Jump to content

Kí ni fíìmù?

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

FÍÌMÙ


Fíìmù jẹ́ ọ̀rọ̀ kàn tí a fi kó àwòràn papọ̀. A máa ń gbé fíìmù jáde nígbà tí a bá gbá àwòrán àwọn ènìyàn àti àwọn nǹkan sílẹ̀ pẹ̀lú kámẹ́rà, tàbí tí a bá ṣẹ̀dá àwòràn nǹkan nípa lílo àwọn irinṣẹ́ kòmpútà. A máa ń lo fíìmù láti ṣẹ̀fẹ̀, láti dá àwọn ènìyàn lára yá, gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ ńlá tí a fi ń kọ àwọn ará ìlú ní nǹkan tuntun. Àwòrán wúlò láti bá ènìyàn sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì. Àkọ́lé àwọn eré tí wọ́n máa ń gbé jáde nínú fíìmù máa ń ní ìtumọ̀, ó sì máa ń pe èrò sọ́kàn òǹwòran.

“Longman dictionary of contemporary English” (1995) túmọ̀ fíìmù gẹ́gẹ́ bíi:

A story that is told using sound and moving pictures, shown at a cinema or on television for entertainment…. To use a camera to record a story or real events so that it can be shown in the cinema or on television.

(Ìtàn tí a sọ pẹ̀lú ohùn àti àwòràn tí ó dúró sójú kan, tí a gbé síta fún wíwò ni sinimá tàbí lóríi tẹlifísàn fún ìdálárayá… tí a fi ẹ̀rọ agbàwòrán sílẹ̀ kámẹ́rà gba ìtàn tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé sílẹ̀ kí a bà á le gbé síta fún wíwò ní sinimá tàbí lórí tẹlifísàn.)

Ohun tí ó ṣe kókó ni wí pé ìtàn ni fíìmù máa ń sọ pẹ̀lú àwòràn àwọn ò̀ṣèré lóríṣìíríṣìí. Ẹ̀rọ kámérà ni wọ́n máa ń lò láti gba àwọn àwòrán yìí sílẹ̀.


Oríṣìíríṣìí fíìmù tó wà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oríṣìírìṣìí fíìmù ni ó wá. Àwọn tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìtàn ìwáṣẹ̀ tàbí àwon ìtàn akọni. Wọ́n máa ń pè wọ́n ní “epics/historical films”. Àpẹẹrẹ àwọn fíìmù àgbéléwò tí ó wà lábẹ́ ọ̀wọ́ yìí, tí wọ́n sì ti gbé jáde ni; Jógun-ó-mí, Odùduwà, Efúnsetán Aníwúrà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

A tún ni àwọn kan tí wọ́n níí ṣe pẹ̀lu híwu ìwà òdaràn. Àpẹẹrẹ àwọn fíìmù tí ó ti wà lórí igbá tí ó sì wa lábẹ́ ọ̀wọ́ yìí ni; Tombolo, Isakaba àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀wọ́ kẹta ni wọ́n ń pè ní “comedy films” (àwàdà). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù tí ó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀fẹ̀ ni wọ́n tí gbé jáde. Àpẹẹrẹ ni fíìmù baba latin, òǹṣèrè kan tí ó gbajúmọ̀ nínú fíìmù Yorùbá tí ó pè ní, “Mr President” tàbí èyí tí òṣèré inú fíìmù òyìnbó ní ilẹ̀ Nàíjáríà kan tí a ń pè ní Nkem Owoh ṣe. Ó pè é ní “Osuofia in London”.

Ọ̀wọ́ kẹrin ni èyí tí wọ́n ń pè ní “drama films” (fíìmù orí ìtàgé). Orí ìtàgé ni wọ́n ti kọ́kọ́ máa ń ṣe irú eré báyìí kí wọ́n tó gbé jáde sínú kásẹ̀tì. Àpẹẹrẹ ní Àkànní Òpómúléró àti Ṣàǹgó. Yàtọ̀ sí èyí, a tún rí àwọn tí wọ́n máa ń ṣe láti ba àwọn ènìyàn lẹ́rù. Nínú irú fíìmù yìí, a ó ò máa rí oríṣi nǹkan tí yóò ba ènìyàn lẹ́rù bíi iwin olórí mẹ́fà, kí ilẹ̀ dédé lanu gbé ènìyàn kan ṣoṣo mi láàárín ọjà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àpẹẹrẹ irúfẹ́ fíìmù wọ̀nyí ni Aníkúlápó tí Ìyá Rainbow ò̀ṣèré Yorùbá kan gbé jáde. Irúfẹ́ fíìmù yìí ni wọ́n ń pé ni “Horror films” lédè òyìnbó.

