Kareem Waris
Ìrísí
Kareem Ọlámilékan Waris jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ọmọ ọdún mẹ́tàlá tí ó jẹ́ gbajúgbajà afọwọ́-yàwòrán ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1] Waris ya àwòrán Ààrẹ orílẹ̀ èdè Faransé, Emmanuel Macron, nígbà tí ó wà sì orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́dún 2018 láàárín wákàtí méjì. Àwòrán yìí dára tó bẹ́ẹ̀ gẹ̀ẹ́ tí Ààrẹ Emmanuel Macron tí orílẹ̀ èdè France fí gbà á lálejò nígbà tí ó wà sí Nàìjíríà. BÁKAN náà, Kareem Ọlámilékan Waris ló gbà àmìn ẹ̀yẹ agbaye ẹlẹ́ẹ̀kejìlélógun (22nd) ní orílè-èdè Taiwan, Taiwan’s 22nd Fervent Global Love of Lives Award lọ́dún 2018. Ó pegedé tí ó sìn borí gbogbo adíje láti gbogbo àgbáyé tí wọ́n tó 2723. [2] [3] [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Meet the 11-year-old creating hyper-real art". BBC News. 2018-06-28. Retrieved 2020-01-07.
- ↑ "Young Nigerian hyper-realistic artist, Kareem Waris Olamilekan wins International Art award". This is africa. 2019-10-03. Retrieved 2020-01-07.
- ↑ Akande, Segun; CNN, for (2018-07-04). "The 11-year-old Nigerian artist who moved President Macron". CNN. Retrieved 2020-01-07.
- ↑ "Nigerian Artist Kareem Waris wins International award". TVC News Nigeria. 2019-09-18. Retrieved 2020-01-07.