Jump to content

Kamaru Usman

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kamaru Usman

Kamaru Usman (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlá oṣù karùn-ún ọdún 1987) jẹ́ gbajúmọ̀ Ajẹ̀ṣẹ́-gídígbò (mixed martial artist) ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà tí ó ń jẹ̀ṣẹ́ ònígídígbò jẹun lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.[1]

Àwọn ìdíje àti Àmì ẹ̀yẹ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kàmárù ti díje lọ́pọ̀ ìgbà nínú ìdíje ìjà-ẹ̀ṣẹ́ ònígídígbò tí Ultimate Fighting Championship (UFC). Kódà, òun ni olùborí nínú ìdíje ìjà ẹ̀ṣẹ́-onígídígbò tí ìdíje ókànlélógún. Títí di ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2019, Kamaru Usman ni ó wà nípò kẹjọ nínú ìmúsípò àwọn ajẹ̀ṣẹ́ onígídígbò lágbàáyé.[2][3]

Ibẹ̀rẹ̀ ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ajẹ̀ṣẹ́-gídígbò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọmọ bíbí ìlú Auchi ní ìpínlẹ̀ Edo lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni Kamaru Usman. Ajagun-fẹ̀yìntì ni bàbá rẹ̀. Àwọn òbí rẹ̀ mú un lọ sí òkè-òkun, lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní nìjàkadì ní ilé ìwé gírámà ti Bowie High School ní Ìlú Arlington, ní ìpínlẹ̀ Texas lorílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Nítorí pé òyìnbó akọ́ni-mọ̀ọ́njà kò lè pe orúkọ rẹ̀ gan dá geere, ló bá kúkú sọ Kamaru Usman ní "Marthy", èyí sìn ní orúkọ tí wọ́n ń pè é nígbà náà. Ní àkókò yìí, ọ̀pọ̀ àṣeyọrí ní Usman ṣe kí ó tó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní kọ́lẹ́ẹ̀jì. Jon Jones wà lára àwọn tí Usman bá jàjàkadì kí ó tó lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì. Ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, Usman díje ìjàkadì ní ilu Iowa ní William Penn University fún ọdún kan gbáko, ìgbà náà ló tó pegedé láti ṣojú orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà nínú ìdíje NAIA fún ti ọdún 2007. Lẹ́yìn èyí, ó kúrò ní kọ́lẹ́ẹ̀jì náà lọ sí University of Nebraska ní Karney (UNK), ó sìn ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gba àmìn-ẹ̀yẹ àkókò lọ́dú 2008.[4] Fún odidi ọdún mẹta gbáko, Usman ni ó gbà àmìn-ẹ̀yẹ ti NCAA Division II All-American

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Kamaru "The Nigerian Nightmare" Usman MMA Stats, Pictures, News, Videos, Biography". Sherdog.com. 2019-03-05. Retrieved 2019-12-18. 
  2. Durosomo, Damola (2019-12-17). "'I’m More American Than Him,' Says Nigerian UFC Champion Kamaru Usman After Crushing MAGA-Supporting Opponent". OkayAfrica. Retrieved 2019-12-18. 
  3. "Kamaru Usman ("The Nigerian Nightmare") - MMA Fighter Page". Tapology. 2019-12-14. Retrieved 2019-12-18. 
  4. "Kamaru Usman Fight Results and History". ESPN. 2019-12-18. Retrieved 2019-12-18.