Bákan náà ni a ní a tún rí àwọn tí wọ́n ń pè ní “dance and musical film” (oníjó). Àwọn wọ̀nyí níí ṣe pẹ̀lú ijó. Àpẹẹrẹ kan ni fíìmù Láídé Bákàrè; Ijóyá. A tún ní àwọn mìíràn bíi Science fiction (Mérìírí ti sáyéńsì), Action film (oníjàgídíjàgan) àti Adventure films (ìtàn lórí ìwádìí) tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ wa níbí.

Àwọn Àkóonú Fíìmù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn fíìmù tí ó ń jáde ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló ní àkóónú tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìṣòró tí ó ń kójú àwọn mùtúmùwà ilẹ̀ Áfíríkà. Àwọn fíìmù kan máa ń gbe ẹ̀sìn kìrìsítẹ́nì àti mùsùlùmí lẹ́sẹ̀ nígbà tí àwọn kan ń polongo ìhìnrere. Àpẹẹrẹ irú àwọn fíìmù wọ̀nyí nii “Agbára ńlá” tí Mike Bamiloye ṣe, “látòrunwá” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lo.̣ Yàtọ̀ sí àwọn fíìmù tí ó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn lóríṣìíríṣìrí, a tún ní àwọn tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìdàrúdàpọ̀ tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìdàrúdàpọ̀ tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ẹ̀sìn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá kọlu ara wọn, yálà nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá fé láti fẹ́ ara wọn tàbí nígbà tí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ bá dạ̀ wọ́n pọ̀. Àpẹẹrẹ ní fíìmù kan tí wọ́n pè ní “Not without my daughter” (Láìsí ọmọbìnrin mi) tí ó ń sọ ìtàn nípa okùnrin mùsùlùmí kan àti obìnrin kìrìsìtẹ́nì kan tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéyàwó tí wọ́n sì tún rí oríṣI ìṣòro nígbà tí wọ́n ń gbáradì fún ìgbéyàwó wọn.

Bákan náà, àwọn fíìmù kan tún wà tí iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n ń jẹ́ níí ṣe pẹ̀lú àrùn tí ó bá ń kojú àwùjọ lásìkò kan kì í sẹ ní Afrika nìkan ní irú fíìmù yìí ti ń jáde. Ní ilẹ̀ Amerika, a rí fíìmù kan tí wọ́n pè ní “philadephia”. Pàtàkì ohun tí ó jẹ́ àkóónú fíìmù yìí ní bí àwọn ènìyàn ṣe máa ń hùwà sí àwọn tí ó ní àrùn éèdì. Ní ìlẹ̀ Nàìjíríà náà, a rí irú fíìmù bíi “Elébòlò” (charlot) àti “wheel of change” (Kẹ̀kẹ́ ìyípadà) tí ó níí ṣe pẹ̀lú àrùn kògbóògùn éèdì.

Síwájú sí ì, àwọn àkóónú mìíràn tí fíìmù tún máa ń ní ni ìwà ìbàjẹ́, ìkìlọ̀ lórí bí wọ́n ṣe máa ń kọ iyán àwọn obìnrin ilẹ̀ Afrika kéré, ìkìlọ̀ nípa àṣà òkèèrè tí ó gbòde kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn fíìmù tí ó kọ́kọ́ jádé máa ń fi àṣà Yorùbá hàn sí gbogbo àgbáyé nítorí wí pé àwọn tí wọ́n ń ṣe fíìmù nígbà náà gbà wí pé ọ̀nà kan tí àwọn lè gbà láti jẹ́ kí àwọn ará ìlú òkèèrè ó gba fíìmù Yorùbá gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí ó kúnjú òṣùwọ̀n ni láti fi ạ̀ṣà àti ìṣe wa hàn nínú eré náà. Ní ọdún 1975 Ọlá Balógun gbé fíìmù kan tí ó pè ní “Àjàní Ògún”. Lẹ́yìn èyí, àwọn díè nínú àwọn tí ń ṣe eré ìbílẹ̀ káàkiri bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa nínú òwò fíìmù. Lásìkò yìí ni Herbert Ogunde ṣe fíìmù tí ó pè ní “Aiye”. Fíìmù yìí jáde ni ọdún 1980. Ohun kan ṣoṣo tí kò wá jẹ́ kí fíìmù yìí dí ìtẹwọ́gbà káàkiri ni pé, ó fi àwọn Yorùbá hàn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn burúkú tí wọ́n máa ń ṣe oríṣìíríṣìí ẹgbẹ́ tí ó ń bànìyàn lẹ́rù. Yàtọ̀ sí èyí, owó tí olóyè Ogunde fi ṣe fíìmù yìí fẹ́ẹ̀ lè má pé nígbà tí wọ́n tà á tán. Níṣe ni ó dàbí ẹni tó ṣòwò tí kò jèrè.

