá ìjàmbá tí ó ṣééṣe kí ó ṣẹlẹ̀ nínú ilé ìdáná.


Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Kitchen". Designing Buildings. 2019-11-05. Retrieved 2023-04-13. 
  2. Charytonowicz, Jerzy; Latala, Dzoana (2011). "Evolution of Domestic Kitchen". Lecture Notes in Computer Science. Berlin, Heidelberg: Springer Berlin Heidelberg. pp. 348–357. doi:10.1007/978-3-642-21666-4_38. ISBN 978-3-642-21665-7. ISSN 0302-9743.