Kenneth Abrahams
Ìrísí
Kenneth Abrahams | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Kenneth Godfrey Abrahams 1936 |
Aláìsí | 2017 |
Kenneth Godfrey Abrahams (1936–2017) jẹ́ oníṣègùn òyìnbó àti ajàfẹ́tọ́ ènìyàn ọmọ orílẹ̀ Namibia.
A bi sí ìlú Cape Town ní orílẹ̀ ède South Africa Ó sì kàwé gboyè ní University of Cape Town\Yunifásítì Cape Town. Abrahams padà kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìsègùn òyìnbó ní Stockholm. Òun àti ìyàwó rẹ̀, Ottilie Abrahams, dára pò mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú SWAPO ní ọdún 1960. Ó wà lára àwọn tí ó gbámú pẹ̀lú ẹgbẹ́ Yu Chi Chan Club tí Neville Alexander dá kalẹ̀, ó sì gbìyànjú láti sá lọ sí Botswana torí èyí. Àwọn Ọlọ́pàá South Africa fi pánpẹ́ òfin gbé òhun àti àwọn ìyókù rẹ̀ níbẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n padà tu sílẹ̀. Abrahams padà dá ilé ìwòsàn kalẹ̀ ní Khomasdal.[1]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Tonchi et al. 2012, p. 13.