Ṣùgbọ́n ti olóyè Ògúǹdé ṣe ti àwọn bíi Ọlá Balógun, Adéyemí Afọláyan tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí “Ade love” àti Moses Oláìyá tí wọ́n ń pè ní “Bàbá Sàlá”. Gégé bí Nosa Owens-Ibie (2004) ṣe sọ, gbogbo fíìmù tí wọ́n ṣe pẹ̀lú owó tí wọ́n yá ni ilé-ìfowópamọ́, wọ́n jẹ gbèsè tí púpọ̀ wọn ò tilẹ̀ dábàá àti ṣe fíìmù àgbéléwò mọ́ léyìn náà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí “Ade love” sọ kí ó tó kú ni ọdún 1995 nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí wọ́n ṣe fun; ó ṣàlàyé bí òun ṣe yá owó ní báńkì láti ṣe fíìmù rẹ̀ “Destiny” (àyànmọ́). Ó ní ní ìgbà náa, dọ́là kan jẹ déédé náìrà mẹ́wàá, ṣùgbọ́n ní ọjọ yìí, ó di náírà kan-dínlógún fún dọ́là kan. Ó ní òun ní láti ya owó si ni láti san owó tí oùn yá ṣe fíìmù náà. Ohun kan tí a ṣàkíyèsí ni pé, owó fa ọwọ́ aago fíìmù Yorùbá sẹ́yìn.

Ní ọdún 1992, Ládi Ládébò, ọ̀kan nínú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe fíìmù sí fídíò gbá oyè méjì lórí fíìmù rẹ̀ méjì: “Èèwò” àti “Vender”. Lẹ́yìn èyí, àwọn bíi Ọlá Balógun àti Herbert Ogunde bẹ̀rẹ̀ sí níí ṣe fíìmù pẹ̀lú irínṣẹ́ tuntun. Èyí jẹ́ kí àwọn fíìmù wọ̀nyí di gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Nàíjíríà àti ní òkèèrè. Ògúǹ̀dé ṣe “Jaiyesinmi”, “Àròpin N’tènìà” àti Àyànmọ́. Láàárín ọdún 1993 sí ọdún 1996, àwọn tí wọ́n ń ṣe fíìmù Yorùbá ti pọ̀ sí. Fíìmù Yorùbá tí ó jáde ní àkókò yìí lé ní igba (200). Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe fíìmù Yorùbá ni ìgbà náà ni: Jimoh Aliu tí ó ṣe “Ètékéte”, Tunde Àlàbí hundeyin ṣe “Iyawo alhaji”, Professor Pellar náà ṣe fíìmù mẹ́ta. Àwọn ni “Idán ńlọ”, “Owó Idán” àti “Agbára”. Oyin Adéjọbí náà ṣe fíìmù kan tí ó pè ní “Orogún Adédigba” ní ọdún 1995. Yàtọ̀ sí èyí, Yẹmí Fáróunbí ṣe fíìmù kan tí ó pè ní “Ẹ̀bùn Olúwa” ní ọdún yìí kan náà. Àwọn òṣèrè bíi Jídé Kòsọ́kọ́ àti Ṣọlá Fósùdó ṣe fíìmù kan tí wọ́n pè ní “Ọkọ Ìyàwó”.

