Julia da Silva Cardoso
Ìrísí
Julia da Silva Cardoso (d. after 1840) tí a tún mọ̀ sí Mae Julia ati Na Julia ('Senhora Julia'), jẹ́ òyìnbó ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ oníṣòwò ẹrú nhara.[1]
Ọmọ orílẹ̀ èdè Portugal tí ó ń jẹ́ José da Silva Cardoso ti Cap Verde ni ó tọ́ ọ dàgbà, ó ṣe é ṣe kó jẹ́ ọmọ rẹ̀. Ó fẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Portugal kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joaquim Antonio de Matto (d. 1843). Ó kópa pàtàkì nínú okoòwò láàárín àwọn òyìnbó Portugal àti àwọn ọmọ Africa, pàápàá jùlọ nínú okoòwò ẹrú ṣíṣe. Bẹ́ẹ̀ náà o jẹ́ gbajúmò aṣojú àti agbódegbà nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú láàárín wọn. Ó jẹ́ àbúrò ìyá àti ẹni tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí ìyá fún Aurelia Correia.