Lunda

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

LUNDA

Àwọn ẹ̀yà yìí wà ní orílẹ̀ èdè Congo, Zambia àti Angola, èdè wọn sì jẹ́ ẹ̀yà ti Bantu. Wọ́n dín díẹ̀ ní ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án wọ́n sì múlé gbe ẹ̀yà Yaka, Suku, Chokwe abbl. A rí àgbẹ̀, apẹja àti onísòwò tààrà ni orílẹ̀ èdè yìí. Mwaat Yaav ni ọba wọn, àwọn ìjòyè náà sì wà. Baálẹ̀ kọ̀ọ̀kan náà sì sà ṣùgbọ́n ìsákọ́lẹ̀ pọn dandan. Wọ́n máa ń dífá alágbọ̀n ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbọ́ nínú nzambi.