Mike Omoighe
A bí Michael Akhaine Osebhajimete Omoighe tí ìnagijẹ sì ń jẹ́ Mike Omoighe, ní ọjọ́ kọọkànlá, oṣù keje (Agẹmọ) ọdún 1958, ó sì jáde láyé ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kìn-ín-ní (Ṣẹrẹ) ọdún 2021. Ó jẹ oníṣẹ́ ọnà aláfọwọ́gbékalẹ̀ àti olùkọ́ iṣẹ́ ọnà aláfọwọ́gbékalẹ̀. a bí Mike ni ìlú Opoji Ekpoma ní ìpínlẹ̀ Ẹdó. Ó dàgbà sí ìpínlẹ̀ Èkó níbi tí ó ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésé-ayé rẹ̀.
Omoighe lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti Yábàá (Yaba College of Technology) ní ọdún 1978, níbi tí ó ti gba àmì gboyè “ND”. Bákan náà ni ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti Auchi (Auchi Polytechnic) ní 1980, tí ó s̀ gba oyè HND. Ó tẹ̀síwájú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifáfiitì ti ìjọba àpapọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó (University of Lagos) ní 1987, tí ó si, gboyè àbójútó ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe (Certificate in Polytechnic Management (CPM) NBTE)), bákan náà ni ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ giga ti ìjọba àpapọ̀ ní Ìbàdàn (University of Ibadan) ní 1994, níbi tí ó ti gboyè ìjìnlẹ̀ nínú ìbánisọ̀rọ̀ ajẹmọ́-àwọ̀rán (Master's in Visual Arts Communication) Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ayàwòrán-an Bruce Onobrakpeya.
Láti ọdún 1986 títí ó fi di olóògbé, Omoighe jẹ́ olùkọ́ iṣé-ọnà aláfọwọ́gbékalẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti Yábàá (Yaba College of Technology), tí ó sì di ipò olórí ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Fine Art, gíwá ilé-ẹ̀kọ́ ìṣe, ìyàwòrán àti àtẹ̀jáde (Dean of School of Art, Design and Printing), àti Gíwá alábòójútó ọrọ̀ tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ (DeanStudent Affairs). Ilé-ẹ̀kọ́ gb ogbonìṣe Yábàá wà ní ile ní ìpínlẹ̀ Èkó, ní orílè-èdè Nàìjíríà. Bákan náà ló jẹ́ Ààrẹ International Association of Art Critics, AICA, ní orílè-èdè Nàjíríà.[1]
Omoighe gbé Titi Omoighe tí òun náà jẹ́ ayàwòrán ní ìyàwó wọ́n sì bí ọmọ. Ó kú ní ọmọdún méjìlélọ́gọ́ta (62) ní ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù ṣẹrẹ ọdún 2021 (January 23, 2021), látàri àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19).[2]
Iṣẹ́ rẹ̀ tó ṣàfihàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- 1980: Auchi, Bendel State
- 1982: National Arts Theatre, Iganmu, Lagos
- 1983: Goethe-Institut, Lagos
- 1984: Italian Cultural Centre, Lagos
- 1984: Scruples, 28 Bode Thomas, Surulere, Lagos
- 1988: Italian Cultural Centre, Lagos
- 1990: Alliance Francaise, Kano; Journey Through Savannah, Didi Museum, Lagos
- 1993: Emotion, National Museum, Onikan, Lagos
- 1996: Beijing Series - Chevron Lekki Lagos
- 1996/1997: Jacinta's Place, Probyn Street Ikoyi Lagos (Salon)
- 2000: Survival Romance, National Gallery of Art, Iganmu, Lagos
- 2005: Seasons and Chain of Coincidences, National Museum, Lagos
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "TOASTING TO MIKE OMOIGHE'S THREE SCORES". This Day Live. Retrieved 26 October 2018.
- ↑ YABATECH chief lecturer dies of COVID-19 complications