Lẹ́yìn tí àwọn òṣèrè yìí ṣe fíìmù yìí tán, àwọn òṣèrè mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé fíìmù tiwọn náà jáde. Bí wọ́n bá ni kí wọ́n ka oríṣi fíìmù Yorùbá tí ó ti jáde, yóò tó ìdá mẹ́fà fíìmù tí ó ti jáde ní ilé-iṣẹ́ àwọn onífíìmù tí ó gbajúmọ̀ nísìnyí. Orúkọ tí wọ́n ń pé ilé-iṣẹ́ náà, tí ó kó àwọn òṣèré mọ́ àwọn tí ń ṣe fíìmù jọ ni wọ́n ń pè ní Nollywood. Ilé-iṣẹ́ fíìmù Yorùbá ti tóbi si; àkóónú fíìmù wọn sì ti ń yípadà sí ti àtijọ́ tí ó jẹ́ wí pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, ẹ̀fẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ni ó ń jẹ ẹ́ lógún.

Ipa àwọn fíìmù Yorubá láwujọ Yorùbá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ohun pàtàkì kan tí ó ya fíìmù Yorùbá sọ́tọ̀ ní èdè àmúlò. Gégẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé àwọn Yorùbá kìí ń sọ̀rọ̀ lásán, wọn máa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú làákàyè àti ọgbọ́n. Àwa náà sí mọ̀ pé èdè Yorùbá yìí kún, ó dùn, ó ṣe pàtàkì, ó sì jọjú gidigidi. Tí wọ́n bá ko eré, ìṣẹ̣̀lẹ̀ láwùjọ àti ọgbọ́n inú rẹ̀ ní wọn ó kó jọ. Àkóónú eré wọn á máa lọ láti orí ìbálòpọ̀ tí ò lẹ́tọ̀ọ́, ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ láàárín ọ̀tọ̀kùlú àti ìjọba, ìjà ìyálé àti ìyàwó, ìrirí ayé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Èdè Yorùbá tí wọ́n fi ń gbé ìtàn wọn kalẹ̀ yìí jẹ́ kí ó yé gbogbo mùtúmùwà ohun gbogbo tí wọ́n ń sọ. Ó sì jẹ́ kí tàgbà tọmọdé, akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́, kòfẹ́sọ̀ àti àgbẹ̀ rí ẹ̀kọ́ kan tàbí òmíràn dìmú nínú fíìmù wọn. Wọn kì í dédé sọ̀rọ̀ bí kò bá ṣe wí pé ó lóhun tí ònkọ̀tàn rí. Àwọn òṣèré náà sì máa ń gbìyànjú láti túmọ̀ gbogbo ohun tí ó bá yẹ kí wọ́n sọ kí ó le yé gbogbo ènìyàn.

Ohun mìíràn tí a tún gbọ́dọ̀ ṣàkíyèsí ni pé àwọn olóṣèlú a máa fi àwọn eré ìgbálódé orí ìtàgé àti ti inú fíìmù polongo ara wọn nígbà ìdìbò. A rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ, nínú àwọn fíìmù àgbéléwò tí ó ti wà lórí àtẹ. Ọ̀kan nínú àwọn tí wọn lò láti kìlọ̀ nípa ìdìbò, ṣe ìlérí àwọn ará ìlú àti tí wọ́n fi pe àfiyèsí àwọn ará ìlú nígbà ìdìbò ni fíìmù tí wọ́n pè ní “Olúọmọ-rẹ̀mílẹ́kún”. Ẹni tí ó ba ṣe àfiyèsí tí ó kún nínú fíìmù yìí yóò mọ̀ wí pé ọ̀kan nínú àwọn olùdíje fún ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ó fi polongo. A lè sọ wí pé fíìmù máa ń jẹ́ kí òye àwọn ènìyàn kún síi. A tún gbọ̣́dọ̀ ṣàkíyèsí pé kìí ṣe gbogbo fíìmù ni ó ń kó ipa gidi ní àwùjọ, àwọn kan tilẹ̀ máa ń polongo ìwà ìbàjẹ́ ni.

ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌLÒ Ẹ̀KA-ÈDÈ NÍNÚ FÍÌMÙ ÀGBÉLÉWÒ JÓGUN-Ó-MÍ, ṢAWORO-IDẸ ÀTI AGOGO-ÈÈWỌ̀

APÁ KAN NÍNÚ ÀṢEKÁGBÁ OYÈ

B.A (HONS.) YORÙBÁ

YUNIFÁSITÌ OBÁFẸ́MI AWÓLỌ́WỌ̀,

[[ILÉ-IFẸ̀.]

LÁTI ỌWỌ́

BÁDÉWỌLÉ OLÚWÁTÓSÌN ADÉBÙKỌ́LÁ

OṢÙ ỌPẸ́ 2007

Supervisor – Dr. F.A. Fabunmi