Mayowa Adegbile

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Máyọ̀wá Adégbilé)
Máyọ̀wá Adégbilé
Mayowa Adegbile in Abuja, Nigeria
Ọjọ́ìbíMáyọ̀wá Abíọ́lá Adégbilé
10 Oṣù Kẹ̀sán 1986 (1986-09-10) (ọmọ ọdún 37)
Nàìjíríà, Èkó
Orílẹ̀-èdèỌmọ Nàìjíríà
Ẹ̀kọ́Enterprise Development Center Lagos Business School Social Sector Management
Iṣẹ́Afowóṣàánú, Olùkọ́
Websiteashakefoundation.org

Máyọ̀wá Adégbilé tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù Kẹ̀sán ọdún 1986 jẹ́ gbajúmọ̀ afowóṣàánú ọmọ Nàìjíríà. Ó wà lára àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́ta tí wọ́n yàn mọ́ àwọn akẹgbẹ́ wọn ní Áfíríkà fún àṣeyọrí ìdíje Google lọ́dún 2014. [1] Máyọ̀wá kọ́kọ́ ló ìkànnì YouTube láti ṣe ìkówójọ fún ilé-iṣẹ́ afowóṣàánú rẹ̀, Ashake Foundation, èyí tí ó dá sílẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn abiyamọ opó, ó máa ń fún wọn ní irinṣẹ́ láti ṣòwò jẹun àti láti rán ebilí wọn lọ́wọ́.[2]

Ilé-iṣẹ́ afowóṣàánú, Ashake (Foundation)[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Máyọ̀wá bẹ̀rẹ̀ Ashake Foundation, ilé-iṣẹ́ afowóṣàánú fún àwọn abiyamọ opó lọ́dún 2012 pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ fún méjìlélógún opó àti àwọn ọmọ mẹ́rìndínlógójì, tí ó pèsè ìrànlọ́wọ́ owó àti ohun èlò okowò fún. Èyí tí mú kí púpọ̀ nínú kúrò nínú ìṣẹ́, tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ sìn padà sí ilé-ìwé .[3]

Àwọn àmìn-ẹ̀yẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Máyọ̀wá gba àmìn-ẹ̀yẹ ti Junior Chamber International lóṣù keje ọdún l 2017, gẹ́gẹ́ bí ọkàn nínú àwọn ọmọdé mẹ́wàá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n mókè nínú afowóṣàánú adarí ọ̀fẹ́.[4]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]