Jump to content

Kodofanianu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Kodofanianu (Kordofanian))

KORDOFANIAN

Kodofanianu

Ní agbègbè orí òkè Nuba ní orílẹ̣̀ èdè Sudan ni àwọn ènìyàn tí ó n sọ èdè yìí wọ́pọ̀ sí jùlọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ogun àti ọ̀tẹ̀ ti fọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yìí ká. Àtẹ ìṣàlẹ̀ yìí ni ó ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọ̀rí èdè tí ó wà ní abẹ́ ori èdè Kordofanian.

Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kordofanian’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Heiban, Tahodi, Rashad, Katla. Heiban pín sí Ìlà Oòrùn (Ko, Warnang); ààrín gbùngbùn (Koalib, Logol, Laru, Ebang, Utoro); lààrín ‘Central àti west’ a rí shirumba; Ní ìwọ̀ oòrùn (Tiro àti Moro).

Talodi: lábẹ́ Tolodi, a rí Ngile (Masakin) àti Dengbebu, Tocho, Jomang, Nding, Tegem. Rashad: lábẹ́ rẹ̀ ni Tagoi àti Tagali wà. Katla: lábẹ́ rẹ̀ ni kalak (Katla) àti Lomorik (Tima).