Mashonaland
Ìrísí
Mashonaland jẹ́ àgbègbè kan ní àríwá Zimbabwe. Ó jẹ́ ilé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní orílè-èdè Zimbabwe. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní Mashonaland wá láti ẹ̀yà Shona, èdè Zezuru àti Korekore sì ni ó gbajúmọ̀ jù níbẹ̀. Harare ni ìlú tí ó tóbi jù níbẹ̀, Chitungwiza sì ni ó tóbi tẹ̀le.
Wọ́n pín àgbègbè Mashonaland sí mẹ́rin,
Harare, olú-ìlú Zimbabwe jẹ́ àgbègbè ara rẹ̀.
Ilẹ̀ Mashonaland
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ilẹ̀ náà ní òkè fífẹ̀ tí apá àríwá àti ìwọ oòrùn àríwá rẹ̀ sì tè lọ ilẹ̀. Ibi tí ó wálẹ̀ jù lára òkè náà ni àríwá ilẹ̀ òkè náà, Odò Zambezi sì ló sújọ sí ibè. Orílè-èdè Zambia ló wà lẹ́yìn odò náà. Odò Munyati àti agbègbè Midlands ni ó wà ní gúúsù àlà òkè náà.