Mahfoozur Rahman Nami

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Mahfoozur Rahman Nami
Member Uttar Pradesh Legislative Assembly
In office
1946–1951
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíMay 1911
Rasra Balia
Aláìsí17 November 1963(1963-11-17) (ọmọ ọdún 52)
Bahraich, Uttar Pradesh
Alma materJamia Miftahul Uloom, Darul Uloom Deoband
Àdàkọ:Infobox religious biography

Mahfoozur Rahman Nami (May 1911 – 17 November 1963) jé mùsùlùmí onímò ìjìnlè, olósèlú àti ònkòwé.

A bíi ní osù karùn odún 1911, NAMI jé akékò jáde ilé-ìwé Jamia Miftahul Uloom àti Darul Uloom Deoband. Ó se ìdásílè Madrasa Nūr-ul-Ulūm àti Azad Inter College ní Bahraich. Ó kú ní ojó ketàdínlógún, osù kokànlá odún 1963.

Ìgbésíayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Inú osù karùn odún 1911[1] ni a bí Nami. Ó parí èkó alábèrè ní Jamia Miftahul Uloom pèlú Abul Lateef Nomani àti Habib al-Rahman al-'Azmi.[2] Nami wo ilé èkó Darul Uloom Deoband ni odún Islam 1344 AH, níbití ó ti kó èkó pèlú Hussain Ahmad Madani, Izaz Ali Amrohi àti Ibrahim Balyawi. Ó jáde ilé-ìwé ní odún Islam 1348 AH.[2]

Nami se ìdásílè Madrasa Nūr-ul-Ulum ní Bahraich.[1] Ó tun se ìdásílè ilé-èkó gíga Maulana Azad Nur-ul-Ulūm, tí a mò bayi sí Azad Inter College, ní Bahraich.[3] Ó díje ní 1946 Indian provincial elections l'ábé àsìá egbé Indian National Congress. Ó s'isé gégé bíi omo ilé Uttar Pradesh Legislative Assembly ní odún 1946 to 1951.[4] Ó jé Parliamentary secretary ní èka ìjoba l'óri èkó.[4] Ní odún 1359 AH, Darul Uloom Deoband yàn án gégé bíi omo ilé-ejó ti Aligarh Muslim University pèlú Muhammad Tayyib Qasmi àti Hifzur Rahman Seoharwi.[5]

Nami fi ayé sí'lè ní ojó ketàdínlógún, osù kokànlá, odún 1963 ní Bahraich tí wón sì sin-ín l'èbá ibòji Shah Naeemullah Bahraichi.[1]

Ìsé ìwé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nani se àtèjáde Miftah al-Quran tí Darul Uloom Azaadville, tí ilé-èkó ti èsìn Islam ti Azaadville, yàn sí àrà ètò èkó won.[6] Àwon isé rè míràn ni:

  • Muallim ul Quran
  • Rahmani Qiada
  • Hilal Bagh
  • Musalmanan-E-Hind ka Taleemi Masla

Àtókàsi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 Asir Adrawi. Tazkirah Mashāhīr-e-Hind: Karwān-e-Rafta. pp. 236–237. 
  2. 2.0 2.1 Qasmi, Ameer Ahmad, ed. Nur-ul-Ulum Ke Darakhshanda Sitāre. pp. 27–28. 
  3. Qasmi, Ameer Ahmad, ed. Nur-ul-Ulum Ke Darakhshanda Sitāre. p. 31. 
  4. 4.0 4.1 Bahraich Ek Tārikhi Sheher. pp. 128, 173. 
  5. Syed Mehboob Rizwi. History of the Dar al-Ulum Deoband (1st, 1981 ed.). Darul Uloom Deoband. p. 248. 
  6. Àdàkọ:Cite thesis

Ìwé ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control