Kọ́ńsónáńtì aránmú asesílébù
Kọ́nsónáǹtì Aránmú aṣesílébù ni kọ́nsónáǹtì tí a lè dá fi ohùn pè gẹ́gẹ́ bíi fáwẹ́lì. Fọ́nrán èdè tí a mọ̀ sí odo sílébù ni fáwẹ́lì ṣùgbọ́n àwọn kọ́nsónáǹtì aránmú tí à ń wí yìí náà ń ṣiṣẹ́ odo sílébù nítorí náà ni a ṣe ń pè wọ́n ní kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi hàn nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kìnní àti ikèjì móòdù yìí.
Orísìírísìí ni ìrísí kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù, Owólabí (2011:115) ṣàlàyé pé nínú èdè Yorùbá, kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù a máa ní ìrísí mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ èyí tí ó sábà máa ń dúró lórí ibi ìsẹ́nupè tí ìró tí ó tẹ̀lé kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù bá ní. Èyí já sí pé àwọn kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù mẹ́fẹ̀ẹ̀fà wọ̀nyí wà ní ìfọ́nká aláìṣèyàtọ̀. Nítorí ìdí èyí, gbogbo wọn jẹ́ ẹ̀dà-fóníìmù tí a gbọdọ̀ fi sí abẹ́ fóníìmù kan ṣoṣo. Àrokò tí a lò fún fóníìmù kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù nínú èdè Yorùbá ni èyí: /m(/.
Bí kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù bá jẹyọ sáájú ìró àfèjì-ètè-pè ([b] àti [m]) òun náà yóó ní àbùdá àfèjì-ètè-pè [m(] nínú àpẹẹrẹ bí i:
ó ń bọ̀ ó ń bú ramú ramù
[ó ḿ́ (bↄ̀] [ó ḿ( bú ramú᷈ ramù᷈]
/ ó ḿ( bↄ̀/ / ó ḿ( bú ramú᷈ ramù᷈/
Bí kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù bá jẹyọ sáájú ìró àfeyínfètèpè ([f]) òun náà yóó ní àbùdá àfeyínfètèpè nínú àpẹẹrẹ bí i:
ó ń fẹ́ ọwọ́ ó ń fọsọ
[ó (́( fɛ́ ↄwↄ́] [ó (́( fↄʃↄ]
/ó ḿ( fɛ́ ↄwↄ́/ /ó ḿ( fↄʃↄ/
Bí kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù bá jẹyọ sáájú ìró afèrìgìpè ([d], [t], [n], [s], [r], [l]) àti ìró afàjàjàfèrìgìpè ([(], [d(]) yóó ní ìrísí ìró afèrìgìpè àpẹẹrẹ ni
ó ń sín ọmọrí náà ń ṣí kòkòrò náà ń dún
[ó ń sí᷈] [ↄmↄrí ná᷈à᷈ ń (í] [kòkòrò ná᷈à᷈ ń dú᷈]
/ ó ḿ( sí᷈/ /ↄmↄrí ná᷈à᷈ ḿ((í/ /kòkòrò ná᷈à᷈ ḿ( dú᷈/
Bí kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù bá jẹyọ sáájú ìró afàjàpè ([(], [j]), òun náà yóó ní ìrísí afàjàpè. Àpẹẹrẹ ni
Adé ń yọ̀
[adé (́( jↄ̀]
/adé ḿ( jↄ̀/
Bí kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù bá jẹyọ sáájú afàfàsépè ([k], [g]) àti afitán-ánnápè ([h]) yóó ní àbùdá afàfàsépè [((] nínú àpẹẹrẹ bí i
ó ń ké ọṣẹ náà ń hó
[ó (( ké] [ↄ(ɛ ná᷈à᷈ ( hó]
/ ó ḿ( ké / / ↄ(ɛ ná᷈à᷈ ḿ( hó /
Bí kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù bá jẹyọ sáájú ìró afàfàséfètèpè ([k(p], [g(b]), òun náà yóó ní àbùdá afàfàséfètèpè ([((m(]) àpẹẹrẹ ni
Ọlọ́run ń gbọ́
[ↄlↄ́ru᷈ ((m( gbↄ́]
/ ↄlↄ́ru᷈ ḿ( gbↄ́/
3.1 Dídárúkọ kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù Ọlọ́rọ̀ ìperí mẹ́rin
Bí a ti ṣe fún kọ́nsónáǹtì àti fáwẹ́lì náà ni a ó ṣe fún kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù, àwọn ohun tí wà á tẹ̀lé ni ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí.
Ipò tí alàfo tán-an-ná wà
Ibi Ìsẹ́nupè
Ọ̀nà Ìsẹ́nupè
Ohùn ni a fi pè é (Aṣesílébù).
[n] akùnyùn afàrìgìpè aránmú aṣesílébù
[((] akùnyùn afàjàpè aránmú aṣesílébù
[(] akùnyùn afàfàsépè aránmú aṣesílébù
[(] akùnyùn afeyínfètèpè aránmú aṣesílébù
[((m(] akùnyùn afàfàséfètèpè aránmú aṣesílébù
[ḿ(] akùnyùn afèjì-ètè-pè aránmú aṣesílébù